Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè

Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè

Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè

Kí nìdí tí àwọn kan fi máa ń sọ̀rọ̀ òdì nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Ọ̀pọ̀ ni kò mọ òtítọ́ nípa ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́. Àwọn míì ò nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń ṣe. Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé ìfẹ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní sí àwọn èèyàn ló mú kí wọ́n máa wàásù, torí wọ́n mọ̀ pé “olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.”—Róòmù 10:13.

Ṣé ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì, ẹgbẹ́ arinkinkin mọ́ ìlànà tàbí ẹ̀ya ìsìn kan làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Kristẹni làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ wọn kì í ṣe ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í ṣe ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, torí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ kan tí kò bá Bíbélì mu tí àwọn ẹlẹ́sìn wọ̀nyí fi ń kọ́ni. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì kò kọ́ wa pé Ọlọ́run tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́ ìfẹ́ máa ń fi iná dá àwọn èèyàn lóró nínú hẹ́ẹ̀lì títí láé. Bẹ́ẹ̀ ni kò kọ́ni pé nǹkan kan wà nínú ara èèyàn tí kì í kú, kò sì sọ pé káwọn Kristẹni máa lọ́wọ́ sí ìṣèlú.—Ísíkíẹ́lì 18:4; Jòhánù 15:19; 17:14; Róòmù 6:23. a

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The World Book Encyclopedia sọ pé: “Ẹgbẹ́ arinkinkin mọ́ ìlànà jẹ́ ẹ̀gbẹ́ ńlá kan tó wá látinú ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àwọn ẹgbẹ́ arinkinkin mọ́ ìlànà kan “ti mú ọ̀rọ̀ àjọṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti ìṣèlú wọnú ẹ̀sìn, nípa lílo àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ní olówuuru.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe bẹ́ẹ̀ rárá. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í lọ́wọ́ sí ìṣèlú, wọn kì í sì í fi dandan mú kí àwọn èèyàn gba èrò wọn, bóyá nípasẹ̀ ìṣèlú tàbí lọ́nà míì. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n sábà máa ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan láti mú kí wọ́n ronú, wọ́n sì máa ń fúnni ní ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro, gẹ́gẹ́ bí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ti ṣe.—Ìṣe 19:8.

Ẹ̀ya ìsìn ni àwùjọ tí kò fara mọ́ ohun tí ẹ̀sìn wọn gbà gbọ́, ó sì lè jẹ́ ẹgbẹ́ kan tó yapa kúrò nínú ẹ̀sìn kan tó sì lọ dá ẹ̀sìn míì sílẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò yapa látinú ẹ̀sìn kankan. Torí náà, wọn kì í ṣe ẹ̀ya ìsìn.

Kí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe láwọn ìpàdé wọn?

Ẹnikẹ́ni ló lè lọ sáwọn ìpàdé wọn. Bíbélì ni wọ́n máa ń kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀, àwọn tó bá wà níbẹ̀ sì ní àǹfààní láti lóhùn sí i. Ọ̀kan lára àwọn ìpàdé tí wọ́n máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ni Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, èyí tó máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n ṣe ń kọ́ni, bí wọ́n ṣe ń kàwé àti bí wọ́n ṣe ń ṣe ìwádìí. Òmíràn ni àsọyé Bíbélì tí wọ́n máa ń fi ọgbọ̀n ìṣẹ́jú sọ, èyí tó máa ń dá lé kókó ọ̀rọ̀ kan tí àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè nífẹ̀ẹ́ sí. Lẹ́yìn àsọyé yìí, wọ́n máa ń fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Orin àti àdúrà ni wọ́n máa fi ń bẹ̀rẹ̀, tí wọ́n sì máa fi ń parí àwọn ìpàdé yìí. Wọn kì í tọrọ owó, wọn kì í sì í gbégbá ọrẹ.—2 Kọ́ríńtì 8:12.

Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń rí owó tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn?

Ọrẹ àtinúwá ni wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìsìn wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gba owó fún ìrìbọmi, ìgbéyàwó, ìsìnkú tàbí àwọn ààtò ẹ̀sìn mìíràn. Bákan náà, wọn kì í gba ìdá mẹ́wàá. Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ fowó ṣe ìtọrẹ lè fi sínú àpótí tí wọ́n gbé sí apá ibì kan nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn fúnra wọn ló máa ń ṣe àwọn ìwé tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nítorí pé èyí máa ń dín ìnáwó kù. Bákan náà, àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ló sábà máa ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn tó mọ níwọ̀n àti àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn.

Ǹjẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tọ́jú ara wọn nígbà tí wọ́n bá ń ṣàìsàn?

Bẹ́ẹ̀ ni. Kódà, ìtọ́jú tó dáa jù lọ ni wọ́n máa ń fẹ́ gbà fún ara wọn àti àwọn èèyàn wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló tiẹ̀ jẹ́ nọ́ọ̀sì, oníṣègùn pàjáwìrì, dókítà àti oníṣẹ́ abẹ. Àmọ́ ṣá o, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gba ẹ̀jẹ̀ sára. Bíbélì sọ pé, ‘Ẹ máa ta kété sí ẹ̀jẹ̀.’ (Ìṣe 15:28, 29) Ó dùn mọ́ni pé ní báyìí, àwọn dókítà tí iye wọn ń pọ̀ sí i ló ti gbà pé ìtọ́jú tí kò la ìfàjẹ̀sínilára lọ ló dáa jù lọ, torí pé ó ń jẹ́ kéèyàn yẹra fún ọ̀pọ̀ ewu tó wà nínú gbígba ẹ̀jẹ̀ sára.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a O lè rí ohun tí Bíbélì sọ nípa èyí àtàwọn kókó pàtàkì míì nínú ìwé náà, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

IBI TÍ ÒMÌNIRA TI GBILẸ̀

Ìwé ìròyìn Excélsior sọ pé ohun kan mú kí ìlú Bejucal de Ocampo tó wà ní apá gúúsù lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ṣàrà ọ̀tọ̀, ohun náà ni pé, “Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó ń gbé ìlú náà.” Ó tún sọ pé, “Àwọn èèyàn lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n, bákan náà wọn kì í dìtẹ̀ sí ìjọba. . . . Dípò tí wọn ì bá fi máa mu ọtí àmuyíràá àti sìgá, ńṣe ni wọ́n máa ń kọrin tí wọ́n sì máa ń ka Bíbélì. Bákan náà, wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ.”

Ìwé náà sọ pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé oríṣiríṣi ẹ̀sìn ló wà ní ìlú náà, “ìjà ẹ̀sìn tàbí awuyewuye kò sí níbẹ̀.” Ó tún sọ pé: “Wọn kì í ṣe ẹ̀tanú, ti pé oríṣiríṣi ẹ̀sìn ni wọ́n ń ṣe kò ní kí wọ́n má ṣe kí ara wọn . . . Ìdílé kọ̀ọ̀kan ń ṣe ẹ̀sìn tó wù ú fàlàlà, síbẹ̀ àlàáfíà wà láàárín àwọn aráàlú. Kò yani lẹ́nu pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ipa tó dáa gan-an lórí àwọn aráàlú Bejucal.” Olùkọ́ iléèwé girama kan ní ìlú náà tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún sọ pé, ‘ìmúra àwọn ọmọ wọn máa ń jẹ́ ti ọmọlúwàbí, wọ́n máa ń ṣe dáadáa nínú ẹ̀kọ́ wọn, wọ́n sì máa ń hùwà dáadáa nínú kíláàsì.’