Oníwàásù 1:1-18

  • Asán ni ohun gbogbo (1-11)

    • Ayé wà títí láé (4)

    • Àwọn ohun tó ń yí po ní ayé (5-7)

    • Kò sí ohun tuntun lábẹ́ oòrùn (9)

  • Ó níbi tí ọgbọ́n èèyàn mọ (12-18)

    • Ìmúlẹ̀mófo (14)

1  Àwọn ọ̀rọ̀ akónijọ,*+ ọmọ Dáfídì, ọba ní Jerúsálẹ́mù.+   Akónijọ sọ pé, “Asán* pátápátá gbáà!” “Asán pátápátá gbáà! Asán ni gbogbo rẹ̀!”+   Èrè wo ni èèyàn rí jẹ nínú gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ Èyí tó ń fi gbogbo agbára rẹ̀ ṣe lábẹ́ ọ̀run?*+   Ìran kan ń lọ, ìran kan sì ń bọ̀,Àmọ́ ayé wà* títí láé.+   Oòrùn ń yọ,* oòrùn sì ń wọ̀;Lẹ́yìn náà, ó ń yára* pa dà sí ibi tí á tún ti yọ.+   Ẹ̀fúùfù ń lọ sí gúúsù, ó sì ń yí lọ sí àríwá;Yíyí ló ń yí po nígbà gbogbo; ẹ̀fúùfù ń yí po ṣáá.   Gbogbo odò* ló ń ṣàn lọ sínú òkun, síbẹ̀ òkun kò kún.+ Ibi tí àwọn odò ti ṣàn wá, ibẹ̀ ni wọ́n ń pa dà sí, kí wọ́n tún lè ṣàn jáde.+   Ohun gbogbo ló ń kó àárẹ̀ báni;Kódà, ó kọjá ohun téèyàn lè sọ. Ìran kì í sú ojú;Bẹ́ẹ̀ ni etí kì í kọ gbígbọ́.   Ohun tó ti wà ni yóò máa wà,Ohun tí a sì ti ṣe la ó tún pa dà ṣe;Kò sí ohun tuntun lábẹ́ ọ̀run.*+ 10  Ṣé ohun kan wà tí a lè sọ pé: “Wò ó, tuntun ni”? Ó ti wà tipẹ́tipẹ́;Ó ti wà ṣáájú àkókò wa. 11  Kò sí ẹni tó ń rántí àwọn èèyàn ayé àtijọ́;Kò sì sí ẹni tó máa rántí àwọn tó ń bọ̀;Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tó máa wá nígbà tó bá yá kò ní rántí àwọn náà.+ 12  Èmi, akónijọ, ló ti ń jọba lórí Ísírẹ́lì ní Jerúsálẹ́mù.+ 13  Mo fi ọgbọ́n+ ṣe ìwádìí àti àyẹ̀wò ohun gbogbo tí a ti ṣe lábẹ́ ọ̀run,+ ìyẹn iṣẹ́ tó ń tánni lókun tí Ọlọ́run fún ọmọ aráyé tó ń mú kí ọwọ́ wọn dí. 14  Mo rí gbogbo iṣẹ́ tí a ṣe lábẹ́ ọ̀run,* Sì wò ó! asán ni gbogbo rẹ̀, ìmúlẹ̀mófo.*+ 15  Ohun tó ti wọ́, a kò lè mú un tọ́,Ohun tí kò sì sí, a kò lè kà á. 16  Nígbà náà, mo sọ lọ́kàn mi pé: “Wò ó! Mo ti ní ọgbọ́n tó pọ̀ gan-an ju ẹnikẹ́ni tó wà ṣáájú mi ní Jerúsálẹ́mù,+ ọkàn mi sì ti kó ọgbọ́n àti ìmọ̀+ tó pọ̀ gan-an jọ.” 17  Mo fi ọkàn mi sí mímọ ọgbọ́n àti mímọ ìwà wèrè* àti mímọ ìwà ẹ̀gọ̀,+ èyí pẹ̀lú jẹ́ ìmúlẹ̀mófo. 18  Nítorí ọ̀pọ̀ ọgbọ́n máa ń mú ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ wá,Tó fi jẹ́ pé ẹni tó ń fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ ń fi ìrora kún ìrora.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “apenijọ.”
Tàbí “Òtúbáńtẹ́.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn?”
Ní Héb.,“dúró.”
Tàbí “tan ìmọ́lẹ̀.”
Tàbí “sáré tete.”
Tàbí “odò ìgbà òtútù; odò abágbàrìn.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “lílépa ẹ̀fúùfù.”
Tàbí “ìwà òmùgọ̀ tó burú jáì.”