Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Àìsáyà 41:10​—“Má Bẹ̀ru; Nitori Mo Wà Pẹlu Rẹ”

Àìsáyà 41:10​—“Má Bẹ̀ru; Nitori Mo Wà Pẹlu Rẹ”

 “Má bẹ̀rù, torí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má ṣàníyàn, torí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Màá fún ọ lókun, àní, màá ràn ọ́ lọ́wọ́, ní tòótọ́, màá fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin.”​—Àìsáyà 41:​10, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Iwọ má bẹ̀ru; nitori mo wà pẹ̀lu rẹ; má foyà; nitori emi ni Ọlọ́run rẹ: emi o fún ọ ni okun; nitotọ, emi o ràn ọ lọwọ; nitotọ, emi o fi ọwọ́ ọ̀tun ododo mi gbe ọ sokè.”​—Àìsáyà 41:​10, Bíbélì Mímọ́.

Ìtumọ̀ Àìsáyà 41:10

 Jèhófà a Ọlọ́run fi dá àwọn tó ń fi òótọ́ sìn ín lójú pé, ìṣòro yòówù kó máa bá wọn fínra, òun ò ní fi wọ́n sílẹ̀.

 “Mo wà pẹ̀lú rẹ.” Jèhófà jẹ́ kí àwọn tó ń sìn ín mọ̀ pé wọn ò dá wà, ìdí nìyẹn tí wọn ò fi gbọ́dọ̀ bẹ̀rù. Torí pé Ọlọ́run mọ ohun tí wọ́n ń fojú winá rẹ̀ tó sì ń gbọ́ àdúrà wọn, ṣe ló dà bíi pé ó wà pẹ̀lú wọn.​—Sáàmù 34:15; 1 Pétérù 3:12.

 “Èmi ni Ọlọ́run rẹ.” Jèhófà fi àwọn tó ń sìn ín lọ́kàn balẹ̀ nígbà tó rán wọn létí pé òun ṣì jẹ́ Ọlọ́run wọn àti pé òun gbà kí wọ́n máa sin òun. Èyí á mú kó dá wọn lójú pé kò sí ohun náà tó lè ṣẹlẹ̀ tí Ọlọ́run ò fi ní gbèjà àwọn.​—Sáàmù 118:6; Róòmù 8:32; Hébérù 13:6.

 “Màá fún ọ lókun, àní, màá ràn ọ́ lọ́wọ́, ní tòótọ́, màá fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin.” Jèhófà sọ ohun kan náà ní ọ̀nà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kó lè fi hàn bó ṣe dájú tó pé òun á tì wọ́n lẹ́yìn. Jèhófà lo àfiwé ọ̀rọ̀ nínú gbólóhùn kẹta láti fi ṣàlàyé ohun tó máa ń ṣe tí àwọn èèyàn rẹ̀ bá nílò ìrànlọ́wọ́. Bí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, Ọlọ́run lè na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sí i kó sì fi fà á dìde.​—Àìsáyà 41:13.

 Ọ̀nà pàtàkì tí Ọlọ́run máa ń lo láti fún àwọn tó ń sìn ín lókun ni nípa Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ (Jóṣúà 1:8; Hébérù 4:12) Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó bá dojú kọ ìṣòro bí ipò òṣì, àìlera, tàbí ikú èèyàn wọn lè rí ọgbọ́n tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Òwe 2:6, 7) Ọlọ́run tún lè lo ẹ̀mí mímọ́, tàbí agbára ìṣiṣẹ́ rẹ̀, láti mú káwọn tó ń sìn ín ronú lọ́nà tó tọ́ kí àdánwò má bàá borí wọn.​—Àìsáyà 40:29; Lúùkù 11:13.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Àìsáyà 41:10

 Ọ̀rọ̀ inú Àìsáyà 41:10 yìí tu àwọn Júù olóòótọ́ tí wọ́n wá kó lẹ́rú lọ sí Bábílónì nínú. Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé tó bá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àkókò tí àwọn Júù máa kúrò ní ìgbèkùn, wọ́n máa gbọ́ ìròyìn nípa ajagunṣẹ́gun kan tó máa pa àwọn ìlú tó yí Bábílónì ká run tó sì máa dúnkookò mọ́ Bábílónì. (Àìsáyà 41:2-4; 44:1-4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù máa ba àwọn ará Bábílónì àti àwọn tó yí wọ́n ká nígbà tí wọ́n bá gbọ́ irú ìròyìn bẹ́ẹ̀, àwọn Júù ò ní bẹ̀rù, torí pé Jèhófà máa dáàbò bò wọ́n. Láti mú kí èyí dá wọn lójú, ìgbà mẹ́ta ló sọ pé kí wọ́n “má bẹ̀rù.”​—Àìsáyà 41:​5, 6, 10, 13, 14.

 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù olóòótọ́ tó wà ní ìgbèkùn ní Bábílónì ni Jèhófà Ọlọ́run kọ́kọ́ darí ọ̀rọ̀ inú Àìsáyà 41:10 sí, ó mú kí ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ yìí wà lákọọ́lẹ̀ kó lè tu gbogbo àwọn tó ń sìn ín nínú. (Àìsáyà 40:8; Róòmù 15:4) Ó ń ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ lóde òní bó ṣe ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ nígbà àtijọ́.

Ka Àìsáyà orí 41 àti àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tí wọ́n fi ṣàlàyé ọ̀rọ̀ àti àwọn atọ́ka etí ìwé.

a Jèhófà ni orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gangan.​—Sáàmù 83:18.