Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Máa Yọ́ Jáde Nílé Lóru?

Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Máa Yọ́ Jáde Nílé Lóru?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Máa Yọ́ Jáde Nílé Lóru?

“Ńṣe la máa ń yọ́ jáde nílé lóru táa máa lọ síbi tí wọ́n ti ń ta kọfí láti lọ pàdé àwọn ọ̀rẹ́ wa. Òkè ńlá kan wà táa máa ń lọ gùn láti lọ wo bí òru ṣe máa ń rí. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi wọ̀nyí ló ń mu sìgá, àmọ́ èmi ò bá wọn fẹnu kàn án ṣá o. Ńṣe la máa jókòó tí àá wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan lóríṣiríṣi, a máa ń gbọ́ àwọn orin ìlù tó ń dún kíkankíkan. A ó sì wá lọ sílé ní aago márùn-ún ìdájí kí àwọn òbí mi tó jí.”—Tara. a

“Bí dádì mi bá ti lọ síbi iṣẹ́ tí mọ́mì mi náà sì ti sùn, màá bá ẹnu ọ̀nà ìta yọ́ jáde. Màá rọra fi ilẹ̀kùn náà sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ torí tí mo bá ní kí n tì í mọ́mì mi á gbọ́ nítorí pé ilẹ̀kùn onírin ni. Èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi á bẹ̀rẹ̀ sí fẹsẹ̀ palẹ̀ kiri ní gbogbo òru. Bó bá wá di òwúrọ̀ tí ọ̀yẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí là, màá tún yọ́ wọlé padà. Mọ́mì máa ń mọ̀ nígbà mìíràn pé mo ti yọ́ jáde tí yóò sì tilẹ̀kùn mọ́ mi síta.”—Joseph.

YÍYỌ́ JÁDE NÍLÉ—ó dún bí eré tó ń dùn mọ́ni tàbí ohun kan tó ń mórí yá. Ó jẹ́ ohun kan tó ń fún ọ láyè láti mọ bí ìgbésí ayé ṣe rí láyè tìrẹ fún wákàtí bíi mélòó kan, àǹfààní kan láti ṣe ohun tó bá wù ọ́ kóo sì wà pẹ̀lú ẹni tó bá wù ọ́ láìsí pé ẹnì kan á bi ọ́. Yàtọ̀ sí èyí, ó ṣeé ṣe kóo ti gbọ́ tí àwọn ojúgbà ẹ ń ṣe fọ́rífọ́rí nípa àwọn ohun tí wọ́n máa ń ṣe àti àríyá tí wọ́n máa ń gbádùn nígbà tí wọ́n bá yọ́ jáde nílé lóru. Èyí lè mú kó wá máa wu ìwọ náà láti dara pọ̀ mọ́ wọn.

Nínú ìwádìí tí àwọn kan ṣe láàárín àádọ́fà àwọn ọmọ tí wọ́n wà ní àwọn kíláàsì ìbẹ̀rẹ̀ àti àwọn kíláàsì ìparí ní ilé ẹ̀kọ́ girama ní Àríwá Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, márùnléláàádọ́ta lára wọn ló jẹ́wọ́ pé àwọn ti yọ́ jáde nílé lóru rí ní ẹ̀ẹ̀kan ó kéré tán. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn ṣe bẹ́ẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ nígbà tí wọ́n wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìnlá. Ìṣòro táa ń wí yìí wá gogò débi tí àwọn ògbóǹkangí kan fi dáa lábàá pé kí àwọn òbí lọ fi àwọn ohun èèlò abánáṣiṣẹ́ tó máa ń dún sí ilé wọn níwọ̀n bí èyí kò ti ní jẹ́ kí àwọn ọmọ náà lè jáde kúrò nílé láìsọ fún àwọn òbí wọn. Kí ló tiẹ̀ ń mú kí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn èwe máa fọwọ́ pa idà ìbínú àwọn òbí wọn lójú nípa yíyọ́ jáde nílé lóru pàápàá?

Ìdí Táwọn Kan Fi Ń Yọ́ Jáde Nílé Lóru

Ohun tó ń mú káwọn èwe kan máa yọ́ jáde nílé lóru kò ju pé ilé ti sú wọn tí wọ́n sì fẹ́ lọ bá àwọn ọ̀rẹ́ wọn kí wọ́n sì jọ gbádùn ara wọn. Ìwé Adolescents and Youth ṣàlàyé pé àwọn èwe lè yọ́ jáde nílé lóru “nítorí àwọn ìfòfindè díẹ̀ kan, fún àpẹẹrẹ, àwọn òbí lè sọ fún àwọn ọmọ wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ jáde nílé bí ojú bá ti pofírí, tàbí kí wọ́n fi òfin fìdí-mọ́lé dè wọ́n kí wọ́n má bàa lọ sí àwọn òde ayẹyẹ. Ńṣe ni àwọn èwe yìí máa wá ọ̀nà èyíkéyìí tí wọ́n á fi lọ tí wọ́n á sì fọgbọ́n padà wọlé láìjẹ́ kí àwọn òbí wọn mọ̀.” Ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ṣàlàyé ìdí tóun fi máa ń yọ́ jáde nílé lóru. Ó sọ pé: “Ńṣe làwọn òbí mi mú kó dà bí ẹni pé ìkókó ṣì ni mí tí mi ò sì lómìnira láti gbé ìgbésí ayé mi bó bá ṣe wù mí. Mo ti gbọ́dọ̀ wọlé nígbà táwọn ẹgbẹ́ mi tó kù ṣì máa wà níta. Àwọn òbí mi kì í sì í fàyè gbà mí láti lọ síbi táwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń lọ . . . Àmọ́ mo máa ń lọ ní tèmi o, tí màá sì parọ́ fún wọn.” Nígbà tí Joseph, táa mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, ló ti bẹ̀rẹ̀ sí yọ́ jáde nílé, ó yọ́ lọ sí agbo àwọn olórin ọlọ́rọ̀ wótowòto táwọn òbí rẹ̀ ti sọ pé kò gbọ́dọ̀ lọ.

Òótọ́ ni pé, èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn èwe ni wọn ò ní èròkérò lọ́kàn fún yíyọ́ jáde nílé lóru. Tara, ọ̀kan lára àwọn èwe táa fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀, sọ pé: “Ohun àkọ́kọ́ tó máa ń wá sí wa lọ́kàn kì í ṣe ‘Jẹ́ ká lọ dẹ́ṣẹ̀ o jàre.’ Mo kàn fẹ́ wà pẹ̀lú àǹtí mi ni, tí òun náà sì fẹ́ jáde nílé láti lọ jẹ̀gbádùn pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” Joseph pẹ̀lú sọ pé: “A kàn máa ń fẹsẹ̀ palẹ̀ kiri ni. Mo máa ń fẹ́ láti wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi ká sì jùmọ̀ sọ̀rọ̀.” Àmọ́ bó ti jẹ́ pé rírìn kiri pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ èèyàn lè máà mú kí èèyàn hu ìwà ọ̀daràn, àìmọye àwọn èwe ni wọ́n ti kó sínú ìjàngbọ̀n tó le.

Àwọn Ewu Tó Wà Níbẹ̀

Obìnrin kan tó jẹ́ ògbóǹkangí nípa ìlera ọpọlọ, Dókítà Lynn E. Ponton ṣàlàyé pé: “Kò sóhun tó burú nínú kí àwọn ọ̀dọ́langba máa fẹ̀mí ara wọn wewu.” Dókítà Ponton ṣàlàyé síwájú sí i pé kò sóhun tó burú níbẹ̀ pé ó tiẹ̀ ń mú ara àwọn èwe le pàápàá láti fẹ́ láti wà lómìnira, láti gbìyànjú ṣe àwọn nǹkan tí wọn ò tíì ṣe rí, àti láti wà ní àwọn ipò tó ń gbádùn mọ́ni irú èyí tí wọn ò tíì wà tẹ́lẹ̀ rí. Ara dídàgbà sókè náà ni. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn èwe ni wọ́n máa ń fi ẹ̀mí ara wọn wewu kọjá bó ṣe yẹ, pàápàá nígbà tí wọn ò bá sí nítòsí àwọn òbí wọn. Ìwé ìròyìn Teen sọ pé: “Báa bá pa ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe àti ìkáàárẹ̀ pọ̀ pẹ̀lú agbára tá ò lò lọ́nà tó dára, ká tún wá fi àwọn èròjà mìíràn bóyá bí ọtí bíà kún un . . . ó lè mú kí àwọn ọ̀dọ́langba fẹ̀mí ara wọn wewu lọ́nà tí kò bọ́ sí i, kí wọ́n sì wá fi ẹ̀mí wọn dí i.” Ìwádìí kan to díẹ̀ lára àwọn ìgbòkègbodò eléwu wọ̀nyí lẹ́sẹẹsẹ, tó ní nínú sísáré àsápajúdé, ìwà bàsèjẹ́, wíwakọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti mutí yó, àti olè jíjà.

Bóo bá ti dán ṣíṣe àìgbọ́ràn wò lẹ́ẹ̀kan, ó rọrùn dáadáa láti tẹ̀ síwájú láti ṣe àwọn ohun tó túbọ̀ burú gidigidi. Ńṣe ló dà bí ohun tí Jésù sọ nínú ìwé Lúùkù 16:10 pé: “Ẹni tí ó bá sì jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú.” Kò yani lẹ́nu nígbà náà, pé yíyọ́ jáde kúrò nílé pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ lè mú kéèyàn dẹ́ṣẹ̀ tó lékenkà. Tara hùwà àgbèrè. Joseph, ní tirẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ta oògùn olóró, nígbà táwọn ọlọ́pàá sì gbá a mú, ńṣe ni wọ́n sọ pé kó lọ fẹ̀wọ̀n jura. Èwe Kristẹni kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ John bẹ̀rẹ̀ sí lo oògùn olóró, bẹ́ẹ̀ ló sì tún ń jí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ káàkiri. Ó bani nínú jẹ́ pé, púpọ̀ irú àwọn èwe bẹ́ẹ̀ ni wọ́n rí àbájáde irú àwọn ìwàkuwà bẹ́ẹ̀ ní ti ara ìyára—gbígboyún, kíkó àìsàn tí ìbálòpọ̀ takọtabo ń ta látaré, tàbí dídi ẹni tó sọ ọtí líle tàbí oògùn olóró di bárakú.—Gálátíà 6:7, 8.

Ọṣẹ́ Tí Àìgbọràn Lè Ṣe

Ìrora ọkàn tí yóò fà fún ọ lè pọ̀ gidigidi ju ìpalára tó lè ṣe fún ọ lọ. Ẹ̀rí-ọkàn tí ìdààmú ti bá máa ń kó másùnmáwo bá èèyàn gan-an. (Sáàmù 38:3, 4) Joseph sọ pé: “Wọ́n máa ń pa á lówe pé ìgbẹ̀yìn ní í yé olókùú àdá. Nígbà míì tí mo bá ronú padà sẹ́yìn, ó máa ń yà mí lẹ́nu pé èmi náà ni mo hu irú ìwà òpònú bẹ́ẹ̀.”

Bákan náà, a ò lè ṣàìmẹ́nu ba ọṣẹ́ tí àìgbọràn lè ṣe fún irú ojú táwọn èèyàn á máa fi wò ẹ́. Ìwé Oníwàásù 10:1 sọ pé: “Àwọn òkú eṣinṣin ní ń mú kí òróró olùṣe òróró ìkunra ṣíyàn-án, kí ó máa hó kùṣọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ìwà òmùgọ̀ díẹ̀ ń ṣe sí ẹni tí ó ṣe iyebíye nítorí ọgbọ́n àti ògo.” Láyé ọjọ́un, ohun kékeré kan bí òkú eṣinṣin lè ba òróró olówó iyebíye tàbí nǹkan olóòórùn dídùn jẹ́ ráúráú. Bákan náà, gbogbo wàhálà tóo ti ṣe táwọn èèyàn fi ń sọ̀rọ̀ ẹ dáadáa lè di èyí tí kìkì “ìwà òmùgọ̀ díẹ̀” yóò bà jẹ́ ráúráú. Bóo bá sì wá jẹ́ Kristẹni, kò sí àní-àní pé irú ìwàkiwà bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ kí o ní àwọn àǹfààní nínú ìjọ. Ó ṣe tán, ẹnu wo ni wàá fi máa fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí pé kí wọ́n tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nígbà táwọn èèyàn mọ̀ pé ìwọ alára kì í ṣe bẹ́ẹ̀?—Róòmù 2:1-3.

Ní paríparì rẹ̀, ronú nípa bó ṣe máa ká àwọn òbí rẹ lára tó nígbà tí wọ́n bá mọ̀ pé o ti yọ́ jáde nílé. Òbí kan ṣàlàyé bó ṣe pá òun láyà tó nígbà tóun ṣàkíyèsí pé ọmọ òun ọlọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kò sí nínú ilé. Ó ṣàpèjúwe ìmọ̀lára rẹ̀ àti ti ọkọ rẹ̀ pé ‘àwọn ò mọ ohun táwọn ò bá ṣe, nítorí pé ìdààmú ọkàn náà pàpọ̀ jù,’ ìdí sì ni pé wọn ò mọ ibi tí ọmọ wọn gbà lọ. Ṣé o fẹ́ mú kí àwọn òbí ẹ ní irú ìrora àti ẹ̀dùn ọkàn bẹ́ẹ̀?—Òwe 10:1.

Níní Òmìnira Tó Gbé Pẹ́ẹ́lí Sí I

A mọ̀ pé ó máa ń tánni ní sùúrù bó bá dà bíi pé àwọn òbí rẹ ti le koko jù. Àmọ́, ṣé yíyọ́ jáde nílé lóru ló máa wá yanjú ọ̀rọ̀ náà? Kò sọ́gbọ́n tóo fẹ́ ta sí i, àṣírí ẹ á tú lọ́jọ́ kan. Kódà, ká tiẹ̀ sọ pé o ń lo agbárí fún àwọn òbí ẹ pàápàá, Jèhófà Ọlọ́run ń wo gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ẹ kedere, títí kan èyí tí o ń ṣe nínú òkùnkùn lọ́gànjọ́ òru. (Jóòbù 34:21) Ọjọ́ kan á jọ́kan tí àṣírí ẹ á tú, tí èyí sì lè máà jẹ́ kí àwọn òbí ẹ tún gbà ẹ́ gbọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Kí ló máa gbẹ̀yìn ẹ̀? Nǹkan gan-an tóo fẹ́, ìyẹn òmìnira, á wá di èyí tó kéré jọjọ!

Rántí o: Kí o tó lè gbádùn òmìnira, o gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí àwọn òbí rẹ lè gbẹ̀rí rẹ̀ jẹ́. Ọ̀nà tó sì dára jù lọ láti ṣe èyí kò ju pé kí o máa gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu lọ. (Éfésù 6:1-3) Bó bá sì wá dà bí ẹni pé àwọn ọ̀nà kan wà tí àwọn òbí ẹ kì í fi í gba tìẹ rò, fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pè wọ́n jókòó kóo sì sọ ọ́ fún wọn. Wọ́n máa ronú nípa ohun tóo bá bá wọn sọ. Bóo bá sì tún gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò lọ́nà mìíràn, o lè rí i pé wọ́n kúkú jàre pẹ̀lú àwọn ìkálọ́wọ́kò tí wọ́n fún ọ. Kódà, bí o kò tiẹ̀ gbà pàápàá, má ṣe gbàgbé láé pé wọ́n fẹ́ràn rẹ tí wọ́n sì ní ire rẹ tó dára jù lọ lọ́kàn. Máa bá a lọ ní jíjẹ́ kí wọ́n túbọ̀ lè gbọ́kàn lé ọ, bí àsìkò bá sì wá tó, wàá rí i pé o máa ní òmìnira tóo fẹ́. b

‘Má Ṣe Bá Wọn Rìn O’

Ní àwọn ìgbà àtijọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń dà bíi pé kí àwọn èwe tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run dara pọ̀ mọ́ àwọn ojúgbà wọn nínú híhu ìwà ẹhànnà. Èyí gan-an ló mú kí Sólómọ́nì gba àwọn èwe níyànjú pé: “Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá gbìyànjú láti sún ọ dẹ́ṣẹ̀, má gbà. . . . Má ṣe bá wọn rìn pọ̀ ní ọ̀nà.” (Òwe 1:10, 15) Fi ìmọ̀ràn yẹn sílò nígbà táwọn tí wọ́n pera wọn lọ́rẹ̀ẹ́ rẹ yẹn bá fẹ́ kó sí ọ lórí pé kí ìwọ náà yọ́ jáde nílé lóru. Sólómọ́nì tún ṣe kìlọ̀kìlọ̀ síwájú sí i pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.”—Òwe 22:3.

Bóo bá ti ń yọ́ jáde nílé lóru, jáwọ́ ńbẹ̀! Nítorí ara rẹ lò ń ṣe o, kì í ṣe ẹnì kan. Jẹ́ kí àwọn òbí ẹ mọ ohun tóo ti ń ṣe, kóo sì múra tán láti fara da ìjìyà tàbí ìkálọ́wọ́kò èyíkéyìí tí wọ́n bá fún ọ. Bó bá pọndandan, yan àwọn ọ̀rẹ́ tuntun—àwọn ọ̀rẹ́ tó máa ní ipa dáadáa lórí ẹ. (Òwe 13:20) Wá àwọn ọ̀nà mìíràn tó gbámúṣé tóo fi lè gbádùn ara rẹ láìfi ẹ̀mí ara rẹ wewu.

Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ níbẹ̀ ni pé kóo ṣàtúnṣe àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó tó wà nínú ipò tẹ̀mí rẹ nípa kíka Bíbélì àti wíwá sí àwọn ìpàdé Kristẹni. Onísáàmù náà béèrè pé: “Báwo ni ọ̀dọ́kùnrin ṣe lè mú ipa ọ̀nà rẹ̀ mọ́?” Ó sì wá fèsì pé: “Nípa ṣíṣọ́ra ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ [Ọlọ́run].” (Sáàmù 119:9) Bóo ṣe ń fẹ̀sọ̀ tún èrò inú rẹ ṣe láti ṣe ohun tí ó tọ́, wàá wá rí i pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé yíyọ́ jáde nílé lóru lè dà bí ohun kan tó ń gbádùn mọ́ni tó sì tún ń mórí yá, kò tó nǹkan téèyàn ń torí ẹ̀ fẹ̀mí wewu.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí orúkọ wọ̀nyí padà.

b Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa béèyàn ṣe lè túbọ̀ lómìnira, wo orí 3 nínú ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 17]

“Àwọn òbí mi kì í fàyè gbà mí láti lọ sí ibi táwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń lọ . . . Àmọ́ mo máa ń lọ ní tèmi o, tí màá sì parọ́ fún wọn.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Yíyọ́ jáde nílé lóru sábà máa ń yọrí sí àwọn ìṣòro tó le kú