Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí la rí kọ́ nínú dídé tí àpọ́sítélì Pétérù dé sílé ọkùnrin kan tó jẹ́ oníṣẹ́ awọ ṣáájú kó tó gba ìpè pé kó lọ sọ́dọ̀ Kọ̀nílíù?

Ìwé Ìṣe inú Bíbélì sọ pé, Pétérù dúró “ní Jópà fún ọjọ́ púpọ̀ díẹ̀ pẹ̀lú Símónì kan, tí ó jẹ́ oníṣẹ́ awọ,” tó ní “ilé kan lẹ́bàá òkun.” (Ìṣe 9:43; 10:6) Iṣẹ́ tí kò mọ́ tí ó sì ń buni kù làwọn Júù ka iṣẹ́ awọ sí. Ìwé Támọ́dì sọ pé, ọ̀rọ̀ àwọn oníṣẹ́ awọ burú ju ti àwọn tó ń kó ìgbẹ́ ẹran lọ. Iṣẹ́ tí Símónì ń ṣe gba pé kó máa fọwọ́ kan òkú ẹran nígbà gbogbo, èyí sì túmọ̀ sí pé ìgbà gbogbo ni yóò jẹ́ aláìmọ́ tó sì máa nílò ìwẹ̀nùmọ́. (Léfítíkù 5:2; 11:39) Gẹ́gẹ́ bí oríṣiríṣi ìwádìí lórí kókó yìí ti fi hàn, ó ṣeé ṣe kí Símónì máa lo omi òkun fún iṣẹ́ rẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀yìn ìlú ni ibi iṣẹ́ rẹ̀ wà, nítorí “òórùn burúkú” tó máa ń jáde látinú awọ.

Láìka gbogbo èyí sí, Pétérù kò rí ohun tó burú nínú dídé sílé Símónì. Èyí fi hàn pé, bíi ti Jésù, ó ṣeé ṣe kí Pétérù náà ti kẹ́kọ̀ọ́ láti yẹra fún ẹ̀tanú tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn Júù, èyí tí wọ́n máa ń ṣe sí àwọn èèyàn tí wọ́n kà sí aláìmọ́.—Mátíù 9:11; Lúùkù 7:36-50.

Kí ni ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé “ìwọ fúnra rẹ wí i”?

Nígbà tí Káyáfà tó jẹ́ àlùfáà àgbà àwọn Júù ní kí Jésù sọ ní gbangba tó bá jẹ́ pé Jésù ni Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, Jésù dá a lóhùn pé: “Ìwọ fúnra rẹ wí i.” (Mátíù 26:63, 64) Kí lóhun tí Jésù sọ yìí túmọ̀ sí?

Kì í ṣe pé Jésù fẹ́ fọgbọ́n yẹ ìbéèrè Káyáfà sílẹ̀. Àkànlò èdè àwọn Júù ni ọ̀rọ̀ náà, “ìwọ fúnra rẹ wí i,” wọ́n sì máa ń lò ó láti fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé ó jẹ́ òótọ́. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Támọ́dì Jerúsálẹ́mù, ìyẹn ìwé ìsìn àwọn Júù èyí tí wọ́n kọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin Sànmánì Kristẹni, sọ nípa ìdáhùn ọkùnrin Júù kan tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá rábì kan ti kú, ó ní: “Ìwọ wí i.” Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé, rábì náà ti kú lóòótọ́.

Jésù mọ̀ pé, àlùfáà àgbà láṣẹ láti fi òun sábẹ́ ìbúra pé kí òun sọ òtítọ́. Àmọ́, tí Jésù kò bá sọ nǹkan kan, á túmọ̀ sí pé Jésù kì í ṣe Kristi. Ohun tí Jésù sọ fún àlùfáà àgbà pé: “Ìwọ fúnra rẹ wí i” jẹ́ ìdáhùn tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ pé Jésù ni Kristi. Nínú ohun tí Máàkù kọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kan náà, nígbà tí Káyáfà fi dandan lé e pé kí Jésù sọ bóyá òun ni Mèsáyà, Jésù fi ìgboyà dá a lóhùn pé: “Èmi ni.”—Máàkù 14:62; tún wo Mátíù 26:25 àti Máàkù 15:2.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ibi tí wọ́n ti ń ṣe awọ ní Fez, lórílẹ̀-èdè Mòrókò