Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Nínú àdúrà àwòṣe tí Jésù gbà, ṣé ohun tó fi ń yé wa ni pé wọ́n ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lọ́run nígbà náà lọ́hùn-ún bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò tíì lé àwọn áńgẹ́lì burúkú jáde kúrò lọ́run?

Gẹ́gẹ́ bí Mátíù 6:10 ṣe wí, Jésù sọ pé: “Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” Ọ̀nà méjì la lè gbà lóye ẹ̀bẹ̀ yìí. Ọ̀nà àkọ́kọ́ ni pé ó jẹ́ ẹ̀bẹ̀ pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí àwọn tọ̀run ti ń ṣe é, tàbí lọ́nà kejì, pé ó jẹ́ ẹ̀bẹ̀ pé kí á ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ní ayé àti ní ọ̀run. a Ohun tí gbólóhùn náà, “kí ìjọba rẹ dé,” tí Jésù sọ ṣáájú rẹ̀ túmọ̀ sí fi hàn pé èyí tá a sọ pé ó jẹ́ ọ̀nà kejì yìí ló bá Ìwé Mímọ́ mu jù lọ. Ìyẹn ló sì fi bí ọ̀ràn ṣe jẹ́ nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé hàn àti bó ṣe jẹ́ nígbà pípẹ́ lẹ́yìn tó kúrò láyé. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?

Ìwé Ìṣípayá sọ ohun méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ìfilọ́lẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run yọrí sí. Ti àkọ́kọ́ jẹ mọ́ ọ̀run fúnra rẹ̀, ti ìkejì sì jẹ mọ́ ilẹ̀ ayé. Ìṣípayá 12:7-9, 12 sọ pé: “Ogun sì bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run: Máíkẹ́lì àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà jagun, dírágónì náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sì jagun ṣùgbọ́n kò borí, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí àyè kankan fún wọn mọ́ ní ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni a fi dírágónì ńlá náà sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà; a fi í sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, a sì fi àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Ní tìtorí èyí, ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn! Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.”

Lílé tí a lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jáde kúrò lọ́run lẹ́yìn ọdún 1914 mú kí gbogbo ẹ̀dá ẹ̀mí ọlọ̀tẹ̀ tán pátá lọ́run, ìdùnnú ńláǹlà sì dé bá àwọn áńgẹ́lì adúróṣinṣin tó jẹ́ ọmọ Jèhófà, tí wọ́n sì jẹ́ apá tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tí Ọlọ́run dá. (Jóòbù 1:6-12; 2:1-7; Ìṣípayá 12:10) Bí apá tó jẹ mọ́ ọ̀run lára ẹ̀bẹ̀ inú àdúrà àwòṣe Jésù ṣe ní ìmúṣẹ nìyẹn. Gbogbo àwọn tó kù ní ọ̀run lẹ́yìn ìgbà náà dúró ṣinṣin sí Jèhófà, wọ́n sì tẹrí ba pátápátá fún un nítorí wọ́n gbà pé òun ni ọba aláṣẹ.

Ó yẹ kí ohun kan ṣe kedere, ìyẹn ni pé, ká tiẹ̀ tó lé Èṣù àtàwọn áńgẹ́lì burúkú yìí jáde pàápàá, nígbà tí wọ́n ṣì lè wọ ọ̀run, ẹni ìtanù ni wọ́n jẹ́ nínú ìdílé Ọlọ́run, wọ́n sì wà lábẹ́ àwọn ìkálọ́wọ́kò kan. Bí àpẹẹrẹ, Júúdà ẹsẹ kẹfà fi hàn pé ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa pàápàá, a ti “fi [wọ́n] pa mọ́ de ìdájọ́ ọjọ́ ńlá náà pẹ̀lú àwọn ìdè ayérayé lábẹ́ òkùnkùn biribiri.” Bákan náà, 2 Pétérù 2:4 sọ pé: “Ọlọ́run kò . . . fawọ́ sẹ́yìn ní fífìyàjẹ àwọn áńgẹ́lì tí ó ṣẹ̀, ṣùgbọ́n, nípa sísọ wọ́n sínú Tátárọ́sì [ipò ẹ̀tẹ́ gbáà], ó jù wọ́n sínú àwọn kòtò òkùnkùn biribiri [nípa tẹ̀mí] láti fi wọ́n pa mọ́ de ìdájọ́.” b

Ipò ẹni ìtanù táwọn áńgẹ́lì burúkú yìí wà nígbà tí wọ́n ṣì wà lọ́run kò dà bí ti ayé yìí tí wọ́n ti ń lo ọlá àṣẹ bó ṣe wù wọ́n. Àní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tiẹ̀ pe Sátánì ní “olùṣàkóso ayé yìí,” ó sì pe àwọn ẹ̀mí èṣù ní “àwọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yìí.” (Jòhánù 12:31; Éfésù 6:11, 12; 1 Jòhánù 5:19) Àṣẹ tí Èṣù ní yìí ló jẹ́ kó lè sọ pé òun yóò fún Jésù ní “gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn” bó bá lè ṣe ìṣe ìjọsìn kan ṣoṣo fún òun. (Mátíù 4:8, 9) Ó ṣe kedere nígbà náà pé, ohun tí ‘dídé’ Ìjọba Ọlọ́run máa yọrí sí fún ayé ni pé, àyípadà rere pátápátá á dé bá ayé.

Lórí ilẹ̀ ayé níbí, ńṣe ni ‘dídé’ Ìjọba Ọlọ́run yóò mú ètò àwọn nǹkan tuntun pátápátá wá. Ìjọba yìí yóò fọ́ gbogbo ìṣàkóso tí ènìyàn dá sílẹ̀ túútúú, ìjọba yẹn nìkan ṣoṣo yóò wá máa ṣàkóso ayé. Lẹ́sẹ̀ kan náà, àwọn èèyàn, olùbẹ̀rù Ọlọ́run tó jẹ́ ọmọ abẹ́ rẹ̀ yóò wá jẹ́ “ilẹ̀ ayé tuntun.” (2 Pétérù 3:13; Dáníẹ́lì 2:44) Ìjọba yìí yóò tún bá gbogbo ọmọ aráyé tó jẹ́ onígbọràn mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò pátápátá, yóò sì sọ gbogbo ilẹ̀ ayé di Párádísè lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Nípa bẹ́ẹ̀, a kò ní gbóòórùn ohunkóhun tó jẹ mọ́ ìṣàkóso lábẹ́ Sátánì mọ́.—Róòmù 8:20, 21; Ìṣípayá 19:17-21.

Ní òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún, nígbà tí Ìjọba Mèsáyà bá ti parí gbogbo ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí ó ṣe, “Ọmọ fúnra rẹ̀ pẹ̀lú yóò fi ara rẹ̀ sábẹ́ Ẹni tí ó fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, kí Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.” (1 Kọ́ríńtì 15:28) Lẹ́yìn náà, ìdánwò ìkẹyìn yóò wáyé, lẹ́yìn èyí ni “ikú kejì” yóò wá pa Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ run ráúráú àti èyíkéyìí nínú àwọn ọlọ̀tẹ̀ ọmọ aráyé tí wọ́n bá tàn jẹ. (Ìṣípayá 20:7-15) Lẹ́yìn èyí, gbogbo ẹ̀dá onílàákàyè láyé àtọ̀run yóò wá máa fayọ̀ tẹrí ba títí láé fún Jèhófà pé òun ni ọba aláṣẹ onífẹ̀ẹ́. Ìgbà yẹn ni ọ̀rọ̀ àdúrà àwòṣe tí Jésù gbà yóò tó ní ìmúṣẹ délẹ̀délẹ̀.—1 Jòhánù 4:8.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bíbélì The Bible—An American Translation, túmọ̀ apá ibí yìí nínú àdúrà àwòṣe Jésù báyìí pé, “Kí ìjọba rẹ dé! Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé àti ní ọ̀run pẹ̀lú!”—Mátíù 6:10.

b Àpọ́sítélì Pétérù fi ipò ìtanù nípa tẹ̀mí yìí wé bí ìgbà téèyàn wà nínú “ẹ̀wọ̀n.” Àmọ́ ṣá, kì í ṣe “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀” tí a ó sọ àwọn ẹ̀mí èṣù sí fún ẹgbẹ̀rún ọdún ni Pétérù ń sọ o.—1 Pétérù 3:19, 20; Lúùkù 8:30, 31; Ìṣípayá 20:1-3.