Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Awọn Ẹmi-eṣu Jẹ Panipani!

Awọn Ẹmi-eṣu Jẹ Panipani!

Satani ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀ ti fi igba gbogbo jẹ oniwa-ika ati elewu. Ni atetekọṣe Satani pa awọn ohun ọsin ati awọn iranṣẹ Joobu oluṣotitọ naa. Lẹhin naa o pa awọn ọmọ Joobu mẹwaa nipa mimu ki “ẹfuufu nlanla” bi ile ti wọn wà ninu rẹ̀ wó. Lẹhin naa Satani kọlu Joobu pẹlu “oówo kíkankíkan lati atẹlẹsẹ rẹ̀ lọ de àtàrí rẹ̀.”—Joobu 1:7-19; 2:7.

Ni ọjọ Jesu, awọn ẹmi-eṣu sọ awọn eniyan kan di odi ati afọju. (Matiu 9:32, 33; 12:22) Wọn fiya jẹ ọkunrin kan wọn sì mu ki o fi òkúta ya ara rẹ̀ palapala. (Maaku 5:5) Wọn tun mu ọdọmọkunrin kan kigbe jade, wọn gbé e ṣánlẹ̀, “wọn sì fi gìrì mú un lọna iwa ipa.”—Luuku 9:42NW.

Ni igba atijọ, awọn ẹmi-eṣu nmu awọn eniyan ṣaisan ti wọn sì nfi gìrì mú awọn miiran

Lonii, Satani ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀ ṣì jẹ apaniyan bii ti tẹlẹ. Niti tootọ, iwa ibi wọn ti ga soke sii lati igba ti a ti le wọn kuro ni ọrun. Irohin yika aye jẹrii si iwa ika wọn. Wọn nfi amodi kọlu awọn eniyan. Wọn ńdáyàjá awọn miiran ni òru, ni fifi oorun dù wọn tabi jijẹ ki wọn lá awọn àlá bibanilẹru. Wọn nba awọn miiran lòpọ̀ lọna ika. Sibẹ awọn miiran ni wọn ńyà ni wèrè, nmu ki wọn paniyan, tabi pa ara wọn.

Awọn ẹmi-eṣu lonii nmu awọn eniyan kan jẹ oniwa-ipa; wọn ńdáyàjá awọn ẹlomiran ni òru, wọn njẹ ki wọn lá awọn àlá bibanilẹru

Lintina, ẹni ti o ngbe ni Suriname, rohin pe ẹmi-eṣu, tabi ẹmi buburu, kan pa 16 ninu mẹmba idile rẹ̀ ti wọn sì fiya jẹ ẹ́ ni ara iyara ati ni ero ori fun 18 ọdun. Lati inu iriri ara-ẹni oun sọ pe awọn ẹmi-eṣu “ngbadun fifi ìyà jẹ awọn ojiya ti ko ba fọwọsowọpọ pẹlu wọn de oju iku.”

Ṣugbọn Jehofa lagbara lati daabobo awọn iranṣẹ rẹ̀ kuro lọwọ ikọluni Satani.—Owe 18:10.