Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ìwà Àìṣòótọ́ Ni?

Ṣé Ìwà Àìṣòótọ́ Ni?

Ṣé Ìwà Àìṣòótọ́ Ni?

“Má ṣàlàyé bí gbogbo jàǹbá náà ṣe wáyé, ìyẹn kò ní kó ẹ sí ìyọnu.”

“Kò yẹ kó o sọ gbogbo bí ọ̀ràn ṣe rí fún àwọn aláṣẹ tó ń gba owó orí.”

“Kókó ibẹ̀ ni pé kí wọ́n máà ṣáà ti rí ẹ gbá mú.”

“Kí nìdí tó fi yẹ kó o rà á nígbà tó o lè rí i lọ́fẹ̀ẹ́?”

Ó ṢEÉ ṢE kó o gbọ́ irú ọ̀rọ̀ yìí tó o bá ní káwọn èèyàn gbà ẹ́ nímọ̀ràn lórí ọ̀ràn tó jẹ mọ́ owó. Àwọn kan rò pé àwọn ní ojútùú sí gbogbo nǹkan tó bá ṣẹlẹ̀. Àmọ́, ìbéèrè náà ni pé, Ṣé ojútùú tí kò ní àgàbàgebè nínú ni?

Àìṣòótọ́ gbalẹ̀ gbòde lónìí débi pé àwọn èèyàn sábà máa ń ka irọ́ pípa, jíjí ìwé wò àti olè jíjà sí ọ̀nà kan tó dáa láti bọ́ lọ́wọ́ ìjìyà, láti pawó wọlé tàbí láti tẹ̀ síwájú. Tó bá dọ̀rọ̀ jíjẹ́ olóòótọ́, àpẹẹrẹ tí kò dáa làwọn tó jẹ́ aṣáájú láwùjọ sábà máa ń fi lélẹ̀. Nínú ọgọ́rùn-ún ẹjọ́ tó wáyé lórílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Yúróòpù lọ́dún 2005 sí ọdún 2006, èyí tó jẹ mọ́ èrú àti ìkówójẹ lé ní márùn-ún dín láàádọ́rùn-ún. Ìyẹn kò sì kan ọ̀pọ̀ ẹjọ́ ìwà àìṣòótọ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, èyí táwọn èèyàn máa ń pè ní “ẹ̀ṣẹ̀ tí kò tó nǹkan.” Kò yani lẹ́nu pé àwọn aṣáájú lẹ́nu iṣẹ́ ajé àtàwọn olóṣèlú lórílẹ̀-èdè yẹn ń ṣe màgòmágó nínú èyí tí wọ́n ti lo ayédèrú ìwé ẹ̀rí kí ọwọ́ wọn bàa lè tẹ ohun tí wọ́n ń wá.

Láìka bí aráyé ṣe bàjẹ́ bàlùmọ̀ nínú ìwà àìṣòótọ́ sí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣì fẹ́ ṣe ohun tó tọ́. Ó ṣeé ṣe kó o wà lára wọn, ó sì lè jẹ́ ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run ló mú kó o fẹ́ láti ṣe ohun tó wù ú. (1 Jòhánù 5:3) Ó lè máa ṣe ẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó kọ̀wé pé: “Àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé a ní ẹ̀rí-ọkàn aláìlábòsí, gẹ́gẹ́ bí a ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18) Fún ìdí yìí, a rọ̀ ẹ́ pé kó o ṣàgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ohun tó lè dán ẹnì kan wò bó ṣe ń fẹ́ láti máa hùwà “láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” A tún máa jíròrò àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ranni lọ́wọ́ tí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ bá wáyé.

Ta Ló Yẹ Kó Sanwó?

Lọ́jọ́ kan tí ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Lisa a ń wa ọkọ̀ lọ, ó ṣàdédé kọlu ọkọ̀ míì. Ẹnì kankan ò fara pa, àmọ́ ọkọ̀ méjèèjì ló bà jẹ́. Lórílẹ̀-èdè tó ń gbé, owó tó pọ̀ ni ọ̀dọ́ tó jẹ́ awakọ̀ máa ń san fún àwọn abánigbófò lórí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, owó yẹn sì máa ń pọ̀ sí i béèyàn bá ṣe ń wakọ̀ jáàmù. Níwọ̀n ìgbà tí Gregor tó jẹ́ ìbátan Lisa tó sì dàgbà jù ú lọ ti wà nínú ọkọ̀ náà, ọ̀rẹ́ wọn kan dábàá pé kí wọ́n sọ pé Gregor ló wa ọkọ̀ náà. Ìyẹn ni kò ní jẹ́ kí Lisa san owó gegere náà fún àwọn abánigbófò. Ojútùú yìí dà bíi pé ó mọ́gbọ́n dání. Kí ni Lisa máa ṣe?

Owó tí àwọn èèyàn máa ń san fún ilé iṣẹ́ abánigbófò ni ilé iṣẹ́ yìí máa ń san fún àwọn oníbàárà tó bá béèrè owó. Nítorí náà, tí Lisa bá tẹ̀ lé àbá ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí, ńṣe ló ń fẹ́ káwọn oníbàárà míì san owó fún ọkọ̀ rẹ̀ tó wà jáàmù láti inú owóbówó táwọn yẹn san. Yàtọ̀ sí pé ó máa parọ́, ó tún máa ja àwọn ẹlòmíì lólè. Ohun kan náà ló máa já sí téèyàn bá parọ́ nínú ìròyìn jàǹbá tó ṣẹlẹ̀ kó bàa lè rí owó tó pọ̀ gbà lọ́wọ́ ilé iṣẹ́ abánigbófò.

Ìyà tí òfin máa fi jẹni lè mú káwọn èèyàn má ṣe hu irú ìwà àìṣòótọ́ yẹn. Àmọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ohun tó ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ tó fi yẹ ká yẹra fún ìwà àìṣòótọ́. Ọ̀kan lára Òfin Mẹ́wàá sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè.” (Ẹ́kísódù 20:15) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún àṣẹ yẹn pa fún àwọn Kristẹni, ó ní: “Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́.” (Éfésù 4:28) Ṣíṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lórí irú ọ̀rọ̀ ìbánigbófò bẹ́ẹ̀ máa fi hàn pé èèyàn ń yẹra fún ohun tí Ọlọ́run dẹ́bi fún. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún ń fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run àtàwọn ọmọnìkejì rẹ.—Sáàmù 119:97.

“Ẹ San Àwọn Ohun ti Késárì Padà fún Késárì”

Oníṣòwò ni Peter. Nítorí kọ̀ǹpútà olówó gọbọi kan tó fẹ́ rà, ẹni tó ń bá a bójú tó ọ̀ràn ìnáwó sọ fún un pé kó sọ fún ìjọba pé kó dín owó orí tó máa ń san kù. Àwọn oníṣòwò bíi Peter máa ń ra irú ohun èlò bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì máa ń gba ẹ̀dínwó owó orí. Lóòótọ́, Peter kò ra kọ̀ǹpútà náà, ó sì ṣeé ṣe kí ìjọba má ṣèwádìí bóyá ó rà á tàbí kò rà á. Àmọ́ tó bá ṣe ohun tí ẹni tó ń bá a bójú tó ọ̀ràn ìnáwó ní kó ṣe yìí, owó orí tó máa san fún ìjọba máa dín kù gan-an. Kí ló yẹ kó ṣe? Kí ló máa ràn án lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó tọ́?

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni ìgbà ayé rẹ̀ pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga . . . Ẹ fi ẹ̀tọ́ gbogbo ènìyàn fún wọn, ẹni tí ó béèrè fún owó orí, ẹ fún un ní owó orí; ẹni tí ó béèrè fún owó òde, ẹ fún un ní owó òde.” (Róòmù 13:1, 7) Àwọn tó bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa san gbogbo owó orí tí àwọn aláṣẹ bá béèrè. Àmọ́ ṣá o, tí òfin ilẹ̀ kan bá dín owó orí tí àwọn kan ń san kù tàbí ti okòwò, kò burú láti gbà á tá a bá lẹ́tọ̀ọ́ sí i.

Àpẹẹrẹ míì rèé tó ní í ṣe pẹ̀lú sísan owó orí. Káfíńtà ni David, wọ́n sì gbà á sí ilé iṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń fi igi ṣe onírúurú ohun èlò ilé. Àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ará ilé rẹ̀ ní kó bá àwọn ṣe àwọn ohun èlò ilé, ó sì ń ṣe àwọn nǹkan yìí nílé iṣẹ́ náà, lẹ́yìn ìgbà tó bá ti parí iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀. Wọ́n láwọn máa fún un lówó tó pọ̀ gan-an ju èyí tó ń gbà ní ilé iṣẹ́ náà, àmọ́ wọn ò fẹ́ kó sọ fún àwọn aláṣẹ ilé iṣẹ́ náà. Nítorí náà, kò ní sí àkọ́sílẹ̀ pé wọ́n ṣe iṣẹ́ kankan, kò sì ní sídìí láti san owó orí. Ọ̀pọ̀ ló gbà pé kò sóhun tó burú nínú èyí, nítorí pé gbogbo àwọn tọ́ràn kàn ló máa jàǹfààní nínú rẹ̀. Nítorí pé David fẹ́ láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ojú wo ló máa fi wo iṣẹ́ téèyàn ṣe láì gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ ilé iṣẹ́?

Lóòótọ́ ọwọ́ lè má tẹ ẹni tó bá ń ṣe irú iṣẹ́ yìí, àmọ́ kò ní san owó orí tó yẹ kí ìjọba gbà. Jésù pa á láṣẹ pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Mátíù 22:17-21) Jésù sọ ọ̀rọ̀ yìí kí àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ lè ní èrò tó tọ́ nípa sísan owó orí. Àwọn aláṣẹ ìjọba tí Jésù pè ní Késárì ka gbígba owó orí sí ẹ̀tọ́ wọn. Nítorí náà, àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ka sísan owó orí sí àṣẹ tó bá Ìwé Mímọ́ mu.

Jíjí Ìwé Wò Nígbà Ìdánwò

Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Marta tó ń lọ sí ilé ìwé gíga ń múra ìdánwò àṣekágbá. Nítorí pé tó bá fẹ́ rí iṣẹ́ tó dáa, èsì ìdánwò rẹ̀ gbọ́dọ̀ dára gan-an, èyí mú kó fi ọ̀pọ̀ wákàtí kàwé. Àwọn kan lára àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ náà ti múra fún ìdánwò yìí, àmọ́ lọ́nà tó yàtọ̀. Wọ́n fẹ́ máa fi ẹ̀rọ atanilólobó, fóònù alágbèéká àtàwọn ẹ̀rọ míì jí ìwé wò kí wọ́n bàa lè gba máàkì tó pọ̀. Ṣé Marta á ṣe ohun tí gbogbo èèyàn ń ṣe yìí kó bàa lè ní máàkì tó pọ̀?

Nítorí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń jí ìwé wò, àwọn èèyàn rò pé kò sí ohun tó burú níbẹ̀. Wọ́n máa ń sọ pé, “kókó ibẹ̀ ni pé kí wọ́n máà ṣáà ti rí ẹ gbá mú.” Àmọ́ àwọn Kristẹni tòótọ́ kò fara mọ́ irú èrò yìí. Lóòótọ́, olùkọ́ lè máà rí ẹni tó jí ìwé wò, àmọ́ ẹnì kan wà tó rí i. Jèhófà Ọlọ́run mọ ohun tá a ṣe, a sì máa jíhìn fún un. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kò sì sí ìṣẹ̀dá tí kò hàn kedere sí ojú rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.” (Hébérù 4:13) Mímọ̀ tá a mọ̀ pé Ọlọ́run ń wò wá, pé ó fẹ́ ká máa ṣe ohun tó tọ́ máa jẹ́ ká jẹ́ olóòótọ́ nígbà tá a bá ń ṣe ìdánwò ní ilé ìwé, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

Kí Lo Máa Ṣe?

Lisa, Gregor, Peter, David àti Marta rí bí ipò tí wọ́n bá ara wọn ṣe gbẹgẹ́ tó. Wọ́n pinnu láti jẹ́ olóòótọ́, kí wọ́n bàa lè tipa bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀rí-ọkàn tó mọ́, kí wọ́n sì lè máa jẹ́ olóòótọ́ nìṣó. Kí lo máa ṣe tó o bá bá ara rẹ nírú ipò yìí?

Àwọn ọ̀rẹ́, ọmọ kíláàsì àtàwọn ará ilé rẹ lè máà rí ohun tó burú nínú irọ́ pípa, jíjí ìwé wò tàbí olè jíjà. Kódà, wọ́n lè fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ kó o lè lọ́wọ́ nínú ohun tí wọ́n ń ṣe. Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó tọ́ láìka bí wọ́n ṣe ń fúngun mọ́ ẹ pé kó o hùwà àìṣòótọ́?

Má gbàgbé pé bó o bá ṣe nǹkan bí Ọlọ́run ṣe fẹ́, ìyẹn máa jẹ́ kó o ní ẹ̀rí-ọkàn tó mọ́, wàá rí ojú rere Ọlọ́run, á sì tún bù kún ẹ. Dáfídì Ọba kọ̀wé pé: “Jèhófà, ta ni yóò jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ? Ta ni yóò máa gbé ní òkè ńlá mímọ́ rẹ? Ẹni tí ń rìn láìlálèébù, tí ó sì ń fi òdodo ṣe ìwà hù tí ó sì ń sọ òtítọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ̀. . . . Ẹni tí ó bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, a kì yóò mú un ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.” (Sáàmù 15:1-5) Kéèyàn ní ẹ̀rí-ọkàn tó mọ́ àti kéèyàn jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run ọ̀run ṣe pàtàkì gan-an ju ohun téèyàn fi ìwà àìṣòótọ́ kó jọ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]

“Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́”

Ọ̀wọ̀ fún òfin Ọlọ́run àti ìfẹ́ ọmọnìkejì ló ń mú ká jẹ́ olóòótọ́ tó bá dọ̀ràn sísan owó ìbánigbófò

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]

“Ẹ fi ẹ̀tọ́ gbogbo ènìyàn fún wọn, ẹni tí ó béèrè fún owó orí, ẹ fún un ní owó orí.”

Láti rí ojú rere Ọlọ́run, a ní láti san gbogbo owó orí tí òfin béèrè

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]

“Ohun gbogbo wà . . . ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.”

Lóòótọ́, ọwọ́ olùkọ́ lè má tẹ̀ wá pé a jí ìwé wò, àmọ́ a fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

“Olè Jíjà Tó Fara Sin”

Ọ̀rẹ́ rẹ kan ra ètò orí kọ̀ǹpútà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe, ìwọ náà sì fẹ́ láti ní irú rẹ̀. Ó ní òun á bá ẹ ṣe ẹ̀dà kan, torí náà, o kò ní láti lọ ra tìrẹ. Ṣé àìṣòótọ́ nìyẹn?

Nígbà tí ẹnì kan bá ra ètò orí kọ̀ǹpútà kan, ó fi hàn pé ó ti fara mọ́ àdéhùn táwọn tí wọ́n ṣe ètò náà gbé kalẹ̀ lórí bó ṣe máa lò ó nìyẹn. Àdéhùn náà lè sọ pé orí kọ̀ǹpútà kan ṣoṣo ni ẹni tó ra ètò náà lè gbe sí, ibẹ̀ nìkan ló sì ti lè lò ó. Torí náà, ẹni tó bá ṣe ẹ̀dà ètò orí kọ̀ǹpútà náà fún ẹlòmíì, kò tẹ̀ lé àdéhùn tó ti wà nílẹ̀ nìyẹn, kò sì bá òfin mu. (Róòmù 13:4) Olè jíjà ni téèyàn bá ṣe ẹ̀dà rẹ̀, torí pé ìyẹn ò ní jẹ́ kí owó tó yẹ kó wọlé fún ẹni tó ṣe é wọlé fún un.—Éfésù 4:28.

Àwọn kan lè sọ pé, ‘Kò sẹ́ni tó máa mọ̀.’ Ó lè jóòótọ́, àmọ́ ká má gbàgbé ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Gbogbo wa la fẹ́ ká jèrè iṣẹ́ wa, a sì fẹ́ káwọn èèyàn ṣe nǹkan ìní wa bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ ṣe ohun kan náà sí àwọn ẹlòmíì. A kì í lọ́wọ́ nínú olè jíjà “tó fara sin,” irú bíi gbígbé iṣẹ́ ọpọlọ b tẹ́nì kan ṣe.—Ẹ́kísódù 22:7-9.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

b Iṣẹ́ ọpọlọ yìí ni nǹkan tẹ́nì kan ṣe tí kò fúnni láṣẹ láti ṣe ẹ̀dà rẹ̀, irú bí orin, ìwé tàbí ètò orí kọ̀ǹpútà, bóyá èèyàn ṣe é sorí bébà ni tàbí ó gbé sorí ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́. Lílo orúkọ ilé iṣẹ́, ẹ̀tọ́ oní-nǹkan, àṣírí ilé iṣẹ́ àti ìkéde láìgba àṣẹ tún wà lára nǹkan tá à ń sọ yìí.