Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tí Àwọn Kan Sọ

Ohun Tí Àwọn Kan Sọ

Ohun Tí Àwọn Kan Sọ

Faransé Agbẹnusọ fún ẹgbẹ́ àwọn ọlọ́pàá ti orílẹ̀-èdè Faransé sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń bọ̀wọ̀ fún òfin orílẹ̀-èdè. . . . Wọn kì í yọ ìlú lẹ́nu. Wọ́n ń ṣiṣẹ́, wọ́n máa ń sanwó orí, wọ́n máa ń kópa nínú ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè wa, wọ́n sì máa ń ṣe ìtọrẹ àánú. Ó máa ń wúni lórí gan-an láti rí bí àwọn èèyàn tí ẹ̀yà àti orílẹ̀-èdè wọn yàtọ̀ síra ṣe ń pàdé pọ̀, tí àlàáfíà sì wà láàárín wọn. . . . Bí gbogbo èèyàn bá jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwa ọlọ́pàá ò ní máa ríṣẹ́ ṣe rárá.”

Ukraine Ìwé The History of Religion in Ukraine, tí ọ̀jọ̀gbọ́n Petro Yarotskyi ṣàtúnṣe rẹ̀, sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ẹ̀kọ́ ọmọlúwàbí tó jíire. Wọ́n máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn pé kí wọ́n yẹra fún àwọn ìwà táwọn èèyàn ayé òde òní kò kà sí nǹkan kan, àmọ́ tó jẹ́ pé ó léwu fún àwọn ọmọdé àtàwọn míì. Torí náà, wọ́n máa ń kìlọ̀ fún àwọn ọmọ wọn nípa ewu tó wà nínú lílo oògùn olóró, sìgá mímu àti mímu ọtí àmujù. Wọ́n mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn jẹ́ olóòótọ́ kó sì máa ṣiṣẹ́ kára. . . . Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ìwà ọmọlúwàbí, bí wọ́n ṣe lè máa bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ àtàwọn míì, bí wọ́n ṣe lè máa lo àwọn ohun ìní àwọn ẹlòmíì lọ́nà tó dáa àti bí wọ́n á ṣe máa tẹ̀ lé òfin ìlú.”

Ítálì Nígbà tí ìwé ìròyìn kan tó ń jẹ́ L’Unità lórílẹ̀-èdè Ítálì ń ròyìn àpéjọ àgbègbè kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní Róòmù, ó sọ pé: “Àwọn èèyàn tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ [30,000] jókòó pẹ̀sẹ̀ sí pápá ìṣeré ti Olympic. . . Wọn kò dọ̀tí ilẹ̀, kò sí ariwo, kò sí ẹni tó ń lọgun. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní pápá ìṣeré ti Olympic lánàá nìyẹn . . . Kò sí ìfaraṣàpèjúwe tí kò tọ́, kò sẹ́ni tó ń mu sìgá, ẹ ò sì lè rí agolo kankan nílẹ̀. Ńṣe lẹ kàn máa rí àwọn èèyàn tó ń ṣí Bíbélì, àwọn tó ń ṣàkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń gbọ́ àtàwọn ọmọdé tó jókòó jẹ́ẹ́.”

Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì “Àlùfáà àgbà ti ìlú Cheltenham nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé àwùjọ àwọn èèyàn ònífọkànsin tí yóò máa lọ káàkiri bíi tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni [Ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà] nílò.”—Ìwé ìròyìn The Gazette, ti ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà tó wà ní ìlú Gloucester nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Netherlands Àwọn tó ń gbé àdúgbò ibi tí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà nílùú Leeuwarden fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní lẹ́tà kan tó kà pé: “Bẹ́ ẹ ṣe jẹ́ kí òpópónà Noorder dùn-ún wò máa ń wú wa lórí gan-an ni. Àwọn ọmọ ìjọ yín máa ń múra dáadáa nígbà gbogbo, wọ́n sì ní ìwà ọmọlúwàbí. Àwọn ọmọdé níwà rere, àwọn àgbàlagbà kì í gbé mọ́tò síbi tí kò yẹ, wọn kì í da ìdọ̀tí sílẹ̀, ìgbà gbogbo sì ni àyíká Gbọ̀ngàn Ìjọba yín máa ń mọ́ tónítóní. Inú wa dùn pé ẹ jẹ́ aládùúgbò wa kò sì wù wá kẹ́ ẹ fi àdúgbò wa sílẹ̀ rárá.”

Mẹ́síkò Elio Masferrer tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n àti olùwádìí ní ilé ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Nípa Ẹ̀dá Ènìyàn àti Ìtàn, ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò sọ pé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣèrànwọ́ fún àwọn “tó kojú ìṣòro lílekoko nínú ìdílé, irú bí ìfipábánilòpọ̀, ìfìyàjẹni, ọtí àmujù àti lílo oògùn olóró.” Ó tún sọ pé, “ẹ̀kọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń buyì kún àwọn tí wọ́n bá ti ro ara wọn pin,” ó sì máa ń jẹ́ kí “ìṣòro wọn mọ níwọ̀n, torí pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.”—Ìwé ìròyìn Excélsior.

Brazil Ìwé ìròyìn kan lórílẹ̀-èdè Brazil sọ pé, “àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an ni. Ìbi tí wọ́n ti ń pàdé máa ń mọ́ tónítóní ní gbogbo ìgbà. Gbogbo nǹkan wọn ló wà létòlétò. . . Bí wọ́n bá sì parí ìpàdé wọn, ńṣe ni ibi tí wọ́n ti ṣe ìpàdé náà á mọ́ tónítóní ju bí wọ́n ṣe bá a lọ. Bí wọ́n bá ń gbọ́ àsọyé, ńṣe ni wọ́n máa ń tẹ́tí sílẹ̀ láìsí ariwo kankan. Wọn kì í ti ara wọn tàbí kí wọ́n rọ́ lu ara wọn. Wọ́n mà ní ìwà ọmọlúwàbí o. . . . Ẹ̀sìn wọn wà létòlétò. Wọ́n mọ ohun tó túmọ̀ sí láti máa jọ́sìn Ọlọ́run.”Ìwé ìròyìn Comércio da Franca.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ dáadáa pé tó bá dọ̀rọ̀ àwọn ìlànà tó yẹ káwa èèyàn máa tẹ̀ lé, Ẹlẹ́dàá mọ̀ ju ẹnikẹ́ni lọ. (Isaiah 48:17, 18) Torí náà, Ọlọ́run ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi ìyìn fún nígbà tí àwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ wọn lọ́nà tó dáa nítorí ìwà rere wọn. Jésù sọ pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín, kí wọ́n sì lè fi ògo fún Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.”—Mátíù 5:16.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

“Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ìwà ọmọlúwàbí . . . àti bí wọ́n á ṣe máa tẹ̀ lé òfin ìlú.”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]

“. . . Àwọn èèyàn tó wá látinú oríṣiríṣi ẹ̀yà àti orílẹ̀-èdè ń pà dé pọ̀, àlàáfíà sì wà láàárín wọn . . . ”