Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àkóbá Wo Ni Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Lè Ṣe fún Ọmọ Ẹ?

Àkóbá Wo Ni Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Lè Ṣe fún Ọmọ Ẹ?

Àwọn ọmọdé tètè máa ń mọwọ́ ẹ̀rọ ìgbàlódé dáadáa, bí ẹni fẹran jẹ̀kọ ni fún wọn, àmọ́ kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fáwọn àgbàlagbà láti mọwọ́ àwọn ẹ̀rọ yìí.

Síbẹ̀ àwọn kan kíyè sí i pé, àwọn ọmọ tó máa ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí ẹ̀rọ ìgbàlódé máa ń . . .

  • sọ ẹ̀rọ ìgbàlódé di bárakú.

  • halẹ̀ mọ́ àwọn míì lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí káwọn míì máa halẹ̀ mọ́ wọn.

  • wo àwòrán ìṣekúṣe, bí wọn ò tiẹ̀ ní in lọ́kàn láti wò ó.

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Ẹ̀RỌ ÌGBÀLÓDÉ LÈ DI BÁRAKÚ

Ó rọrùn gan-an káwọn nǹkan téèyàn máa ń ṣe lórí ẹ̀rọ ìgbàlódé di bárakú, àpẹẹrẹ kan ni kéèyàn máa gbá géèmù. Ìwé Reclaiming Conversation sọ ohun tó fà á, ó ní: “Àwọn tó ṣe ohun èlò orí fóònù ṣe é lọ́nà tó fi jẹ́ pé téèyàn bá ti bẹ̀rẹ̀ sí lò ó kò ní fẹ́ jáwọ́ ńbẹ̀.” Béèyàn bá ṣe ń pẹ́ nídìí ẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni owó púpọ̀ á máa wọlé fáwọn tó ṣe é.

RÒ Ó WÒ NÁ: Ṣáwọn ọmọ ẹ kì í pẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ nídìí fóònù tàbí kọ̀ǹpútà wọn? Báwo lo ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa lo àkókò wọn lọ́nà tó dáa?​—ÉFÉSÙ 5:​15, 16.

ÀWỌN TÓ Ń HALẸ̀ MỌ́NI LÓRÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ

Táwọn kan bá wà lórí ìkànnì àjọlò, wọ́n máa ń halẹ̀ mọ́ni. Wọ́n máa ń sọ ọ̀rọ̀kọ́rọ̀, wọn máa ń rí àwọn èèyàn fín tàbí kí wọ́n dìídì máa múnú bí wọn.

Ìdí táwọn kan fi máa ń sọ ìsọkúsọ tàbí ṣe ohun tí ò dáa lóri ìkànnì àjọlò ni pé wọ́n fẹ́ káwọn èèyàn gba tiwọn, kí wọ́n sì di gbajúmọ̀. Ẹnì kan sì lè máa bínú torí ó gbà pé ìwà àìdáa ni wọ́n hù sóun bí wọn ò ṣe pe òun síbi àríyá kan.

RÒ Ó WÒ NÁ: Ṣáwọn ọmọ ẹ kì í kan àwọn èèyàn lábùkù tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ̀ẹ̀tì? (Éfésù 4:31) Báwo ló ṣe máa ń rí lára wọn táwọn èèyàn bá ń ṣe nǹkan tí wọn ò sì pè wọ́n síbẹ̀?

ÀWÒRÁN ÌṢEKÚṢE

Íńtánẹ́ẹ̀tì ti mú kó rọrùn láti wo àwòrán ìṣekúṣe. Táwọn òbí bá tiẹ̀ ṣe nǹkan sórí fóònù tàbí kọ̀ǹpútà káwọn ọmọ má bàa dórí ìkànnì tí wọ́n ti lè wo ìwòkuwò, àwọn ọmọ ṣì lè rí nǹkan tí ò dáa wò.

Kò bófin mu kéèyàn máa fi àwòrán ìhòòhò ara ẹ̀ ránṣẹ́ sáwọn míì tàbí kó ní káwọn míì fi àwòrán ìhòòhò ara wọn ránṣẹ́ sóun. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ lè jẹ̀bi ẹ̀sùn fífi àwòrán ìṣekúṣe han ọmọdé, ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn sì ni.

RÒ Ó WÒ NÁ: Báwo lo ṣe lè ran ọmọ ẹ lọ́wọ́ kó má bàa wo àwòrán ìṣekúṣe, kó má sì fi ránṣẹ́ sáwọn míì?​—ÉFÉSÙ 5:3, 4.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

KỌ́ ỌMỌ RẸ

Àwọn ọmọdé tètè máa ń mọwọ́ ẹ̀rọ ìgbàlódé lóòótọ́, síbẹ̀ ó yẹ káwọn òbí kọ́ wọn béèyàn ṣe ń lò ó láìséwu. Ìwé kan tó ń jẹ́ Indistractable sọ pé téèyàn bá gbé fóònù tàbí kọ̀ǹpútà lé ọmọ kan lọ́wọ́ nígbà tí ò tíì mọ béèyàn ṣe ń lò ó láìséwu, “ṣe ló dà bí ìgbà téèyàn ní kọ́mọ náà kán lu agbami láì mọ̀wẹ̀.”

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tó yẹ kó tọ̀; kódà tó bá dàgbà, kò ní kúrò nínú rẹ̀.” ​— ÒWE 22:6.

Sàmì sí àwọn tí wàá fẹ́ tẹ̀ lé lára àwọn àbá yìí tàbí kó o kọ èyí tíwọ fúnra ẹ ronú kàn.

  • Màá bá ọmọ mi sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe lè máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn tó bá wà lórí ìkànnì àjọlò

  • Màá jẹ́ kọ́mọ mi mọ ohun tó lè ṣe tó bá gbà pé àwọn èèyàn ò ka òun sí

  • Màá ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe kọ́mọ mi má bàa wo ìwòkuwò

  • Màá máa yẹ fóònù ọmọ mi wò látìgbàdégbà kí n lè mọ ohun tó wà lórí ẹ̀

  • Màá pinnu iye àkókò tí ọmọ mi á máa lò nídìí fóònù ẹ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan

  • Mi ò ní jẹ́ kó máa dá nìkan lo fóònù nínú yàrá ẹ̀ lóru

  • Màá ṣòfin pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ lo fóònù tàbí kọ̀ǹpútà ẹ̀ nígbà tá a bá ń jẹun