Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ORIN 46

A Dúpẹ́, Jèhófà

Yan Àtẹ́tísí
A Dúpẹ́, Jèhófà

(1 Tẹsalóníkà 5:18)

 1. 1. A dúpẹ́ Jèhófà, fún ìmọ́lẹ̀ rẹ

  Tó ń tàn sórí wa ní ojoojúmọ́.

  A dúpẹ́ pé a lè gbàdúrà sí ọ,

  Tá a lè sọ gbogbo ‘ṣòro wa fún ọ.

 2. 2. A dúpẹ́ Jèhófà fọ́mọ rẹ ọ̀wọ́n,

  Tó fìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣẹ́gun ayé yìí.

  A dúpẹ́, ò ń tọ́ wa ká lè ṣèfẹ́ rẹ,

  Ká sì lè mú àwọn ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.

 3. 3. A dúpẹ́ pá a láǹfààní láti wàásù

  Nípa òtítọ́ àt’orúkọ rẹ.

  A dúpẹ́ pé ìṣòro máa tán láìpẹ́,

  Ìbùkún ‘jọba rẹ yóò wà láéláé.