Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Ara Ẹ Ṣe Lè Mọlé Nínú Ìjọ Tó O Wà Báyìí

Bí Ara Ẹ Ṣe Lè Mọlé Nínú Ìjọ Tó O Wà Báyìí

ALLEN * ṣẹ̀ṣẹ̀ kó dé ìjọ tuntun kan ni, ìjọ náà sì jìn tó ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [900] máìlì sí ìjọ tó wà tẹ́lẹ̀. Ó sọ pé: “Àyà mi ń já nígbà tí mò ń ronú àtikó wá síbí. Mi ò mọ̀ bóyá àwọn èèyàn á bá mi ṣọ̀rẹ́.”

Tó bá jẹ́ pé ìwọ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ kó lọ síjọ míì, ó ṣeé ṣe kí àyà ẹ máa já. Kí láá jẹ́ kára ẹ tètè mọlé? Kí lo lè ṣe tí ara ẹ ò bá tètè mọlé? Tó bá sì jẹ́ pé ìwọ ò kó lọ síbì kankan, báwo lo ṣe lè ran àwọn tó kó wá sí ìjọ yín lọ́wọ́?

BÓ O ṢE LÈ NÍ ÀWỌN Ọ̀RẸ́ TUNTUN

Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí ná: Tí wọ́n bá wú irúgbìn tàbí igi kan lọ gbìn síbòmíì, ó máa ń pẹ́ díẹ̀ kó tó lè fìdí múlẹ̀. Láwọn ilẹ̀ kan, tí wọ́n bá wú igi, wọ́n á gé díẹ̀ kúrò lára gbòǹgbò rẹ̀ kó lè rọrùn láti gbé. Tí wọ́n bá ti tún un gbìn, igi náà á bẹ̀rẹ̀ sí í ta gbòǹgbò tuntun. Lọ́nà kan náà, ara rẹ lè má tètè mọlé tó o bá kó lọ síjọ míì. Ní ìjọ tó o wà tẹ́lẹ̀, o láwọn ọ̀rẹ́ tẹ́ ẹ mọwọ́ ara yín dáadáa, o sì ń gbádùn bẹ́ ẹ ṣe jọ ń ṣe àwọn nǹkan tẹ̀mí pa pọ̀. Ká kúkú sọ pé o ti ta gbòǹgbò, o sì ti fìdí múlẹ̀ dáadáa nínú ìjọ yẹn. Àmọ́ ní báyìí tó o ti dé ìjọ tuntun, ó yẹ kó o ṣe àwọn ohun táá jẹ́ kí ara rẹ mọlé, bí ìgbà tó ò ń ta gbòǹgbò tuntun. Kí láá jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹ? Á ṣeé ṣe tó o bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Jẹ́ ká gbé mélòó kan yẹ̀ wò.

Bíbélì fi ẹni tó ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé wé “igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi, tí ń pèsè èso tirẹ̀ ní àsìkò rẹ̀, èyí tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé kì í sì í rọ, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.”​Sm. 1:​1-3.

Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí igi máa rí omi fà déédéé. Lọ́nà kan náà, ó ṣe pàtàkì kí Kristẹni tó bá fẹ́ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Torí náà, máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, kó o sì máa lọ sípàdé déédéé. Máa dá kẹ́kọ̀ọ́, kẹ́ ẹ sì máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé déédéé. Àwọn nǹkan tó jẹ́ kó o máa ṣe dáadáa nínú ìjọsìn Jèhófà nínú ìjọ tó o wà tẹ́lẹ̀ náà ni kó o máa ṣe níbi tó o wà báyìí.

‘Ẹni tí ó ń bomi rin àwọn ẹlòmíràn ní fàlàlà, a ó bomi rin òun náà ní fàlàlà.’​Òwe 11:25.

Tó o bá ń lọ sóde ẹ̀rí déédéé, ara ẹ á tètè mọlé níjọ tuntun tó o wà, wàá sì láwọn ọ̀rẹ́. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Kevin sọ pé: “Ohun tó ran èmi àtìyàwó mi lọ́wọ́ nígbà tá a dé ìjọ tuntun ni pé a ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Èyí sì jẹ́ ká tètè mọ àwọn ará, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àtàwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn.” Arákùnrin Roger tó kó lọ sí ibi tó jìn tó ẹgbẹ̀rún kan [1,000] máìlì síbi tó ń gbé tẹ́lẹ̀ sọ pé: “Ọ̀nà tó dáa jù tó o lè tètè gbà dojúlùmọ̀ àwọn ará ni pé kó o máa lọ sóde ẹ̀rí déédéé. O lè jẹ́ káwọn alàgbà mọ̀ pé o ṣe tán láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá wà nínú ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, o lè bá wọn tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe, o lè ṣe iṣẹ́ pàjáwìrì tí ẹni tó ni iṣẹ́ náà kò bá wá tàbí kó o tiẹ̀ yọ̀ǹda láti gbé àwọn kan wá sípàdé. Táwọn ará bá rí i pé ìwọ tó o jẹ́ ẹni tuntun ní ẹ̀mí ìyọ̀nda ara ẹni, wọ́n á fà ẹ́ mọ́ra.”

“Ẹ gbòòrò síwájú.”​2 Kọ́r. 6:13.

Máa bá àwọn ará sọ̀rọ̀ dáadáa. Nígbà tí Arábìnrin Melissa, ọkọ rẹ̀ àti ọmọbìnrin wọn kó lọ sí ìjọ tuntun, wọn ò jẹ́ kó pẹ́ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ará ṣọ̀rẹ́. Ó sọ pé: “A máa ń bá àwọn ará sọ̀rọ̀ dáadáa kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn tí ìpàdé bá parí. Èyí máa ń jẹ́ ká lo àkókò pẹ̀lú wọn dípò ká kàn kí wọn lásán.” Yàtọ̀ síyẹn, ó jẹ́ kí wọ́n tètè mọ orúkọ àwọn ará. Bákan náà, wọ́n máa ń pe àwọn ará wá sílé wọn kí wọ́n lè jọ jẹun, èyí sì ti jẹ́ kí wọ́n láwọn ọ̀rẹ́ tó gbámúṣé. Ó tún sọ pé: “A gba nọ́ńbà tẹlifóónù ara wa, ká lè jọ máa kàn síra, ká sì tún jọ máa ṣe àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn àtàwọn nǹkan míì.”

Tí ojú bá ń tì ẹ́ láti bá àwọn tó ò mọ̀ rí sọ̀rọ̀, àwọn nǹkan kan wà tó o lè ṣe. Bí àpẹẹrẹ, máa rẹ́rìn-ín músẹ́ sáwọn èèyàn kódà tí kò bá tiẹ̀ mọ́ ẹ lára. Tó o bá ń rẹ́rìn-ín, àwọn èèyàn á sún mọ́ ẹ. Ó ṣe tán, téèyàn bá jẹ́ ọlọ́yàyà, inú ẹ̀ á máa dùn. (Òwe 15:30) Arábìnrin Rachel tó kó lọ síbi tó jìn gan-an sílé sọ pé: “Ojú máa ń tì mí gan-an. Kódà, mo ní láti kọ́ bí mo ṣe lè máa yá mọ́ àwọn ará níjọ tuntun tí mo wà. Mo máa ń wá ẹni tó dá jókòó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, màá sì lọ bá a sọ̀rọ̀, torí pé ojú lè máa ti òun náà bíi tèmi.” Torí náà, fi ṣe àfojúsùn rẹ pé wàá bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ kí ìpàdé kọ̀ọ̀kan tó bẹ̀rẹ̀ tàbí lẹ́yìn ìpàdé.

Lọ́wọ́ kejì, ó lè yá ẹ lára láti sún mọ́ àwọn ará tó wà ní ìjọ tuntun tó o wà, àmọ́ ní báyìí tó o ti dojúlùmọ̀ àwọn kan, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ yá ẹ lára mọ́ láti mọ àwọn tó kù. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè gba pé kó o sapá kó o lè máa fi kún àwọn tó o ti mọ̀.

Tí wọ́n bá wú igi kan lọ gbìn síbòmíì, ó máa ń pẹ́ díẹ̀ kó tó lè fìdí múlẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n bá tún un gbìn, igi náà á bẹ̀rẹ̀ sí í ta gbòǹgbò tuntun

JẸ́ KÍ ARA Ẹ MỌLÉ DÁADÁA

Igi yàtọ̀ sí igi, ó máa ń pẹ́ káwọn igi kan tó ta gbòǹgbò tí wọ́n bá wú wọn lọ síbòmíì. Lọ́nà kan náà, ara àwọn kan máa ń tètè mọlé ju àwọn míì lọ tí wọ́n bá kó lọ síjọ tuntun. Tó bá ti ṣe díẹ̀ tó o ti kó lọ síjọ míì àmọ́ tí ara ẹ ò tíì mọlé, a rọ̀ ẹ́ pé kó o fi àwọn ìlànà Bíbélì yìí sílò:

“Ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.”​Gál. 6:9.

Jẹ́ kí ara ẹ mọlé dáadáa kódà bó bá tiẹ̀ máa gbà ẹ́ lákòókò ju bó o ṣe rò lọ. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn míṣọ́nnárì tó lọ sílé ẹ̀kọ́ Gílíádì máa ń lo ọdún mélòó kan ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ sìn kí wọ́n tó lọ ṣèbẹ̀wò sílé. Èyí máa ń jẹ́ kí wọ́n mọwọ́ àwọn ará ibẹ̀ dáadáa, kí wọ́n sì kọ́ àṣà wọn.

Alejandro tó ti ṣí kúrò láti ibì kan sí ibòmíì lọ́pọ̀ ìgbà sọ pé kì í ṣe ọjọ́ kan ni ibi tuntun máa ń mọ́ èèyàn lára. Ó sọ pé: “Nígbà tá a kó kúrò kẹ́yìn, ìyàwó mi sọ pé, ‘Ìjọ tá a wà tẹ́lẹ̀ ni gbogbo ọ̀rẹ́ mi wà.’ ” Alejandro wá rán an létí pé ohun kan náà ló sọ lọ́dún méjì sẹ́yìn nígbà tí wọ́n ń kó kúrò níbì kan. Àmọ́, láàárín ọdún méjì yẹn, ìyàwó rẹ̀ kó àwọn ará mọ́ra, kódà ó láwọn ọ̀rẹ́ tuntun.

“Má sọ pé: ‘Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé àwọn ọjọ́ àtijọ́ sàn ju ìwọ̀nyí lọ?’ nítorí pé ọgbọ́n kọ́ ni ìwọ fi béèrè nípa èyí.”​Oníw. 7:10.

Má ṣe fi ìjọ tó o wà tẹ́lẹ̀ wé ìjọ tuntun tó o wà báyìí. Bí àpẹẹrẹ, ara àwọn tó wà níjọ tó o wà báyìí lè yá mọ́ èèyàn ju ibi tó o wà tẹ́lẹ̀ tàbí kí wọ́n má fi bẹ́ẹ̀ kóni mọ́ra. Ṣe ni kó o máa wo ibi tí wọ́n dáa sí torí ohun tíwọ náà fẹ́ kí wọ́n ṣe fún ẹ nìyẹn. Kódà, èrò tí àwọn kan tó ṣí lọ síbòmíì ní nípa àwọn ará ti jẹ́ kí wọ́n máa bi ara wọn pé, ‘Ṣé lóòótọ́ ni mo nífẹ̀ẹ́ “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará”?’​—1 Pét. 2:17.

“Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín.”​Lúùkù 11:9.

Máa gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́. Alàgbà kan tó ń jẹ́ David sọ pé: “Apá ẹ ò lè ká a. Ká sòótọ́, ó lójú nǹkan tá a lè ṣe yanjú láìsí ìrànlọ́wọ́ Jèhófà. Torí náà, gbàdúrà nípa ẹ̀.” Rachel tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lókè náà gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, ó sọ pé: “Tó bá ń ṣe èmi àti ọkọ mi bíi pé a ò fi bẹ́ẹ̀ sún mọ́ àwọn ará, ṣe la máa ń dìídì gbàdúrà sí Jèhófà nípa ẹ̀, a máa sọ fún un pé ‘Jọ̀ọ́, jẹ́ ká mọ̀ bóyá à ń ṣe nǹkan kan tó ń jẹ́ káwọn ará máa yẹra fún wa.’ Lẹ́yìn ìyẹn, a wá gbìyànjú láti túbọ̀ máa lo àkókò pẹ̀lú wọn.”

Ẹ̀yin òbí, tí ara àwọn ọmọ yín ò bá tètè mọlé, ṣe ni kẹ́ ẹ gbàdúrà nípa ọ̀rọ̀ yìí pẹ̀lú wọn. Ẹ bá wọn wá àwọn ọ̀rẹ́ tuntun, ọ̀nà kan tẹ́ ẹ sì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kẹ́ ẹ máa pe àwọn ará wá sílé yín tàbí kẹ́ ẹ máa ṣe àwọn nǹkan míì táá jẹ́ káwọn ọmọ yín dojúlùmọ̀ àwọn ará.

ṢE OHUN TÁÁ JẸ́ KÍ ARA ÀWỌN TÓ WÁ SÍ ÌJỌ YÍN MỌLÉ

Kí làwọn nǹkan tó o lè ṣe táá jẹ́ kára àwọn tó wá sí ìjọ yín tètè mọlé? Gbàrà tí wọ́n bá ti dé ni kó o ti mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́. Ronú àwọn nǹkan tí ìwọ náà máa fẹ́ káwọn ará ṣe fún ẹ tó bá jẹ́ ìwọ lo ṣẹ̀ṣẹ̀ dé, kó o sì ṣe àwọn nǹkan náà. (Mát. 7:12) O lè ní kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ yín nínú Ìjọsìn Ìdílé yín tàbí kẹ́ ẹ jọ wo Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW. Ẹ sì lè jọ lọ sóde ẹ̀rí. O lè pè wọ́n wá sílé yín kẹ́ ẹ jọ jẹun, ó dájú pé wọn ò ní gbàgbé ohun tó o ṣe. Ǹjẹ́ o lè ronú àwọn ọ̀nà míì tó o lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́?

Arákùnrin Carlos sọ pé: “Nígbà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ìjọ wa, arábìnrin kan jẹ́ ká mọ àwọn ibi tá a ti máa rí nǹkan rà ní ẹ̀dínwó. Ohun tó ṣe yìí ràn wá lọ́wọ́ gan-an.” O lè kọ́ àwọn tó kúrò ní ilẹ̀ tí ojú ọjọ́ ti yàtọ̀ sí tiyín nípa bí wọ́n ṣe lè múra nígbà ooru tàbí nígbà òtútù. O tún lè jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n á ṣe máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Sọ ohun tó o mọ̀ nípa àdúgbò yín fún wọn àtohun táwọn ẹlẹ́sìn ibẹ̀ gbà gbọ́.

ÀǸFÀÀNÍ TÓ WÀ NÍNÚ JÍJẸ́ KÁRA ẸNI MỌLÉ

Ó ti lé lọ́dún kan tí Allen tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ ti wà níjọ tó wà báyìí. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo kọ́kọ́ dé, kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún mi láti mọ àwọn ará nínú ìjọ. Àmọ́ ní báyìí, a ti di ọmọ ìyá, mo sì ń láyọ̀.” Allen wá rí i pé òun ò pàdánù ọ̀rẹ́ kankan, dípò bẹ́ẹ̀ ṣe lòun tún ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun, kò sì sóhun tó máa já okùn ọ̀rẹ́ wọn títí láé.

^ ìpínrọ̀ 2 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.