Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọmọkùnrin Kan Gba Ẹ̀mí Pọ́ọ̀lù Là

Ọmọkùnrin Kan Gba Ẹ̀mí Pọ́ọ̀lù Là

Kọ́ Ọmọ Rẹ

Ọmọkùnrin Kan Gba Ẹ̀mí Pọ́ọ̀lù Là

ṢÓ O mọ̀ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láwọn mọ̀lẹ́bí tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù? a— Obìnrin kan tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí Pọ́ọ̀lù àtọmọ obìnrin náà wà lára wọn. Ọmọ mọ̀lẹ́bí Pọ́ọ̀lù náà sì gba ẹ̀mí Pọ́ọ̀lù là! A ò mọ orúkọ ọmọkùnrin yẹn, bẹ́ẹ̀ la ò sì mọ orúkọ màmá ẹ̀, àmọ́ a mohun tó ṣe. Ṣéwọ náà á fẹ́ mohun tó ṣe?—

Pọ́ọ̀lù ṣẹ̀ṣẹ̀ pa dà dé láti ìrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kẹta ni, ìlú Jerúsálẹ́mù ló sì wà. Ó ṣeé ṣe kí ìṣẹ̀lẹ̀ tá à ń sọ yìí wáyé lọ́dún 56 Sànmánì Kristẹni. Wọ́n ti fàṣẹ ọba mú Pọ́ọ̀lù, ó sì gbọ́dọ̀ jẹ́jọ́. Àmọ́ àwọn ọ̀tá Pọ́ọ̀lù ò fẹ́ kí wọ́n gbẹ́jọ́ Pọ́ọ̀lù. Ṣe ni wọ́n fẹ́ pa á! Torí náà, wọ́n ṣètò pé káwọn ogójì [40] ọkùnrin lọ fara pa mọ́ sójú ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù máa gbà kọjá kí wọ́n lè pa á.

Àmọ́, ọmọkùnrin náà gbọ́ nípa ohun táwọn èèyàn wọ̀nyẹn fẹ́ ṣe. Ṣó o mohun tó ṣe?— Ó lọ sọ fún Pọ́ọ̀lù. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Pọ́ọ̀lù sọ fún ọmọ ogun kan pé: “Mú ọ̀dọ́kùnrin yìí lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun, nítorí ó ní ohun kan láti ròyìn.” Ọmọ ogun yẹn sì mú ọ̀dọ́kùnrin náà lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun Kíláúdíù Lísíà, ó sì sọ fún ọ̀gágun náà pé ọ̀dọ́kùnrin yìí ní ọ̀rọ̀ pàtàkì kan tó fẹ́ bá a sọ. Kíláúdíù mú ọmọ mọ̀lẹ́bí Pọ́ọ̀lù yìí lọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ọmọ náà sì ṣàlàyé gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún un.

Kíláúdíù wá kìlọ̀ fún ọmọkùnrin yìí pé: “Má ṣẹnu fóró sọ fún ẹnikẹ́ni pé o ti mú nǹkan wọ̀nyí ṣe kedere sí mi.” Lẹ́yìn náà ló wá pe méjì lára àwọn ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n lọ múra igba [200] ọmọ ogun sílẹ̀, àwọn àádọ́rin [70] ẹlẹ́ṣin àti igba [200] àwọn ológun tó máa ń fi ọ̀kọ̀ jà, kí wọ́n lè lọ sí Kesaréà. Ní déédéé aago mẹ́sàn-án alẹ́ ọjọ́ yẹn, àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti àádọ́rin [470] ọkùnrin yìí gbéra, wọ́n sì lọ fa Pọ́ọ̀lù lé Fẹ́líìsì, tó jẹ́ Gómìnà Ìlú Róòmù, lọ́wọ́ ní Kesaréà. Nínú lẹ́tà kan tí Kíláúdíù kọ sí Fẹ́líìsì, ó jẹ́ kó mọ báwọn ọ̀tá ṣe gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Pọ́ọ̀lù.

Ìgbà táwọn Júù wọ̀nyí ò rí Pọ́ọ̀lù pa lójú ọ̀nà, wọ́n bá forí lé Kesaréà kí wọ́n lè lọ fẹ̀sùn kàn án nílé ẹjọ́. Àmọ́ ẹ̀sùn wọn ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, wọn ò rí nǹkan kan sọ láti fi hàn pé Pọ́ọ̀lù ṣohun kan tí kò dáa. Síbẹ̀, wọ́n ṣì pàpà fi Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n fún odindi ọdún méjì. Pọ́ọ̀lù wá pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sílùú Róòmù, wọ́n sì gbà á láyè láti lọ síbẹ̀.—Ìṣe 23:16–24:27; 25:8-12.

Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìtàn nípa ọmọkùnrin tó gba ẹ̀mí Pọ́ọ̀lù là yìí?— A kẹ́kọ̀ọ́ pé ó gba ìgboyà láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tó yẹ káwọn ẹlòmíì gbọ́, tá a bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, a lè gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là. Kódà nígbà tí Jésù mọ̀ pé àwọn ọ̀tá ‘ń wá ọ̀nà láti pa òun,’ ó ṣì ń bá a nìṣó láti máa wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ohun tí Jésù ní káwa náà máa ṣe nìyẹn. Ṣé a máa ṣe bẹ́ẹ̀? A máa lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá nígboyà bíi ti ọmọ mọ̀lẹ́bí Pọ́ọ̀lù.—Jòhánù 7:1; 15:13; Mátíù 24:14; 28:18-20.

Pọ́ọ̀lù gba Tímótì tó jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ̀ nímọ̀ràn pé: “Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ. Dúró nínú nǹkan wọ̀nyí, nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.” (1 Tímótì 4:16) Ó dájú pé ọmọ mọ̀lẹ́bí Pọ́ọ̀lù fi ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún wa yìí sílò. Ṣéwọ náà á ṣe bẹ́ẹ̀?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó bá jẹ́ pé ọmọdé lò ń kàwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kọ́mọ náà sọ tinú ẹ̀.

Ìbéèrè:

○ Àwọn wo ni mọ̀lẹ́bí Pọ́ọ̀lù, ẹ̀kọ́ wo la sì kọ́ nípa wọn?

○ Kí ni ọmọ mọ̀lẹ́bí Pọ́ọ̀lù ṣe láti gba ẹ̀mí Pọ́ọ̀lù là?

○ Kí la lè ṣe, láti fi gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là ká lè fi hàn pé a ṣègbọràn sọ́rọ̀ Jésù?