ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Ẹ Sá fún Ìbọ̀rìṣà

Yorùbá
Ẹ Sá fún Ìbọ̀rìṣà
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202020363/univ/art/202020363_univ_sqr_xl.jpg
mwb20 October ojú ìwé 2

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 31-32

Ẹ Sá fún Ìbọ̀rìṣà

Ẹ Sá fún Ìbọ̀rìṣà

32:1, 4-6, 9, 10

Torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti pẹ́ ní Íjíbítì, wọn ò rí ìbọ̀rìṣà bí ohun tó burú mọ́. Lónìí, oríṣiríṣi ọ̀nà lèèyàn lè gbà máa bọ̀rìṣà láìmọ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò ní dìídì lọ máa bọ òòṣà, a lè di abọ̀rìṣà tá a bá gbà kí ìfẹ́ ọkàn wa máa darí wa, ìyẹn ò sì ní jẹ́ ká sin Jèhófà tọkàntọkàn mọ́.

Àwọn nǹkan wo ni mò ń ṣe tó lè mú kó nira fún mi láti máa sin Jèhófà tọkàntọkàn, kí ni mo lè ṣe láti borí wọn?