Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Àwọn Èèyàn Ṣe Ń Ba Ayé Yìí Jẹ́?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Àwọn Èèyàn Ṣe Ń Ba Ayé Yìí Jẹ́?

 “Ọ̀pọ̀ nǹkan táwọn èèyàn ń ṣe lónìí máa tó ba ayé yìí jẹ́. Lára àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ni pé omi máa ya wọ àwọn ìlú ńlá. Ooru tó gbóná janjan á máa mú. Àwọn ìjì tó ń bani lẹ́rù á máa jà. Omi tó ṣeé mu ò ní tó. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹranko àti eweko ló sì máa pa run. Ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe àsọdùn o, ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ nìyẹn táwọn èèyàn ò bá jáwọ́ nínú bí wọ́n ṣe ń tú àwọn nǹkan olóró sáfẹ́fẹ́.”​—Ọ̀rọ̀ tí António Guterres tó jẹ́ akọ̀wé àgbà fún Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé sọ nínú ìròyìn Ìgbìmọ̀ Táwọn Ìjọba Ṣètò nípa Ojú Ọjọ́ Tó Ń Yí Pa Da tó jáde ní April 4, 2022.

 “Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti kìlọ̀ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mẹ́tàlélógún (423) ọgbà táwọn èèyàn ti ń gbafẹ́ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni àjálù ti máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́. Ohun tó sì fà á ni bí ojú ọjọ́ ṣe ń gbóná sí i. Ṣe làwọn nǹkan yìí dà bí àjálù tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀, bí iná àti àkúnya omi, àwọn yìnyín tó ń yọ́ àti ooru tó gbóná.”​—“Àkúnya Omi ní Yellowstone, Àmí Àjálù Tó Ń Bọ̀,” nínú ìwé ìròyìn The New York Times, June 15, 2022.

 Ṣé ohun táwọn èèyàn ti bà jẹ́ nínú ayé yìí ṣì máa látùnṣe? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ta ló máa tún un ṣe? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ.

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn máa ba ayé yìí jẹ́

 Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa “run àwọn tó ń run ayé.” (Ìfihàn 11:18) Ohun mẹ́ta la lè rí kọ́ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí:

  1.  1. Ohun táwọn èèyàn ń ṣe máa ba ayé yìí jẹ́ gan-an.

  2.  2. Ìwà ìbàjẹ́ yìí máa dópin.

  3.  3. Ọlọ́run ló máa tún ohun táwọn èèyàn ti bà jẹ́ ṣe, kì í ṣe àwọn èèyàn.

Ọ̀la ń bọ̀ wá dáa

 Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ‘ayé máa wà títí láé.’ (Oníwàásù 1:4) Kò sígbà táwọn èèyàn ò ní máa gbé inú ẹ̀.

  •   “Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.”​—Sáàmù 37:29.

 Gbogbo ohun táwọn èèyàn ti bà jẹ́ pátápátá ni Ọlọ́run máa tún ṣe.

  •   “Aginjù àti ilẹ̀ tí kò lómi máa yọ̀, aṣálẹ̀ tó tẹ́jú máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ó sì máa yọ ìtànná bíi sáfúrónì.”​—Àìsáyà 35:1.