Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 45

Àṣàrò Ọkàn Mi

Àṣàrò Ọkàn Mi

(Sáàmù 19:14)

  1. 1. Kí àwọn èrò ọkàn mi,

    Tí mò ń ṣàṣàrò lé lórí

    Máa múnú rẹ dùn, Jèhófà,

    Kó sì mú kí n dúró ṣinṣin.

    T’àníyàn bá bò mí mọ́lẹ̀,

    Tí kò jẹ́ kí n lè sùn lóru,

    Kí n máa rántí rẹ, Jèhófà,

    Àti àwọn ohun tó tọ́.

  2. 2. Gbogbo ohun tó jẹ́ mímọ́

    Àti àwọn ìwà rere;

    Ohun tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa,

    Ni mo fẹ́ máa rò lọ́kàn mi.

    Jáà, ìrònú rẹ dára gan-an!

    Ó pọ̀ kọjá àfẹnusọ.

    Màá ṣàṣàrò lé ọ̀rọ̀ rẹ,

    Jọ̀ọ́, jẹ́ kó máa gbà mí lọ́kàn.