Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àkànṣe Ìwàásù Tá A Máa Ṣe ní Oṣù November Láti Kéde Ìjọba Ọlọ́run

Àkànṣe Ìwàásù Tá A Máa Ṣe ní Oṣù November Láti Kéde Ìjọba Ọlọ́run

Jésù wàásù “ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.” (Lk 4:43) Ó tún kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí Ìjọba yẹn dé. (Mt 6:​9, 10) Lóṣù November, a máa ṣe ìkéde àkànṣe láti sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. (Mt 24:14) Ṣètò àkókò ẹ kíwọ náà lè kópa nínú iṣẹ́ yìí. Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù yẹn lè pinnu bóyá ọgbọ̀n (30) tàbí àádọ́ta (50) wákàtí ni wọ́n máa ròyìn.

O lè ka ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Ronú nípa ẹ̀sìn tí ẹnì kọ̀ọ̀kan ń ṣe kó o tó yan ẹsẹ Bíbélì tó o máa kà. Tẹ́ni náà bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ, fún un ní Ilé Ìṣọ́ No. 2 2020. Rí i pé o tètè pa dà sọ́dọ̀ ẹni náà, kó o sì fi ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀. Àsìkò díẹ̀ ló kù tí Ìjọba Ọlọ́run á fọ́ gbogbo àwọn tó ń ta kò ó. (Da 2:44; 1Kọ 15:​24, 25) Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu àkànṣe ìwàásù yìí ká lè fi hàn pé ọ̀dọ̀ Jèhófà la wà, a sì ń ṣojú fún Ìjọba rẹ̀!

Ìjọba Ọlọ́run máa sọ ayé di Párádísè!