Nọ́ńbà 14:1-45
14 Gbogbo àpéjọ náà ń kígbe, àwọn èèyàn náà ń ké, wọ́n sì ń sunkún ní gbogbo òru+ yẹn.
2 Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí Mósè àti Áárónì,+ gbogbo àpéjọ náà sì ń sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí wọn pé: “Ó sàn ká ti kú sí ilẹ̀ Íjíbítì tàbí ká tiẹ̀ ti kú sínú aginjù yìí!
3 Kí ló dé tí Jèhófà fẹ́ mú wa wá sí ilẹ̀ yìí kí wọ́n lè fi idà+ pa wá? Wọ́n á kó+ àwọn ìyàwó wa àti àwọn ọmọ wa lẹ́rú. Ǹjẹ́ kò ní dáa ká pa dà sí Íjíbítì?”+
4 Wọ́n tiẹ̀ ń sọ fún ara wọn pé: “Ẹ jẹ́ ká yan ẹnì kan ṣe olórí wa, ká sì pa dà sí Íjíbítì!”+
5 Mósè àti Áárónì wá wólẹ̀ lójú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n pé jọ.
6 Jóṣúà+ ọmọ Núnì àti Kélẹ́bù+ ọmọ Jéfúnè, tí wọ́n wà lára àwọn tó lọ ṣe amí ilẹ̀ náà wá fa aṣọ wọn ya,
7 wọ́n sì sọ fún gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ilẹ̀ tí a lọ ṣe amí rẹ̀ dára gan-an ni.+
8 Bí inú Jèhófà bá dùn sí wa, ó dájú pé ó máa mú wa dé ilẹ̀ yìí, ó sì máa fún wa, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn ni.+
9 Àmọ́ ẹ má ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, ẹ má sì bẹ̀rù àwọn èèyàn ilẹ̀ náà,+ torí a máa jẹ wọ́n run.* Ààbò wọn ti kúrò lórí wọn, Jèhófà sì wà pẹ̀lú wa.+ Ẹ má bẹ̀rù wọn.”
10 Síbẹ̀, gbogbo àwọn èèyàn náà sọ pé àwọn máa sọ wọ́n lókùúta.+ Àmọ́ ògo Jèhófà fara han gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ lórí àgọ́ ìpàdé.
11 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Ìgbà wo ni àwọn èèyàn yìí máa jáwọ́ nínú fífojú di mí?+ Ìgbà wo sì ni wọ́n máa tó nígbàgbọ́ nínú mi pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ àmì tí mo ṣe láàárín wọn?+
12 Jẹ́ kí n fi àjàkálẹ̀ àrùn kọ lù wọ́n, kí n sì lé wọn lọ, sì jẹ́ kí n sọ ìwọ di orílẹ̀-èdè ńlá, tó máa lágbára jù wọ́n lọ.”+
13 Àmọ́ Mósè sọ fún Jèhófà pé: “Àwọn ọmọ Íjíbítì tí o fi agbára rẹ mú àwọn èèyàn yìí kúrò láàárín wọn á gbọ́,+
14 wọ́n á sì sọ fún àwọn tó ń gbé ilẹ̀ yìí. Àwọn náà ti gbọ́ pé ìwọ Jèhófà wà pẹ̀lú àwọn èèyàn+ yìí, o sì ti fara hàn wọ́n lójúkojú.+ Ìwọ ni Jèhófà, ìkùukùu rẹ sì wà lórí wọn, ò ń lọ níwájú wọn nínú ọwọ̀n ìkùukùu* ní ọ̀sán àti nínú ọwọ̀n iná* ní òru.+
15 Tí o bá pa gbogbo àwọn èèyàn yìí lẹ́ẹ̀kan náà,* àwọn orílẹ̀-èdè tí òkìkí rẹ ti kàn dé ọ̀dọ̀ wọn máa sọ pé:
16 ‘Jèhófà ò lè mú àwọn èèyàn yìí dé ilẹ̀ tó búra pé òun máa fún wọn, ló bá pa wọ́n sí aginjù.’+
17 Ní báyìí Jèhófà, jọ̀ọ́, fi agbára ńlá rẹ hàn, bí ìlérí tí o ṣe, pé:
18 ‘Jèhófà, Ọlọ́run tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀*+ sì pọ̀ gan-an, tó ń dárí ìṣìnà àti ẹ̀ṣẹ̀ jini, àmọ́ tí kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀, tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá jẹ àwọn ọmọ, dórí ìran kẹta àti dórí ìran kẹrin.’+
19 Jọ̀ọ́, ro ti ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tó pọ̀ gan-an, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn yìí jì wọ́n, bí o ṣe ń dárí jì wọ́n láti Íjíbítì títí di báyìí.”+
20 Jèhófà wá sọ pé: “Mo dárí jì wọ́n bí o ṣe sọ.+
21 Àmọ́ ṣá o, ó dájú pé bí mo ti wà láàyè, ògo Jèhófà+ máa kún gbogbo ayé.
22 Síbẹ̀, kò sí ìkankan nínú àwọn tó fojú rí ògo mi àti àwọn iṣẹ́ àmì+ mi tí mo ṣe ní Íjíbítì àti ní aginjù, tó tún wá ń dán mi wò+ nígbà mẹ́wàá yìí, tí kò sì fetí sí ohùn mi,+
23 tó máa rí ilẹ̀ tí mo búra pé màá fún àwọn bàbá wọn. Àní, ìkankan nínú àwọn tó ń fojú di mí kò ní rí ilẹ̀ náà.+
24 Àmọ́ torí pé ẹ̀mí tí Kélẹ́bù+ ìránṣẹ́ mi ní yàtọ̀, tó sì ń fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀ lé mi, ó dájú pé màá mú un wá sí ilẹ̀ tó lọ, yóò sì di ti+ àtọmọdọ́mọ rẹ̀.
25 Torí pé àfonífojì* ni àwọn ọmọ Ámálékì àti àwọn ọmọ Kénáánì+ ń gbé, kí ẹ ṣẹ́rí pa dà lọ́la, kí ẹ sì gba ọ̀nà Òkun Pupa+ lọ sínú aginjù.”
26 Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé:
27 “Ìgbà wo ni àwọn èèyàn burúkú yìí máa tó jáwọ́ kíkùn sí mi?+ Mo ti gbọ́ ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń sọ nígbà tí wọ́n ń kùn sí mi.+
28 Sọ fún wọn pé, ‘“Ó dájú pé bí mo ti wà láàyè,” ni Jèhófà wí, “ohun tí mo gbọ́ tí ẹ sọ+ gẹ́lẹ́ ni màá ṣe sí yín!
29 Inú aginjù yìí lẹ máa kú sí,+ àní gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè nínú yín, àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kùn sí mi.+
30 Ìkankan nínú yín kò ní wọ ilẹ̀ tí mo búra* pé ẹ máa gbé,+ àfi Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè àti Jóṣúà ọmọ Núnì.+
31 “‘“Àwọn ọmọ yín tí ẹ sọ pé wọ́n máa kó+ lẹ́rú ni màá mú débẹ̀, wọ́n á sì mọ ilẹ̀ tí ẹ kọ̀+ náà.
32 Àmọ́ inú aginjù yìí ni ẹ̀yin máa kú sí.
33 Ogójì (40) ọdún+ ni àwọn ọmọ yín fi máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn nínú aginjù, wọ́n sì máa jìyà ìwà àìṣòótọ́ tí ẹ hù* títí ẹni tó kẹ́yìn nínú yín fi máa kú sínú aginjù.+
34 Ogójì (40) ọjọ́+ lẹ fi ṣe amí ilẹ̀ náà, àmọ́ ogójì (40) ọdún+ lẹ máa fi jìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín, ọjọ́ kan fún ọdún kan, ọjọ́ kan fún ọdún kan, ẹ ó wá mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ta kò mí.*
35 “‘“Èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀. Ohun tí màá ṣe fún àwọn èèyàn burúkú yìí tí wọ́n kóra jọ láti ta kò mí nìyí: Inú aginjù yìí ni wọ́n máa ṣègbé sí, ibí ni wọ́n sì máa kú sí.+
36 Àwọn ọkùnrin tí Mósè rán lọ ṣe amí ilẹ̀ náà, tí wọ́n mú ìròyìn burúkú wá nípa ilẹ̀ náà,+ tí wọ́n sì wá mú kí gbogbo àpéjọ náà máa kùn sí i,
37 àní, Jèhófà+ máa kọ lu àwọn ọkùnrin tó mú ìròyìn burúkú wá nípa ilẹ̀ náà, wọ́n á sì kú níwájú rẹ̀.
38 Àmọ́ ó dájú pé Jóṣúà ọmọ Núnì àti Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè, tí wọ́n wà lára àwọn ọkùnrin tó lọ ṣe amí ilẹ̀ náà máa wà láàyè.”’”+
39 Nígbà tí Mósè sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀fọ̀ gidigidi.
40 Síbẹ̀, wọ́n dìde ní àárọ̀ kùtù, wọ́n sì gbìyànjú láti lọ sórí òkè náà, wọ́n sọ pé: “A ti ṣe tán láti lọ síbi tí Jèhófà sọ, torí a ti ṣẹ̀.”+
41 Àmọ́ Mósè sọ pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣe kọjá ohun tí Jèhófà pa láṣẹ? Ohun tí ẹ fẹ́ ṣe yìí kò ní yọrí sí rere.
42 Ẹ má gòkè lọ, torí Jèhófà ò sí pẹ̀lú yín; ṣe ni àwọn ọ̀tá+ yín máa ṣẹ́gun yín.
43 Àwọn ọmọ Ámálékì àti àwọn ọmọ Kénáánì máa bá yín jà,+ wọ́n á sì fi idà ṣẹ́gun yín. Torí pé ẹ ti fi Jèhófà sílẹ̀, Jèhófà ò ní tì yín lẹ́yìn.”+
44 Síbẹ̀, wọ́n ṣorí kunkun,* wọ́n sì lọ sí orí òkè+ náà, àmọ́ àpótí májẹ̀mú Jèhófà àti Mósè kò kúrò ní àárín ibùdó.+
45 Àwọn ọmọ Ámálékì àti àwọn ọmọ Kénáánì tí wọ́n ń gbé ní òkè yẹn wá sọ̀ kalẹ̀, wọ́n bá wọn jà, wọ́n sì ń tú wọn ká títí lọ dé Hóómà.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “oúnjẹ ni wọ́n jẹ́ fún wa.”
^ Tàbí “àwọsánmà tó rí bí òpó.”
^ Tàbí “iná tó rí bí òpó.”
^ Ní Héb., “bí ẹnì kan ṣoṣo.”
^ Tàbí “inú rere onífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”
^ Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
^ Ní Héb., “tí mo gbé ọwọ́ mi sókè.”
^ Ní Héb., “iṣẹ́ aṣẹ́wó tí ẹ ṣe.”
^ Tàbí “láti jẹ́ ọ̀tá mi.”
^ Lédè Hébérù, ó tún túmọ̀ sí “ìgbójú” tàbí “ìkọjá àyè.”

