Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ

Tí Èrò Yín Ò Bá Jọra

Tí Èrò Yín Ò Bá Jọra

 Ohun tó máa ń wu kálukú yàtọ̀, bá a ṣe máa ń ṣe nǹkan yàtọ̀, ìwà wa ò sì bára mu. Àwọn nǹkan yìí máa ń dá ìṣòro sílẹ̀ láàárín àwọn tọkọtaya. Àmọ́ àwọn nǹkan kan wà tó tún le jùyẹn lọ, bí àwọn èyí tá a tò sísàlẹ̀ yìí:

 •   Bí àkókò tẹ́ ẹ máa lò pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí yín ṣe máa pọ̀ tó

 •   Bí ẹ ṣe máa ṣọ́wó ná

 •   Bóyá ẹ máa bímọ àbí ẹ ò ní bímọ

 Kí lo lè ṣe tí èrò ìwọ àti ẹnì kejì rẹ ò bá jọra?

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀

 Ti pé ẹ bára yín mu ò túmọ̀ sí pé ẹ̀ẹ́ máa ronú bákan náà tàbí pé ẹ̀ẹ́ máa ṣe nǹkan lọ́nà kan náà. Èrò àwọn tọkọtaya tó mọwọ́ ara wọn jù lọ pàápàá máa ń yàtọ̀ síra nígbà míì, kódà lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì.

 “Nínú ilé tí wọ́n ti tọ́ mi dàgbà, ṣe ni gbogbo wa máa ń tẹ̀ lé ara wa kiri ṣó-ṣò-ṣó bí ọmọ adìyẹ. A máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn òbí wa àgbà àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa míì lópin ọ̀sẹ̀. Àmọ́ nínú ilé tí wọ́n ti tọ́ ọkọ mi dàgbà, wọn ò kì í fi bẹ́ẹ̀ fara mọ́ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn. Torí náà èrò wa yàtọ̀ síra tó bá dọ̀rọ̀ bí àkókò tá a máa lò lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wa ṣe máa pọ̀ tó àti èyí tó yẹ ká fi máa báwọn mọ̀lẹ́bí wa tó wà lọ́nà jíjìn sọ̀rọ̀.”​—Tamara.

 “Èrò èmi àti ìyàwó mi yàtọ̀ síra lórí ohun tó yẹ ká máa náwó lé lórí, torí bí wọ́n ṣe tọ́ wa dàgbà. Láàárín oṣù mélòó kan lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó, a bára wa jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yẹn. Kódà, kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì la jọ sọ ọ́ kó tó di pé a dé orí ìpinnu kan.”​—Tyler.

Èèyàn méjì lè ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ kan náà, àmọ́ kí èrò wọn yàtò síra. Bọ́rọ̀ ṣe máa ń rí nìyẹn tí èrò tọkọtaya ò bá jọra lórí ọ̀rọ̀ kan

 Ti pé ẹ gbà fún ara yín kò ní kí ìṣòro yanjú. Bí àpẹẹrẹ, kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí àna ọkọ tàbí ti ìyàwó bá ń ṣàìsàn, tó sì nílò ìtọ́jú? Àbí tí ọkọ bá sọ pé òun fẹ́ ọmọ, tí ìyàwó ò sì fẹ́? a

 “Èmi àti ìyàwó mi sọ̀rọ̀ gan-an nípa ọ̀rọ̀ ọmọ bíbí. Ó wù ú, ohun tó sì máa ń rò nìyẹn ṣáá, ìyẹn sì túbọ̀ ń mú kí èrò wa yàtọ̀ síra gan-an. Èmi ò mọ ẹni tó fẹ́ gbà fún ẹnì kejì nínú wa.”​—Alex.

 Ti pé èrò yín ò jọra ò ní kí ìgbéyàwó yín dojú rú. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ pé, tí ìwọ àti ẹnì kejì rẹ kò bá ti lè fẹnu kò lórí ọ̀rọ̀ kan tó ṣe pàtàkì, ohun tó bá gbà ni kó o fún un kí ohun tó o fẹ́ lè tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́, kódà bó jẹ́ kí ẹ̀yin méjèèjì tú ká. Àmọ́ tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ohun tó o fẹ́ lo kà sí pàtàkì ju ẹ̀jẹ́ tó o jẹ́ fún Ọlọ́run pé bíná ń jó, bíjì ń jà, kò sóhun tó máa yà yín.

 Ohun tó o lè ṣe

 Pinnu pé wàá fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó rẹ. Tó o bá pinnu pé, bíná ń jó, bíjì ń jà, kò sí ohun tó máa yà yín, ẹ̀yin méjèèjì á lè jọ wá ojútùú sí ìṣòro tó bá yọjú.

 Ìlànà Bíbélì: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí èèyàn kankan má ṣe yà á.”​—Mátíù 19:6.

 Rò ó dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, tí ọkọ bá sọ pé òun fẹ́ ọmọ, tí ìyàwó ò sì fẹ́, àwọn nǹkan kan wà tó yẹ kí wọ́n jíròrò, bíi:

 •   Bẹ́ ẹ ṣe mọwọ́ ara yín tó.

   Ṣé ẹ mọwọ́ ara yín débi pé wàhálà ọmọ títọ́ ò ní paná ìfẹ́ àárín yín?

 •   Ojúṣe àwọn òbí.

   Ọmọ títọ́ kọjá kí èèyàn kàn máa pèsè oúnjẹ, aṣọ àti ilé fún ọmọ.

 •   Owó tó ń wọlé.

   Ṣé wàá lè ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, kó o bójú tó ojúṣe ìdílé àtàwọn ojúṣe míì, tí ọ̀kan ò sì ní pàkan lára?

 Ìlànà Bíbélì: “Èwo nínú yín ló máa fẹ́ kọ́ ilé gogoro, tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kó ṣírò ohun tó máa ná an?”​—Lúùkù 14:28.

 Ronú nípa gbogbo ohun tó so mọ́ ọ̀rọ̀ náà. Àwọn ọ̀rọ̀ kan wà tẹ́ ẹ máa lè yanjú. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ ọ̀rọ̀ ọmọ bíbí lẹ̀ ń fà, ọkọ tàbí ìyàwó tó bá sọ pé òun ò fẹ́ ọmọ lè bi ara rẹ̀ pé:

 •   ‘Ṣé ohun tí mò ń sọ ni pé mi ò fẹ́ bímọ rárá, àbí mi ò kàn tíì ṣe tán báyìí?’

 •   ‘Ṣé mò ń wò ó pé mi ò ní lè tọ́ ọmọ yẹn dáadáa ni mo ṣe ń sọ pé mi ò fẹ́ bímọ?’

 •   ‘Àbí ẹ̀rù ń bà mí pé ẹnì kejì mi ò ní ráyè tèmi mọ́?’

 Bákan náà, ọkọ tàbí ìyàwó tó fẹ́ ọmọ lè ronú lórí àwọn ìbéèrè bíi:

 •   ‘Ṣé a ti ṣe tán láti ṣe ojúṣe obí báyìí?’

 •   ‘Ṣé agbára wa máa ká ìnáwó ọmọ títọ́?’

 Ìlànà Bíbélì: “Ọgbọ́n tó wá láti òkè . . . ń fòye báni lò.”​—Jémíìsì 3:17.

 Wo àǹfààní tó wà nínú èrò tí ẹnì kejì ẹ ní. Èèyàn méjì lè ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ kan náà, àmọ́ kí èrò wọn yàtọ̀ lórí ẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ló rí pẹ̀lú àwọn tọkọtaya, àwọn náà lè gbé ọ̀rọ̀ kan yẹ̀ wò, kí èrò tí kálukú wọn ní nípa ẹ̀ sì yàtọ̀. Àpẹẹrẹ kan ni tó bá dọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa náwó. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé èrò yín ò jọra lórí ọ̀rọ̀ kan, tẹ́ ẹ sì fẹ́ jọ sọ ọ́ kó lójú, ẹ bẹ̀rẹ̀ látibi tí èrò yín ti jọra.

 •   Kí ló jọra nínú ohun tẹ́yin méjèèjì ń fẹ́?

 •   Àǹfààní wo ló wà nínú èrò tí kálukú yín ní?

 •   Kí ìgbéyàwó yín má bàa níṣòro, ṣé ọ̀kan nínú yín lè fara mọ́ èrò ẹnì kejì, àbí kí ẹ̀yin méjèèjì kúkú jọ gba ti ara yín rò?

 Ìlànà Bíbélì: “Kí kálukú máa wá ire ti ẹlòmíì, kì í ṣe ti ara rẹ̀.”​—1 Kọ́ríńtì 10:24.

a Àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì kan wà tó yẹ kí tọkọtaya ti jọ sọ kí wọ́n tó ṣègbéyàwó. Síbẹ̀, ohun tí wọn ò retí lè ṣẹlẹ̀, tàbí kí ojú tí ọkọ tàbí ìyàwó fi ń wo nǹkan ti yí pa dà.​—Oníwàásù 9:11.