Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ìwọ Yóò Hùwà Lọ́nà Ìdúróṣinṣin”

“Ìwọ Yóò Hùwà Lọ́nà Ìdúróṣinṣin”

Sún Mọ́ Ọlọ́run

“Ìwọ Yóò Hùwà Lọ́nà Ìdúróṣinṣin”

2 SÁMÚẸ́LÌ 22:26

ỌGBẸ́ kékeré kọ́ ló máa ń dá síni lọ́kàn nígbà tí ẹnì kan téèyàn fọkàn tán bá jáni kulẹ̀. Irú ìjákulẹ̀ yìí pọ̀ nínú ayé aláìṣòótọ́ yìí. (2 Tímótì 3:1-5) Ǹjẹ́ ẹnì kankan wà tá a lè gbára lé pátápátá? Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ayé àtijọ́.

Ní gbogbo ìgbà tí Dáfídì fi gbé láyé, ó dojú kọ ìjákulẹ̀ tó lékenkà. Sọ́ọ̀lù tó jẹ́ ọba àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì jowú rẹ̀, ó sì mú kó sá jáde kúrò nílùú, tó wá ń lọ gbé níbòmíì. Nínú ìdílé òun fúnra rẹ̀, Míkálì tó jẹ́ ìyàwó Dáfídì kò finú kan bá ọkọ rẹ̀ lò, dípò ìyẹn ńṣe ló ń “tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀ nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (2 Sámúẹ́lì 6:16) Áhítófẹ́lì tó jẹ́ agbani-nímọ̀ràn tí Dáfídì fọkàn tán di ọ̀dàlẹ̀, ó sì bá wọn lọ́wọ́ nínú ọ̀tẹ̀ sí Dáfídì. Ta ni aṣáájú nínú ọ̀tẹ̀ yìí? Áà, Ábúsálómù tó jẹ́ ọmọ Dáfídì ni! Lójú gbogbo bí wọ́n ṣe dalẹ̀ Dáfídì yìí, ṣé ó sọ pé òun kò fọkàn tán ẹnì kankan mọ́, kó sì sọ pé kò sẹ́ni tó ṣe é fọkàn tán?

Ìdáhùn rẹ̀ wà nínú ọ̀rọ̀ tí Dáfídì kọ sílẹ̀ nínú ìwé 2 Sámúẹ́lì 22:26. Dáfídì tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ dúró sán-ún-sán-ún kọ ewì kan, ó sọ nípa Jèhófà Ọlọ́run pé: “Ìwọ yóò hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin sí ẹni ìdúróṣinṣin.” Ó dá Dáfídì lójú pé, kò sí bí àwọn èèyàn ṣe lè já òun kulẹ̀ tó, Jèhófà kò ní já òun kulẹ̀.

Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ yìí. Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí “hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin” tún lè túmọ̀ sí “hùwà lọ́nà inúure.” Ìfẹ́ ló máa jẹ́ kí èèyàn dúró ti ẹnì kan tọkàntọkàn. Jèhófà máa ń dúró ti àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí i tìfẹ́tìfẹ́. a

Tún kíyè sí i pé, jíjẹ́ adúróṣinṣin kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán, ohun téèyàn máa ń ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀ ni. Jèhófà hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin, Dáfídì rí i bẹ́ẹ̀ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i. Lákòókò tí nǹkan dojú rú nínú ìgbésí ayé Dáfídì, Jèhófà ràn án lọ́wọ́, ó dáàbò bò ó, ó sì tọ́ olóòótọ́ ọba yìí sọ́nà. Dáfídì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún bó ṣe dá a nídè “kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀.”—2 Sámúẹ́lì 22:1.

Kí la lè rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ Dáfídì yìí? Jèhófà kì í yí pa dà. (Jákọ́bù 1:17) Kò yí àwọn ìlànà rẹ̀ pa dà, ó sì máa ń mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Nínú sáàmù míì tí Dáfídì kọ, ó sọ pé: “Jèhófà . . . kì yóò sì fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀.”—Sáàmù 37:28.

Jèhófà mọyì rẹ̀ tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin. Ó ka ìdúróṣinṣin wa sí ohun iyebíye, ó sì rọ̀ wá pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ òun nípa jíjẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn ẹlòmíì. (Éfésù 4:24; 5:1) Tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin lọ́nà yìí, ó dájú pé kò ní fi wá sílẹ̀ láé. Kò sí báwọn èèyàn ṣe lè já wa kulẹ̀ tó, a lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa hùwà sí wa lọ́nà ìdúróṣinṣin, á ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìṣòro èyíkéyìí tó lè dé bá wa. Ǹjẹ́ kò wù ẹ́ láti sún mọ́ Jèhófà, “ẹni ìdúróṣinṣin”?—Ìṣípayá 16:5.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìwé 2 Sámúẹ́lì 22:26 bá ohun tó wà nínú Sáàmù 18:25 mu. Báyìí ni wọ́n ṣe túmọ̀ sáàmù yìí nínú ìtumọ̀ Bíbélì kan: “Ìwọ máa ń fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn sí àwọn adúróṣinṣin.”—Bíbélì The Psalms for Today.