Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Óò Máa Rìn Ní Orúkọ Jèhófà Títí Láé!

A Óò Máa Rìn Ní Orúkọ Jèhófà Títí Láé!

A Óò Máa Rìn Ní Orúkọ Jèhófà Títí Láé!

“Àwa . . . yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.”—MÍKÀ 4:5.

1. Àwọn ọ̀rọ̀ wo ló dún gbọnmọgbọnmọ nínú ìwé Míkà orí kẹta sí ìkarùn-ún?

 JÈHÓFÀ ní ọ̀rọ̀ láti bá àwọn èèyàn rẹ̀ sọ. Míkà sì ni wòlíì tí ó ń lò. Ọlọ́run fẹ́ dá àwọn oníwà àìtọ́ lẹ́jọ́. Ó fẹ́ fìyà jẹ Ísírẹ́lì nítorí ìpẹ̀yìndà rẹ̀. Àmọ́, inú wa dùn pé Jèhófà yóò bù kún àwọn tó bá ń rìn ní orúkọ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dún gbọnmọgbọnmọ ní orí kẹta sí ìkarùn-ún àsọtẹ́lẹ̀ Míkà.

2, 3. (a) Ànímọ́ wo ló yẹ káwọn olórí Ísírẹ́lì ní, àmọ́ kí ni wọ́n ń ṣe ní ti gidi? (b) Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé àkànlò èdè tó wà nínú ìwé Míkà 3:2, 3?

2 Wòlíì Ọlọ́run kéde pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí Jékọ́bù àti ẹ̀yin aláṣẹ ilé Ísírẹ́lì. Kì í ha ṣe iṣẹ́ yín ni láti mọ ìdájọ́ òdodo?” Bẹ́ẹ̀ ni, iṣẹ́ wọn kúkú ni! Iṣẹ́ tó yẹ kí wọ́n gbájú mọ́ nìyẹn. Àmọ́ iṣẹ́ wo wá ni wọ́n jókòó tì? Míkà sọ pé: “Ẹ̀yin olùkórìíra ohun rere àti olùfẹ́ ìwà búburú, tí ń bó awọ ara kúrò lára àwọn ènìyàn àti ẹ̀yà ara kúrò lára egungun wọn; ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ ẹ̀yà ara àwọn ènìyàn mi pẹ̀lú, tí ẹ sì ti bó awọ ara wọn kúrò lára wọn, tí ẹ sì fọ́ egungun wọn pàápàá sí wẹ́wẹ́, tí ẹ sì fọ́ wọn túútúú bí ohun tí ó wà nínú ìkòkò ẹlẹ́nu fífẹ̀ àti bí ẹran ní inú ìkòkò ìse-oúnjẹ.”—Míkà 3:1-3.

3 Áà, ńṣe làwọn aṣáájú ń fìyà jẹ àwọn tálákà àtàwọn tí kò ní olùgbèjà! Àwọn àkànlò èdè tí Míkà lò níhìn-ín yé àwọn tó ń fetí sí i yékéyéké. Nígbà tí wọ́n bá pa àgùntàn, wọ́n á da omi gbígbóná sí i lára, wọ́n á wá bó o láwọ kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí kun ún. Nígbà míì, wọ́n á fọ́ àwọn egungun rẹ̀ kí mùdùnmúdùn inú wọn lè jáde. Wọ́n á wá se ẹran àti egungun náà nínú irú ìkòkò ńlá tí Míkà mẹ́nu kàn. (Ìsíkíẹ́lì 24:3-5, 10) Àpèjúwe yìí mà kúkú bá ìyà táwọn aṣáájú burúkú náà fi ń jẹ àwọn èèyàn wọn nígbà ayé Míkà mu o!

Jèhófà Fẹ́ Ká Máa Ṣe Ìdájọ́ Òdodo

4. Báwo ni Jèhófà ṣe yàtọ̀ sáwọn aṣáájú Ísírẹ́lì?

4 Ìyàtọ̀ ńláǹlà ló wà láàárín Jèhófà, Olùṣọ́ Àgùntàn onífẹ̀ẹ́ náà àtàwọn aṣáájú Ísírẹ́lì. Nítorí pé wọn ò ṣe ìdájọ́ òdodo, wọ́n pa iṣẹ́ tá a gbé lé wọn lọ́wọ́ tì, ìyẹn iṣẹ́ dídáàbò bo agbo. Dípò ìyẹn, wọ́n ń fi ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan tú àwọn àgùntàn ìṣàpẹẹrẹ náà jẹ, wọ́n ń fi ìdájọ́ òdodo dù wọ́n, wọ́n sì ‘ń ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀,’ gẹ́gẹ́ bí Míkà 3:10 ti sọ. Ẹ̀kọ́ wo lèyí ń kọ́ wa?

5. Kí ni Jèhófà fẹ́ káwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ ṣe?

5 Ọlọ́run ń retí pé káwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ máa ṣe ìdájọ́ òdodo. Ohun táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà sì ń ṣe lóde òní nìyẹn. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, èyí bá ohun tó wà ní Aísáyà 32:1 mu, níbi tá a ti kà á pé: “Wò ó! Ọba kan yóò jẹ fún òdodo; àti ní ti àwọn ọmọ aládé, wọn yóò ṣàkóso bí ọmọ aládé fún ìdájọ́ òdodo.” Àmọ́ kí ló ń ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Míkà? Ńṣe ni àwọn “olùkórìíra ohun rere àti olùfẹ́ ìwà búburú” ń yí ìdájọ́ po.

Àdúrà Àwọn Wo Ni Ọlọ́run Ń Gbọ́?

6, 7. Kókó pàtàkì wo la tẹnu mọ́ nínú Míkà 3:4?

6 Ǹjẹ́ àwọn olubi tó wà nígbà ayé Míkà lè retí àtirí ojú rere Jèhófà? Rárá o! Míkà 3:4 sọ pé: “Wọn yóò ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kì yóò dá wọn lóhùn. Yóò sì fi ojú rẹ̀ pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn ní àkókò yẹn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe búburú nínú ìbánilò wọn.” Èyí gbé kókó pàtàkì kan jáde.

7 Jèhófà kò ní gbọ́ àdúrà wa bá a bá ń dẹ́ṣẹ̀ láìronú pìwà dà. Àgàgà bá a bá ń gbé ìgbésí ayé méjì, tá à ń yọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dá, tá a tún wá ń díbọ́n pé à ń fi ìṣòtítọ́ sin Ọlọ́run. Dáfídì kọ ọ́ lórin nínú Sáàmù 26:4, pé: “Èmi kò bá àwọn tí kì í sọ òtítọ́ jókòó; àwọn tí ń fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́ ni èmi kì í sì í bá wọlé.” Ẹ ò rí i pé èyí fi hàn kedere pé Jèhófà ò ní gbọ́ àdúrà àwọn tó ń tàpá sí Ọ̀rọ̀ rẹ̀!

Ẹ̀mí Ọlọ́run fún Wọn Lágbára

8. Ìkìlọ̀ wo la ṣe fún àwọn wòlíì èké nígbà ayé Míkà?

8 Áà, ìwàkíwà mà pọ̀ lọ́wọ́ àwọn aṣáájú Ísírẹ́lì o! Àwọn wòlíì èké mú kí àwọn èèyàn Ọlọ́run máa rìn gbéregbère nípa tẹ̀mí. Àwọn aṣáájú oníwọra wọ̀nyí ń kígbe “Àlàáfíà!” ṣùgbọ́n ogun ni wọ́n ń gbé dìde sí ẹnikẹ́ni tí kò bá fi oúnjẹ sí wọn lẹ́nu. Jèhófà sọ pé: “Nítorí náà, òru yóò wà fún yín, tí kò fi ní sí ìran; òkùnkùn yóò sì ṣú fún yín, kí ẹ má bàa woṣẹ́. Dájúdájú, oòrùn yóò wọ̀ lórí àwọn wòlíì, ọjọ́ yóò sì ṣókùnkùn lórí wọn. Ojú yóò sì ti àwọn olùríran, a ó sì já àwọn woṣẹ́woṣẹ́ kulẹ̀ dájúdájú. Wọn yóò sì bo túbọ̀mu.”—Míkà 3:5-7a.

9, 10. Kí ni ‘bíbo túbọ̀mu’ túmọ̀ sí, kí sì nìdí tí Míkà kò fi ní láti bo túbọ̀mu rẹ̀?

9 Kí nìdí tí wọ́n á fi “bo túbọ̀mu”? Ìtìjú ló sún àwọn èèyàn burúkú ìgbà ayé Míkà ṣe èyí. Ó sì yẹ kójú ti àwọn ẹni ibi wọ̀nyí lóòótọ́. Torí pé “kò sí ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” fún wọn. (Míkà 3:7b) Jèhófà kì í gbọ́ àdúrà ẹni burúkú.

10 Kò sídìí fún Míkà láti “bo túbọ̀mu.” Ìtìjú ò bá a. Jèhófà ń gbọ́ àdúrà rẹ̀. Wo Míkà 3:8, níbi tí wòlíì olóòótọ́ náà ti sọ pé: “Ní ọwọ́ kejì, ẹ̀wẹ̀, èmi alára sì ti kún fún agbára, nípa ẹ̀mí Jèhófà, àti ti ìdájọ́ òdodo àti agbára ńlá.” Ẹ wo bí inú Míkà ti dùn tó pé jálẹ̀ ọ̀pọ̀ ọdún tóun fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun, ìgbà gbogbo lòun ń “kún fún agbára, nípa ẹ̀mí Jèhófà”! Èyí ló fún un lókun tó fi “lè sọ ìdìtẹ̀ Jékọ́bù fún un, [tó] sì sọ ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì fún un.”

11. Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń fún àwọn èèyàn lágbára láti wàásù ọ̀rọ̀ rẹ̀?

11 Míkà nílò agbára tó kọjá ti ẹ̀dá kí ó bàa lè jẹ́ iṣẹ́ ìdájọ́ tí Ọlọ́run fi rán an. Ó nílò ẹ̀mí Jèhófà. Àwa náà ńkọ́? Àfi bí Jèhófà bá ń fún wa lókun nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ nìkan la fi lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa láṣeyọrí. Ó dájú pé a ò lè kẹ́sẹ járí rárá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù náà tá a bá ń mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀. Ìyẹn ò sì ní jẹ́ kí Ọlọ́run tẹ́tí sí wa bá a bá gbàdúrà sí i pé kó fún wa lókun láti fi ṣe iṣẹ́ yìí. Àní sẹ́, àfi bí “ẹ̀mí Jèhófà” bá wà lára wa nìkan ló fi lè ṣeé ṣe fún wa láti máa polongo ìhìn ìdájọ́ Baba wa ọ̀run. Nípasẹ̀ àdúrà tí Ọlọ́run ń gbọ́ àti nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́, àwa náà lè fìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bíi ti Míkà.

12. Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ìjímìjí láti ‘máa fi àìṣojo sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’?

12 Bóyá o rántí ìtàn tó wà nínú Ìṣe 4:23-31. Fojú inú wò ó pé o jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọ̀rúndún kìíní. Àwọn onínú burúkú tó ń ṣe inúnibíni ń wá ọ̀nà láti pa àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi lẹ́nu mọ́. Ṣùgbọ́n àwọn adúróṣinṣin yìí gbàdúrà sí Olúwa Ọba Aláṣẹ wọn, pé: “Jèhófà, fiyè sí àwọn ìhalẹ̀mọ́ni wọn, kí o sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹrú rẹ láti máa bá a nìṣó ní fífi àìṣojo rárá sọ ọ̀rọ̀ rẹ.” Kí ni àbájáde rẹ̀? Nígbà tí wọ́n ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ tán, ibi tí wọ́n kóra jọpọ̀ sí mì, gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan sì kún fún ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì fi àìṣojo sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nítorí náà, ǹjẹ́ ká máa tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ tá à ń rí gbà nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ bá a ṣe ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ.

13. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù àti Samáríà, kí sì nìdí?

13 Tún ronú nípa ọjọ́ Míkà. Míkà 3:9-12 sọ pé àwọn alákòóso tó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó dájọ́, àwọn àlùfáà ń díye lé ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni, àwọn wòlíì èké sì ń gbowó láti woṣẹ́ fáwọn èèyàn. Abájọ tí Ọlọ́run fi pinnu pé Jerúsálẹ́mù, olú ìlú Júdà, yóò di “òkìtì àwókù lásán-làsàn”! A mí sí Míkà láti kìlọ̀ pé Ọlọ́run yóò sọ Samáríà di “òkìtì àwókù” nítorí pé ìjọsìn èké àti ìwà ìbàjẹ́ gbèèràn ní Ísírẹ́lì pẹ̀lú. (Míkà 1:6) Kódà, ìparun tá a sọ tẹ́lẹ̀, pé àwọn ọmọ ogun Ásíríà máa mú wá sórí Samáríà, ṣojú wòlíì náà lọ́dún 740 ṣááju Sànmánì Tiwa. (2 Ọba 17:5, 6; 25:1-21) Ó hàn gbangba pé agbára Jèhófà nìkan ló fi lè jẹ́ àwọn iṣẹ́ alágbára tá a rán sí Jerúsálẹ́mù àti Samáríà yìí.

14. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Míkà 3:12 ṣe nímùúṣẹ, báwo ló sì ṣe yẹ kó nípa lórí wa?

14 Ó dájú pé Júdà kò lè bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ mímúná látọ̀dọ̀ Jèhófà. Ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Míkà 3:12, Síónì yóò di èyí tí a ‘tu bí ilẹ̀ pápá lásán-làsàn.’ Tá a bá wẹ̀yìn wò ní ọ̀rúndún kọkànlélógún tá a wà yìí, a mọ̀ pé nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ará Bábílónì pa Júdà àti Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. Èyí wáyé ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí Míkà sàsọtẹ́lẹ̀, àmọ́, ó dá a lójú pé ìparun yẹn ń bọ̀. Bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ ló ṣe yẹ kó dá àwa náà lójú pé òpin ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí yóò dé ní “ọjọ́ Jèhófà” tá a sọ tẹ́lẹ̀.—2 Pétérù 3:11, 12.

Jèhófà Mú Àwọn Ọ̀ràn Tọ́

15. Lọ́rọ̀ ara rẹ, báwo lo ṣe máa ṣàlàyé àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Míkà 4:1-4?

15 Bá a bá tún padà lọ wo ìwé Míkà, a óò rí i pé ìrètí tí ń múni lọ́kàn yọ̀ ló kéde tẹ̀ lé e. Ẹ ò rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ tí ń múni lọ́kàn le ló wà nínú Míkà 4:1-4! Ara ọ̀rọ̀ tí Míkà sọ níbẹ̀ ni pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́ pé òkè ńlá ilé Jèhófà yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá, dájúdájú, a óò gbé e lékè àwọn òkè kéékèèké; àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ síbẹ̀. . . . Dájúdájú, òun yóò ṣe ìdájọ́ láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, yóò sì mú àwọn ọ̀ràn tọ́ ní ti àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ńlá tí ó jìnnà réré. Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Wọn kì yóò gbé idà sókè, orílẹ̀-èdè lòdì sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́. Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì; nítorí ẹnu Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti sọ ọ́.”

16, 17. Báwo ni Míkà 4:1-4 ṣe ń nímùúṣẹ lónìí?

16 Àwọn wo ni “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn” àti “orílẹ̀-èdè alágbára” tá a mẹ́nu kàn níhìn-ín? Wọn kì í ṣe àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ìjọba ayé yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, àsọtẹ́lẹ̀ náà ń tọ́ka sáwọn èèyàn lẹ́nìkọ̀ọ̀kan látinú gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ní òkè ńlá Jèhófà tó wà fún ìjọsìn tòótọ́.

17 Níbàámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ Míkà, ìjọsìn mímọ́ Jèhófà ni gbogbo èèyàn yóò máa ṣe kárí ayé láìpẹ́. Lóde òní, àwọn èèyàn “tí wọ́n ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” ni à ń kọ́ ní ọ̀nà Jèhófà. (Ìṣe 13:48) Jèhófà ń ṣe ìdájọ́, ó sì ń mú àwọn ọ̀ràn tọ́ nípa tẹ̀mí fún àwọn onígbàgbọ́ tí wọ́n fara mọ́ Ìjọba náà. Wọn yóò la “ìpọ́njú ńlá” já gẹ́gẹ́ bí ara “ogunlọ́gọ̀ ńlá” náà. (Ìṣípayá 7:9, 14) Níwọ̀n bí wọ́n ti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, lónìí pàápàá wọ́n ń gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ẹlẹgbẹ́ wọn àti pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ìdùnnú ńlá gbáà ló jẹ́ láti wà lára wọn!

A Ti Pinnu Láti Máa Rìn Ní Orúkọ Jèhófà

18. Kí ni ‘jíjókòó sábẹ́ àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ ẹni’ ń ṣàpẹẹrẹ?

18 Lọ́jọ́ tiwa, tí ìbẹ̀rù bo ayé mọ́lẹ̀ bámúbámú yìí, inú wa dùn gidigidi pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà Jèhófà. À ń fi ìháragàgà retí àkókò tó ti sún mọ́lé yìí, tí gbogbo èèyàn tó fẹ́ràn Ọlọ́run yóò ṣíwọ́ kíkọ́ṣẹ́ ogun jíjà, tí wọ́n á tún jókòó sábẹ́ àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn. Inú ọgbà àjàrà la sábà máa ń gbin igi ọ̀pọ̀tọ́ sí. (Lúùkù 13:6) Jíjókòó sábẹ́ àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ ẹni dúró fún wíwà ní àlàáfíà, ipò aásìkí àti ààbò. Àní nísinsìnyí pàápàá, àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà ń fún wa ní ìbàlẹ̀ ọkàn àti ààbò tẹ̀mí. Nígbà tí irú ipò bẹ́ẹ̀ bá dé lábẹ́ Ìjọba náà, àyà wa ò ní já mọ́ rárá, ọkàn wa á sì balẹ̀ pẹ̀sẹ̀.

19. Kí ló túmọ̀ sí láti máa rìn ní orúkọ Jèhófà?

19 Tá a bá fẹ́ rí ojú rere àti ìbùkún Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ máa rìn ní orúkọ Jèhófà. A sọ èyí ní kedere nínú Míkà 4:5, níbi tí wòlíì náà ti polongo pé: “Gbogbo àwọn ènìyàn, ní tiwọn, yóò máa rìn, olúkúlùkù ní orúkọ ọlọ́run tirẹ̀; ṣùgbọ́n àwa, ní tiwa, yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.” Rírìn ní orúkọ Jèhófà kì í kàn ṣe ọ̀ràn wíwulẹ̀ sọ pé òun ni Ọlọ́run wa. Ó ju kí á kàn máa kópa nínú àwọn ìpàdé Kristẹni àti ká máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run nìkan, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìgbòkègbodò wọ̀nyẹn náà ṣe pàtàkì. Bí a bá ń rìn ní orúkọ Jèhófà, àá ya ara wa sí mímọ́ fún un àá sì máa gbìyànjú láti máa fi ìṣòtítọ́ sìn ín pẹ̀lú ìfẹ́ àtọkànwá. (Mátíù 22:37) Gẹ́gẹ́ bí olùjọsìn rẹ̀, a ti pinnu láti máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa títí ayé.

20. Kí la sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nínú Míkà 4:6-13?

20 Wàyí o, ẹ jẹ́ ká gbé àsọtẹ́lẹ̀ Míkà 4:6-13 yẹ̀ wò. “Ọmọbìnrin Síónì” yóò lọ sígbèkùn “títí dé Bábílónì.” Ohun náà gan-an tó ṣẹlẹ̀ sáwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù ní ọ̀rúndún keje ṣááju Sànmánì Tiwa nìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀, àsọtẹ́lẹ̀ Míkà fi hàn pé àṣẹ́kù yóò padà bọ̀ sí Júdà, nígbà tí Síónì bá ti ìgbèkùn dé, Jèhófà yóò rí sí i pé òun pa àwọn ọ̀tá Síónì run pátápátá.

21, 22. Báwo ni Míkà 5:2 ṣe nímùúṣẹ?

21 Míkà orí karùn-ún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí ohun tó wà nínú Míkà 5:2-4. Míkà sọ tẹ́lẹ̀ pé Alákòóso kan tí Ọlọ́run yàn, ìyẹn ẹnì kan “tí orírun rẹ̀ jẹ́ láti àwọn àkókò ìjímìjí,” yóò jáde wá láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Yóò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn “nínú okun Jèhófà.” Kò tán síbẹ̀ o, òkìkí Alákòóso yìí yóò kàn, kì í ṣe ní Ísírẹ́lì nìkan, àmọ́ “títí dé òpin ilẹ̀ ayé” pàápàá. Aráyé ní gbogbo gbòò lè máà mọ ẹni tí alákòóso yìí jẹ́ o, àmọ́ kì í ṣe àdììtú fún àwa.

22 Ta ni ẹni pàtàkì jù lọ nínú gbogbo àwọn tá a bí nílùú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù? Ta sì ni “yóò tóbi títí dé òpin ilẹ̀ ayé”? Kò sí ẹlòmíràn tó lè jẹ́ bí kò ṣe Jésù Kristi, Mèsáyà náà! Nígbà tí Hẹ́rọ́dù Ńlá béèrè ibi tí a ó ti bí Mèsáyà lọ́wọ́ àwọn olórí àlùfáà àtàwọn akọ̀wé, wọ́n dá a lóhùn pé: “Ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Jùdíà” ni. Wọ́n tiẹ̀ fa ọ̀rọ̀ inú Míkà 5:2 yọ. (Mátíù 2:3-6) Díẹ̀ lára àwọn gbáàtúù ènìyàn mọ̀ nípa èyí pẹ̀lú, nítorí Jòhánù 7:42 fa ọ̀rọ̀ wọn yọ pé: “Ìwé Mímọ́ kò ha ti sọ pé Kristi ń bọ̀ wá láti inú ọmọ Dáfídì, àti láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù abúlé tí Dáfídì ti wà tẹ́lẹ̀ rí?”

Ìtura Tòótọ́ fún Àwọn Èèyàn

23. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ nísinsìnyí tó ń mú Míkà 5:7 ṣẹ?

23 Míkà 5:5-15 sọ pé ará Ásíríà yóò gbógun wá, yóò ṣẹ́gun, ṣùgbọ́n fúngbà díẹ̀ ni. Ó tún sọ tẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run yóò gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè aláìgbọràn. Míkà 5:7 ṣèlérí pé a óò mú àwọn àṣẹ́kù Júù tí wọ́n ronú pìwà dà padà bọ̀ sí ilẹ̀ wọn, àmọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tún ní í ṣe pẹ̀lú àkókò wa lónìí. Míkà sọ pé: “Àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú Jékọ́bù yóò sì dà bí ìrì láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ní àárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀wààrà òjò lórí ewéko.” Àpèjúwe tó fakíki yìí la fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àṣẹ́kù Jékọ́bù, ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí, yóò jẹ́ ìbùkún látọ̀dọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Inú “àwọn àgùntàn mìíràn” Jésù tí wọ́n nírètí àtiwà lórí ilẹ̀ ayé dùn láti máa ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àṣẹ́kù “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ti òde òní, tí wọ́n sì ń tu àwọn ẹlòmíràn lára nípa tẹ̀mí. (Jòhánù 10:16; Gálátíà 6:16; Sefanáyà 3:9) Látàrí èyí, kókó kan wà tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò. Gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba náà, ó yẹ kí gbogbo wa mọyì àǹfààní tá a ní láti mú ìtura tòótọ́ wá fáwọn èèyàn.

24. Àwọn kókó wo lo jèrè látinú ìwé Míkà orí kẹta sí ìkarùn-ún?

24 Tóò, ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú orí kẹta sí ìkarùn-ún àsọtẹ́lẹ̀ Míkà? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn kókó wọ̀nyí: (1) Ọlọ́run retí pé kí àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ máa ṣe ìdájọ́ òdodo. (2) Jèhófà kò ní gbọ́ àdúrà wa tá a bá mọ̀ọ́mọ̀ ń dẹ́ṣẹ̀. (3) Àfi bí Ọlọ́run bá ń fún wa lókun nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ nìkan la fi lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa láṣeparí. (4) Bá a bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ máa rìn ní orúkọ Jèhófà. (5) Gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba náà, ó yẹ ká mọyì àǹfààní tá a ní láti mú ìtura tòótọ́ wá fáwọn èèyàn. Ó ṣeé ṣe kó o ti jèrè àwọn kókó mìíràn. Ṣùgbọ́n kí ni nǹkan míì tá a tún lè rí kọ́ nínú ìwé Bíbélì tó kún fún àsọtẹ́lẹ̀ yìí? Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí àwọn ẹ̀kọ́ gidi kọ́ nínú orí méjì tó gbẹ̀yìn àsọtẹ́lẹ̀ Míkà tó ń fún ìgbàgbọ́ lókun yìí.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ni Ọlọ́run fẹ́ káwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ ṣe?

• Kí nìdí tí àdúrà àti ẹ̀mí mímọ́ fi ṣe pàtàkì nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà?

• Báwo làwọn èèyàn ṣe ń ‘rìn ní orúkọ Jèhófà’?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ǹjẹ́ o lè ṣàlàyé àkàwé Míkà tó dá lórí ìkòkò ìse-oúnjẹ?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

À ń fi ìgboyà ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa bí ti Míkà