Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 KỌ́ ỌMỌ RẸ

Pétérù Parọ́, Ananíà Náà Parọ́​—⁠Ẹ̀kọ́ Wo Ni Èyí Kọ́ Wa?

Pétérù Parọ́, Ananíà Náà Parọ́​—⁠Ẹ̀kọ́ Wo Ni Èyí Kọ́ Wa?

Kí ni irọ́? Tí o bá sọ ohun kan tí ìwọ fúnra rẹ mọ̀ pé kì í ṣe òótọ́, o parọ́ nìyẹn. Ṣé o ti parọ́ rí? * Kódà àwọn àgbàlagbà kan tó fẹ́ràn Ọlọ́run ti parọ́ rí. Ó ṣeé ṣe kí o tiẹ̀ mọ ẹnì kan tó parọ́ nínú Bíbélì. Pétérù ni orúkọ rẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn méjìlá tó jẹ́ àpọ́sítélì Jésù ni. Gbọ́ ohun tó mú kó parọ́.

Nígbà tí wọ́n mú Jésù, wọ́n mú un lọ sí ilé àlùfáà àgbà. Ní ọwọ́ ìdájí, Pétérù wọnú àgbàlá ilé àlùfáà, ṣùgbọ́n àwọn èèyàn kò mọ̀ pé Pétérù ni. Nígbà tó yá, ìmọ́lẹ̀ iná tó ń jó jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin àlùfáà àgbà tó ṣílẹ̀kùn fún Pétérù dá a mọ̀. Ó wá sọ fún Pétérù pé: “Ìwọ, náà, wà pẹ̀lú Jésù.” Ẹ̀rù ba Pétérù, ló bá sọ pé rárá, òun kọ́.

Bíbélì sọ pé nígbà tó yá “ọmọdébìnrin mìíràn ṣàkíyèsí rẹ̀.” Òun náà tún sọ pé: “Ọkùnrin yìí wà pẹ̀lú Jésù.” Pétérù tún parọ́ pé òun kọ́. Nígbà tó ṣe díẹ̀ sí i, àwọn míì tún wá bá Pétérù, wọ́n sọ pé: “Dájúdájú, ìwọ pẹ̀lú jẹ́ ọ̀kan lára wọn.”

Àyà Pétérù wá ń já. Ló bá tún parọ́ ní ẹ̀ẹ̀kẹta, ó ní: “Èmi kò mọ ọkùnrin náà!” Àkùkọ kan wá kọ. Jésù wá yíjú wo Pétérù, kíá ni Pétérù sì rántí ohun tí Jésù sọ fún un ní wákàtí mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn. Ohun tí Jésù sọ fún un ni pé: “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ yóò sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi ní ìgbà mẹ́ta.” Pétérù wá bú sẹ́kún. Ohun tó ṣe yẹn dùn ún gan-an, ó sì ronú pìwà dà.

Ǹjẹ́ irú nǹkan yìí lè ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà?— Ká sọ pé o wà ní ilé ìwé lọ́jọ́ kan, o sì gbọ́ tí àwọn ọmọ ilé ìwé rẹ ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀kan nínú wọn sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í kí àsíá.” Òmíràn sọ pé: “Wọn kì í ṣe ọjọ́ ìbí.” Ẹlòmíràn sì sọ pé: “Wọn kò gba Jésù gbọ́, torí wọn kì í ṣe Kérésìmesì.” Ọ̀kan nínú wọn wá kọjú sí ẹ, ó ní: “Ṣebí Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ìwọ náà, àbí?” Kí ni wàá sọ?

 Ó máa dáa kí o ti múra bí o ṣe máa dáhùn lọ́nà tó dára sílẹ̀ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ tó ṣẹlẹ̀. Pétérù kò múra sílẹ̀ rárá. Torí náà, nígbà tí wọ́n bi í ní ìbéèrè, ó parọ́! Àmọ́, ó ronú pìwà dà, Ọlọ́run sì dárí jì í.

Ẹlòmíì tó tún parọ́ lára àwọn tó kọ́kọ́ jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù ni Ananíà. Ọlọ́run kò dárí ji òun àti ìyàwó rẹ̀ tó ń jẹ́ Sáfírà. Ṣe ni àwọn méjèèjì jọ pinnu láti parọ́. Jẹ́ ká wo ìdí tí Ọlọ́run kò fi dárí ji Ananíà àti Sáfírà.

Ní ọjọ́ kẹwàá lẹ́yìn tí Jésù kúrò láàárín àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, tó sì pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run ní ọ̀run, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] èèyàn ló ṣèrìbọmi ní Jerúsálẹ́mù. Ọ̀pọ̀ wọn ló jẹ́ pé ọ̀nà tó jìn ni wọ́n ti wá ṣe ayẹyẹ Pẹ́ńtíkọ́sì ní Jerúsálẹ́mù. Lẹ́yìn tí àwọn wọ̀nyí di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, wọ́n fẹ́ láti dúró díẹ̀ níbẹ̀, kí wọ́n lè túbọ̀ mọ̀ sí i nípa ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́. Torí náà, àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù fi owó ara wọn tọ́jú àwọn tó dúró yìí.

Ananíà àti ìyàwó rẹ̀ ta ilẹ̀ wọn kan, kí wọ́n lè fi owó rẹ̀ ran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi lọ́wọ́. Nígbà tí Ananíà kó owó ilẹ̀ tí ó tà náà wá fún àwọn àpọ́sítélì, ó sọ pé gbogbo rẹ̀ ni òun kó wá. Àmọ́ irọ́ ló pa! Ó ti tọ́jú díẹ̀ pa mọ́ nínú rẹ̀! Ọlọ́run wá jẹ́ kí Pétérù mọ ohun tí Ananíà ṣe yìí. Torí náà Pétérù sọ fún un pé: “Kì í ṣe ènìyàn ni o ṣèké sí, bí kò ṣe Ọlọ́run.” Bí Ananíà ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó ṣubú lulẹ̀ ó sì kú! Ní nǹkan bí wákàtí mẹ́tà lẹ́yìn ìyẹn, ìyàwó rẹ̀ wọlé wá sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì. Torí kò tíì gbọ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkọ rẹ̀, òun náà parọ́. Ló bá ṣubú lulẹ̀, ó sì kú.

Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n tí èyí kọ́ wa ni pé: Ó ṣe pàtàkì pé ká máa sọ òótọ́! Gbogbo wa pátá ni èyí kàn! Ìdí ni pé gbogbo wa ni a máa ń ṣe àṣìṣe, pàápàá nígbà tí a kò bá tíì dàgbà. Ǹjẹ́ kò dùn mọ́ ẹ nínú pé Jèhófà fẹ́ràn rẹ àti pé ó máa dárí jì ẹ́ bó ṣe dárí ji Pétérù?— Àmọ́ o, máa rántí pé a gbọ́dọ̀ máa sọ òótọ́. Tún rántí pé, tí a bá parọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni. Torí náà, a gbọ́dọ̀ bẹ Ọlọ́run pé kó jọ̀ọ́, kó dárí jì wá. Ó jọ pé ohun tí Pétérù ṣe gan-an nìyẹn, tí Ọlọrun sì dárí jì í. Tí àwa náà bá rí i dájú pé a kò parọ́ mọ́, Ọlọ́run máa dárí jì wá!

Kà á nínú Bíbélì rẹ

^ ìpínrọ̀ 3 Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ tinú rẹ̀.