Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Bí Àwọn Èèyàn Á Ṣe Máa Hùwà Lónìí?

Ṣé Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Bí Àwọn Èèyàn Á Ṣe Máa Hùwà Lónìí?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

 Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ìwà àwọn èèyàn níbi gbogbo láyé á máa burú sí i ní àkókò wa yìí. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ò ní tẹ̀ lé àwọn ìIànà gíga tí Ọlọ́run fún wa mọ́, wọn ò sì ní hùwà ọmọlúàbí mọ́. a (2 Tímótì 3:1-5) Àmọ́ o, Bíbélì tún sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn kan ò ní bá wọn lọ́wọ́ sáwọn ìwà burúkú yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, wọ́n á sapá kí àwọn èèyàn burúkú má kéèràn ràn wọ́n, kí ìrònú àti ìṣe wọn lè máa bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.—Àìsáyà 2:2, 3.

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa

 Kí ni Bíbélì sọ nípa bí àwọn èèyàn á ṣe máa ronú àti bí wọ́n á ṣe máa hùwà lákòókò wa yìí?

 Bíbélì sọ onírúurú ìwàkiwà tó máa gba ayé kan, ìmọtara-ẹni-nìkan ló sì ń fa gbogbo àwọn ìwà yìí. Àwọn èèyàn ò ní lè ‘kó ara wọn níjàánu,’ wọ́n á “nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan” àti pé “wọ́n á fẹ́ràn ìgbádùn dípò Ọlọ́run.”—2 Tímótì 3:2-4.

 Bí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe sọ ló rí, àwọn èèyàn lónìí ò mọ̀ ju tara wọn lọ, ohun tó máa ṣe àwọn nìkan láǹfààní, tó máa jẹ́ kára tù àwọn nìkan, tó sì máa jẹ́ kí wọ́n gbà pé ayé tiwọn nìkan ló nítumọ̀ ni wọ́n mọ̀. Ìwà burúkú yìí ti wá gba ayé kan. Ìwà tèmi nìkan ti gba ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn débi pé wọn ò “nífẹ̀ẹ́ ohun rere.” Ìyẹn ni pé, wọn ò lè nífẹ̀ẹ́ ohun tó dára mọ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn ti ya “aláìmoore,” torí náà, wọn kì í ronú pé ó yẹ káwọn dúpẹ́ oore táwọn míì ṣe fún wọn tàbí kí wọ́n fi ìmoore hàn fún àwọn nńkan tí wọ́n ní.—2 Tímótì 3:2, 3.

 Ìmọtara-ẹni-nìkan ló ń fà àwọn ìwà míì tó jẹ́ ara àmì ọjọ́ ìkẹyìn:

  •   Ojúkòkòrò. Àwọn tó “nífẹ̀ẹ́ owó” pọ̀ gan-an, wọ́n sì gbà pé owó tàbí àwọn nǹkan ìní wọn ló fi hàn pé ayé àwọn dáa.—2 Tímótì 3:2.

  •   Ìgbéraga. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló “jẹ́ afọ́nnu, agbéraga” àti “ajọra-ẹni-lójú.” (2 Tímótì 3:2, 4) Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ máa ń fi owó wọn, ẹ̀bùn àbínibí wọn àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n ní yangàn.

  •   Ìfọ̀rọ̀-èké-banijẹ́. Kò sí ibi táwọn “asọ̀rọ̀ òdì” àti àwọn “abanijẹ́” ò sí lónìí. (2 Tímótì 3:2, 3) Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí àwọn tó máa ń sọ̀rọ̀ burúkú nípa Ọlọ́run àtàwọn èèyàn, tí wọ́n sì máa ń parọ́ mọ́ wọn.

  •   Olóríkunkun. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ “aláìṣòótọ́,” “ẹni tí kì í fẹ́ ṣe àdéhùn,” “ọ̀dàlẹ̀” àti “alágídí.” (2 Tímótì 3:2-4) Wọn kì í fẹ́ gbọ́ tẹlòmíì, wọn kì í sì mú ìlérí tàbí àdéhùn wọn ṣẹ.

  •   Ìwà ipá. Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí “burú gan-an,” wọ́n máa ń tètè bínú, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí wọ́n hùwà ìkà tàbí ìwà ipá.—2 Tímótì 3:3.

  •   Ìwà tí kò bófin mu. Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé “ìwà tí kò bófin mu máa pọ̀ sí i” ní àkókò wa. (Mátíù 24:12) Ó tún sọ tẹ́lẹ̀ pé “rògbòdìyàn” tàbí “ìdàrúdàpọ̀” à máa ṣẹlẹ̀ níbi gbogbo.—Lúùkù 21:9, àlàyé ìsàlẹ̀.

  •   Kò sí ìfẹ́ nínú ìdílé. Àwọn ọmọ tí kì í ‘gbọ́ràn sí òbí’ àti àwọn “tí kò ní ìfẹ́ àdámọ́ni [nínú ìdílé]” ti jẹ́ kí ìṣòro ìdílé máa pọ̀ sí i, irú bíi káwọn òbí pa àwọn ọmọ wọn tì, kí wọ́n máa hùwà àìdáa sí ọmọdé àti ìwà ipá inú ilé.—2 Tímótì 3:2, 3.

  •   Àwọn tó ń fi ẹ̀sìn bojú. Àwọn èèyàn tó ń díbọ́n bí “ẹni tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn” túbọ̀ ń pọ̀ ṣí i. (2 Tímótì 3:5) Dípò kí wọ́n máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ọ̀rọ̀ dídùn tí àwọn olórí ẹ̀sìn wọn ń sọ, tí wọ́n fẹ́ràn láti máa gbọ́ ni wọ́n ń tẹ̀ lé.—2 Tímótì 4:3, 4.

 Àkóbá wo ni àwọn tí ò mọ̀ ju tara wọn lọ máa ń ṣe fáwọn míì?

 Ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan tó ń pọ̀ sí i ti fa ìdààmú ọkàn àti ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára fún ọ̀pọ̀ èèyàn. (Oníwàásù 7:7) Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ owó máa ń lu àwọn míì ní jìbìtì. Àwọn èèyàn tí kò ní ìfẹ́ àdámọ́ni nínú ìdílé máa ń hùwà àìdáa sáwọn ará ilé wọn, èyí sì lè jẹ́ kí àwọn tí wọ́n hùwà àìdáa sí ní ro ara wọn pin tàbí kí wọ́n fẹ́ gbẹ̀mí ara wọn. Àwọn ọ̀dàlẹ̀ èèyàn àtàwọn aláìṣòótọ́ náà ti kó ẹ̀dùn ọkàn tí kì í lọ bọ̀rọ̀ bá àwọn tí wọ́n hùwà ọ̀dàlẹ̀ tàbí ìwà àìṣòótọ́ sí.

 Kí nìdí tí ìwà àwọn èèyàn à fi máa burú sí i?

 Bíbélì sọ ìdí rẹ̀ gan-an tí ìwà àwọn èèyàn fi ń burú sí i:

  •   Ìfẹ́ táwọn èèyàn ní sí Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wọn ti ń dín kù. (Mátíù 24:12) Torí ẹ̀ ni ìwà ìmọta ra-ẹni-nìkan ṣe ń pọ̀ sí i.

  •   Wọ́n ti lé Sátánì Èṣù kúrò ní ọ̀run wá sí sàkání ilẹ̀ ayé. (Ìfihàn 12:9, 12) Látìgbà yẹn ló ti ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ya onímọtara-ẹni-nìkan.—1 Jòhánù 5:19.

 Kí ló yẹ ká ṣe táwọn tó yí wa ká bá ń hùwà burúkú?

 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Yẹra fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀.” (2 Tímótì 3:5) Ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé ká máa yẹra fún gbogbo èèyàn láwùjọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ò yẹ ká ṣọ́ra, ká má lọ máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó jẹ́ pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, tí wọn ò sì nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.—Jémíìsì 4:4.

 Ṣé gbogbo èèyàn ni ìwà wọn á máa burú sí i?

 Rárá o. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n “ń kẹ́dùn, tí wọ́n sì ń kérora torí gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe” láyé. (Ìsíkíẹ́lì 9:4) Àwọn yìí ò ní lọ́wọ́ sí ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan, wọ́n á sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run ní ìgbésí ayé wọn. Wọ́n yàtọ̀ gédégbé sí àwọn èèyàn tó kù nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn. (Málákì 3:16, 18) Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa sapá láti gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo èèyàn, wọn ò sì ní jagun tàbí kí wọ́n hùwà ipá.—Míkà 4:3.

 Ṣé ìwà àwọn èèyàn máa burú débi pé ayé yìí máa dàrú?

 Rárá o. Ìwà àwọn èèyàn ni gbogbo ayé kò ní burú débi pé ayé yìí máa dàrú. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run máa mú àwọn tí kò pa òfin rẹ̀ mọ́ kúrò láìpẹ́. (Sáàmù 37:38) Ọlọ́run á mú “ayé tuntun” wá, ìyẹn àwùjọ àwọn èèyàn tuntun tó jẹ́ olódodo, tí wọ́n máa gbé ní àlàáfíà lórí ilẹ̀ ayé títí láé. (2 Pétérù 3:13; Sáàmù 37:11, 29) Ó dájú pé ohun tí à ń retí yìí máa ṣẹlẹ̀. Ní báyìí, Bíbélì ń ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti yí ìgbésí ayé wọn pa dà sí èyí tó máa bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.—Éfésù 4:23, 24.

a Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àtàwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé fi hàn pé a ti wà ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tó máa “jẹ́ àkókò tí nǹkan máa le gan-an.” (2 Tímótì 3:1) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, wo “Kí Ni Àmì ‘Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn’ Tàbí ‘Àkókò Òpin’?