Àkọsílẹ̀ Máàkù 15:1-47

  • Jésù dé iwájú Pílátù (1-15)

  • Wọ́n fi ṣẹlẹ́yà ní gbangba (16-20)

  • Wọ́n kàn án mọ́gi ní Gọ́gọ́tà (21-32)

  • Ikú Jésù (33-41)

  • Wọ́n sìnkú Jésù (42-47)

15  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin, àní gbogbo Sàhẹ́ndìrìn, gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n de Jésù, wọ́n mú un lọ, wọ́n sì fà á lé Pílátù lọ́wọ́.+  Pílátù wá bi í pé: “Ṣé ìwọ ni Ọba Àwọn Júù?”+ Ó fèsì pé: “Ìwọ fúnra rẹ ti sọ ọ́.”+  Àmọ́ àwọn olórí àlùfáà ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀sùn kàn án.  Pílátù tún bẹ̀rẹ̀ sí í bi í pé: “Ṣé o ò ní fèsì rárá ni?+ Wo adúrú ẹ̀sùn tí wọ́n ń fi kàn ọ́.”+  Àmọ́ Jésù ò dáhùn mọ́, débi pé ó ya Pílátù lẹ́nu.+  Tí wọ́n bá ń ṣe àjọyọ̀, ó máa ń tú ẹlẹ́wọ̀n kan tí wọ́n bá fẹ́ sílẹ̀ fún wọn.+  Ní àkókò yẹn, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Bárábà wà nínú ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú àwọn tó dìtẹ̀ sí ìjọba, tí wọ́n sì pààyàn nígbà tí wọ́n ń dìtẹ̀.  Torí náà, àwọn èrò wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè ohun tí Pílátù máa ń ṣe fún wọn.  Ó dá wọn lóhùn pé: “Ṣé ẹ fẹ́ kí n tú Ọba Àwọn Júù sílẹ̀ fún yín?”+ 10  Torí Pílátù mọ̀ pé àwọn olórí àlùfáà ń ṣe ìlara rẹ̀ ni wọ́n ṣe fà á lé òun lọ́wọ́.+ 11  Àmọ́ àwọn olórí àlùfáà ru àwọn èrò náà sókè pé kí wọ́n ní kó tú Bárábà sílẹ̀ fún àwọn dípò rẹ̀.+ 12  Pílátù tún fún wọn lésì pé: “Kí wá ni kí n ṣe sí ẹni tí ẹ̀ ń pè ní Ọba Àwọn Júù?”+ 13  Wọ́n ké jáde lẹ́ẹ̀kan sí i pé: “Kàn án mọ́gi!”*+ 14  Àmọ́ Pílátù sọ fún wọn pé: “Kí ló dé? Nǹkan burúkú wo ló ṣe?” Síbẹ̀, wọ́n túbọ̀ kígbe pé: “Kàn án mọ́gi!”+ 15  Torí náà, kí Pílátù lè tẹ́ àwọn èrò náà lọ́rùn, ó tú Bárábà sílẹ̀ fún wọn; lẹ́yìn tó sì ní kí wọ́n na Jésù,+ ó fà á lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kàn án mọ́gi.+ 16  Àwọn ọmọ ogun wá mú un lọ sínú àgbàlá, ìyẹn inú ilé gómìnà, wọ́n sì pe gbogbo ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun jọ.+ 17  Wọ́n wọ aṣọ aláwọ̀ pọ́pù fún un, wọ́n wá fi ẹ̀gún hun adé, wọ́n sì dé e sí i lórí; 18  wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún un pé: “A kí ọ o,* ìwọ Ọba Àwọn Júù!”+ 19  Bákan náà, wọ́n ń fi ọ̀pá esùsú gbá a ní orí, wọ́n sì ń tutọ́ sí i lára, wọ́n kúnlẹ̀, wọ́n sì tẹrí ba* fún un. 20  Níkẹyìn, lẹ́yìn tí wọ́n fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n bọ́ aṣọ aláwọ̀ pọ́pù náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n sì wọ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ fún un. Wọ́n wá mú un jáde lọ kí wọ́n lè kàn án mọ́gi.+ 21  Bákan náà, wọ́n fi dandan mú ẹnì kan tó ń kọjá lọ, ìyẹn Símónì ará Kírénè, pé kó gbé òpó igi oró* rẹ̀. Ó ń bọ̀ láti ìgbèríko, òun ni bàbá Alẹkisáńdà àti Rúfọ́ọ̀sì.+ 22  Wọ́n wá mú un wá sí ibi tí wọ́n ń pè ní Gọ́gọ́tà, tó túmọ̀ sí “Ibi Agbárí.”+ 23  Ibẹ̀ ni wọ́n ti fẹ́ fún un ní wáìnì tí wọ́n fi òjíá sí kí wáìnì náà lè le,+ àmọ́ kò mu ún. 24  Wọ́n kàn án mọ́gi, wọ́n sì ṣẹ́ kèké lé aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ kí wọ́n lè pinnu ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan máa mú.+ 25  Ó ti wá di wákàtí kẹta,* wọ́n sì kàn án mọ́gi. 26  Wọ́n kọ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án pé: “Ọba Àwọn Júù.”+ 27  Bákan náà, wọ́n kan àwọn olè méjì mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ọ̀kan ní ọ̀tún rẹ̀ àti ọ̀kan ní òsì rẹ̀.+ 28 * —— 29  Àwọn tó ń kọjá lọ ń bú u, wọ́n sì ń mi orí wọn,+ wọ́n ń sọ pé: “Ṣíọ̀! Ìwọ tí o fẹ́ wó tẹ́ńpìlì palẹ̀, kí o sì fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ ọ,+ 30  gba ara rẹ là, kí o sọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí òpó igi oró.”* 31  Bákan náà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ láàárín ara wọn, wọ́n ń sọ pé: “Ó gba àwọn ẹlòmíì là; kò lè gba ara rẹ̀ là!+ 32  Kí Kristi, Ọba Ísírẹ́lì sọ̀ kalẹ̀ látorí òpó igi oró,* ká lè rí i, ká sì gbà gbọ́.”+ Àwọn tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ pàápàá ń fi ṣe ẹlẹ́yà.+ 33  Nígbà tó di wákàtí kẹfà,* òkùnkùn ṣú bo gbogbo ilẹ̀ náà títí di wákàtí kẹsàn-án.*+ 34  Ní wákàtí kẹsàn-án, Jésù ké jáde pé: “Élì, Élì, làmá sàbákìtanì?” tó túmọ̀ sí: “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?”+ 35  Nígbà tí àwọn kan lára àwọn tó dúró nítòsí gbọ́ èyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ẹ wò ó! Ó ń pe Èlíjà.” 36  Ẹnì kan wá sáré lọ rẹ kànrìnkàn sínú wáìnì kíkan, ó fi sórí ọ̀pá esùsú, ó sì fún un pé kó mu ún,+ ó ní: “Ẹ fi sílẹ̀! Ká wò ó bóyá Èlíjà máa wá gbé e sọ̀ kalẹ̀.” 37  Àmọ́ Jésù ké jáde, ó sì gbẹ́mìí mì.*+ 38  Aṣọ ìdábùú ibi mímọ́+ ya sí méjì látòkè dé ìsàlẹ̀.+ 39  Nígbà tí ọ̀gágun tó dúró ní ọ̀ọ́kán rẹ̀ rí i pé ó ti gbẹ́mìí mì, pẹ̀lú àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yìí, ó sọ pé: “Ó dájú pé Ọmọ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí.”+ 40  Àwọn obìnrin kan tún wà, tí wọ́n ń wòran láti ọ̀ọ́kán, lára wọn ni Màríà Magidalénì, Màríà ìyá Jémíìsì Kékeré àti Jósè àti Sàlómẹ̀,+ 41  àwọn tó máa ń tẹ̀ lé e, tí wọ́n sì máa ń ṣe ìránṣẹ́ fún un+ nígbà tó wà ní Gálílì àti ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin míì tó bá a gòkè wá sí Jerúsálẹ́mù. 42  Bó ṣe ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, tí ọjọ́ yẹn sì jẹ́ Ìpalẹ̀mọ́, ìyẹn ọjọ́ tó ṣáájú Sábáàtì, 43  Jósẹ́fù ará Arimatíà wá, ọ̀kan lára àwọn Ìgbìmọ̀ ni, ẹni tí wọ́n kà sí èèyàn dáadáa, tí òun náà ń retí Ìjọba Ọlọ́run. Ó fi ìgboyà wọlé lọ síwájú Pílátù, ó sì ní kó gbé òkú Jésù fún òun.+ 44  Àmọ́ Pílátù ń wò ó pé ó lè má tíì kú, ó wá ránṣẹ́ pe ọ̀gágun náà, ó bi í bóyá Jésù ti kú. 45  Torí náà, lẹ́yìn tí ọ̀gágun náà ti fi dá a lójú, ó gbà kí Jósẹ́fù máa gbé òkú náà lọ. 46  Lẹ́yìn tó ra aṣọ ọ̀gbọ̀* tó dáa, tó sì gbé e sọ̀ kalẹ̀, ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa náà dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì* kan+ tí wọ́n gbẹ́ sínú àpáta; ó wá yí òkúta sí ẹnu ọ̀nà ibojì náà.+ 47  Àmọ́ Màríà Magidalénì àti Màríà ìyá Jósè kò yéé wo ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “A júbà rẹ.”
Tàbí “forí balẹ̀.”
Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́sàn-án àárọ̀.
Ìyẹn, nǹkan bí aago méjìlá ọ̀sán.
Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán.
Tàbí “mí èémí àmíkẹ́yìn.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”