Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Káwọn Ọmọdé Máa Kàwé​—Apá 2: Ti Orí Ẹ̀rọ Tàbí Tinú Ìwé?

Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Káwọn Ọmọdé Máa Kàwé​—Apá 2: Ti Orí Ẹ̀rọ Tàbí Tinú Ìwé?

 Èwo ni ọmọ rẹ máa fẹ́ràn láti kà​—ṣé èyí táa tẹ̀ sórí ẹ̀rọ tàbí ti inú ìwé?

 Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló máa fẹ́ràn ti orí ẹ̀rọ. Dókítà Jean M. Twenge sọ pé: “Lásìkò wa yìí tí Íńtánẹ́ẹ̀tì ti délé dóko, tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ń lo fóònù tàbí kọ̀ǹpútà, wọn kì í fẹ́ kàwé lórí bébà mọ́ torí ó tètè máa ń sú wọn.” a

 Ká sòótọ́, kíkàwé lórí ẹ̀rọ ní àǹfààní tiẹ̀. Ọmọ ogún ọdún kan tó ń jẹ́ John sọ pé: “Ìwé orí ẹ̀rọ ni wọ́n ń lò ní ilé ìwé tí mo lọ, abala tí wọ́n fi ń ṣèwádìí tó wà lórí ẹ̀ máa ń jẹ́ kí n tètè rí àwọn ìsọfúnni tí mo nílò.”

 Táwọn èèyàn bá ń kàwé látorí ẹ̀rọ, wọ́n tún máa ń ní àǹfààní sáwọn nǹkan míì tó máa jẹ́ kí ìwé kíkà náà rọrùn fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, ẹni tó ń kàwé lè tẹ ìlujá kan, kíyẹn sì fún un láǹfààní láti wo fídíò, kó gbọ́ àtẹ́tísí, kó rí ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ tàbí kó ṣe àwọn nǹkan míì nípa ohun tó ń kà. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé kò sí àǹfààní kankan nínú kíka ìwé orí bébà?

 Àwọn kan gbà pé káwọn ka ìwé lórí bébà ló dáa jù táwọn bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀. Kí nìdí?

  •   Ó máa ń jẹ́ kéèyàn pọkàn pọ̀. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Nathan sọ pé, “Àwọn ìpolówó ọjà àtàwọn nǹkan míì tó máa ń yọ kì í jẹ́ kí n lè pọkàn pọ̀ tí mo bá ń kàwé lórí ẹ̀rọ.”

     Ìṣòro kan náà ni Karen tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún ní. Ó sọ pé: “Tí mo bá ń kàwé lórí fóònù tàbí tablet, àwọn nǹkan míì tó wà lórí fóònù máa ń pín ọkàn mi níyà, ó sì lè máa ṣe mí bíi kí n gbá géèmù.”

     Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa lo àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ.”​—Kólósè 4:​5, Phillips.

     Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣé ọmọ rẹ lè kó ara rẹ̀ níjàánu, kó sì pọkàn pọ̀ tó bá ń kàwé tàbí kẹ́kọ̀ọ́ lórí fóònù? Tí kò bá lè pọkàn pọ̀ ńkọ́, báwo lo ṣe lè ràn án lọ́wọ́?

     Àbá: Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ̀ pé tí àwọn ohun tó wà lórí fóònù bá ń pín ọkàn rẹ̀ níyà tó bá ń kàwé, ó máa lo ọ̀pọ̀ àkókò nídìí iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ̀, ìyẹn sì máa dín àkókò tó lè fi ṣe àwọn nǹkan míì kù.

  •   Bó ṣe lè lóye ohun tó ń kà. Ìwé kan tó ń jẹ́ Be the Parent, Please sọ pé: “Ìwádìí fi hàn pé ohun téèyan kà lórí ìwé máa ń yéni ju torí ẹ̀rọ lọ.”

     Ìdí ni pé àwọn tó bá ń kàwé lórí ẹ̀rọ èèyàn máa ń yára kàwé, lópọ̀ ìgbà wọn kì í ronú lórí ohun tí wọ́n ń kà. Òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ Nicholas Carr sọ pé: “A máa ń fẹ́ mọ ọ̀pọ̀ nǹkan láàárín àkókò díẹ̀ tá a bá ń kàwé lórí ẹ̀rọ.” b

     Nígbà míì, àǹfààní wà nínú kéèyàn yára kàwé. Bí Carr ṣe sọ, ìṣòro ibẹ̀ ni pé “ó ti ń di ọ̀nà tó mọ́ wa lára láti kàwé.” Torí náà, tó bá mọ́ ọmọ rẹ lára láti máa yára kàwé, ohun tó ń kà lè má wọ̀ ọ́ lọ́kàn.

     Ìlànà Bíbélì: “Pẹ̀lú gbogbo ohun tí o sì ní, ní òye.”​—Òwe 4:7.

     Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣé o lè ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ lórí kókó kan ì báà jẹ́ nínú ìwé tàbí lórí ẹ̀rọ?

     Àbá: Kò síbi téèyàn ò ti lè kàwé yálà nínú ìwé tàbí lórí ẹ̀rọ. Méjèèjì ló láǹfààní tiẹ̀. Torí náà má ṣàṣejù. Àwọn nǹkan tí wọ́n fi kún ìwé orí ẹ̀rọ lè jẹ́ ká tètè lóye ohun tí à ń kà. Torí náà, má ṣe rin kinkin pé ọ̀nà kan pàtó ni kí ọmọ rẹ máa gbà kàwé, méjèèjì ló ní ibi tó dáa sí àti ibi tó kù sí. Yàtọ̀ síyẹn, má gbàgbé ọmọ kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra.

  •   Bó ṣe lè rántí ohun tó kà. Ferris Jabr sọ nínú àpilẹ̀kọ kan tó wà nínú ìwé ìròyìn Scientific American pé, “ó lè ṣòro láti ràntí ohun tí à ń kà, tàbí kí ọpọlọ wa ṣiṣẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ tá a bá ń kàwé lórí ẹ̀rọ ní ìfiwéra pẹ̀lú èyí tá a bá kà nínú ìwé.”

     Tí èèyàn bá ń ka nǹkan látinu ìwé, ó máa ń rọrùn láti fojú inú yàwòrán ohun tá à ń kà tàbí ká tiẹ̀ rántí ojú ìwé tá a ti rí i. Ṣe ló máa dà bíi pé a sàmì sí àwọn ohun tá a rí, ká lè pa dà síbẹ̀ tá a bá nílò rẹ̀.

     Láfikún sí i, àwọn olùṣèwádìí ti rí i pé àwọn tó ń ka ìsọfúnni tí wọ́n tẹ̀ sínú ìwé máa ń rántí ohun tí wọ́n kà dáadáa. Ohun tó sì fà á ni pé wọ́n fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí wọ́n ń kà.

     Ìlànà Bíbélì: “Má ṣe jẹ́ kí ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ àti làákàyè bọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́.”​—Òwe 3:21.

     Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣé ó máa ń ṣòro fún ọmọ rẹ láti rántí ohun tó kà? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo lo ṣe lè ràn án lọ́wọ́ kó lè mú ọ̀nà tó ń gbà kẹ́kọ̀ọ́ sunwọ̀n sí i? Ṣé o lè rọ̀ ọ́ pé kó kà á nínú ìwé dípò orí ẹ̀rọ?

     Àbá: Kì í ṣe ohun tí ọmọ rẹ ń lò láti kẹ́kọ̀ọ́ ló ṣe pàtàkì, bí ko ṣe bó ṣe máa lóye ohun tó kọ́. Nígbà míì, àwọn èèyàn máa ń ronú pé àwọn mọ̀wé kà gan-an lórí ẹ̀rọ.

a Látinú ìwé iGen.

b Látinú ìwé The Shallows.