Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Báwo lo ṣe lè jẹ́ òbí rere?

Ǹjẹ́ o máa ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ ọlọ́run?

Àwọn ọmọ máa ń ṣe dáadáa nínú ilé tí bàbá àti ìyá bá ti fẹ́ràn ara wọn, tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn. (Kólósè 3:14, 19) Jèhófà Ọlọ́run máa ń  gbóríyìn fún Ọmọ rẹ̀. Bákan náà, àwọn òbí tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì máa ń gbóríyìn fún wọn.—Ka Mátíù 3:17.

Baba wa ọ̀run máa ń tẹ́tí sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì máa ń kíyè sí bí nǹkan ṣe ń rí lára wọn. Ó máa dáa kí àwọn òbí kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà, kí wọ́n sì máa fetí sí àwọn ọmọ wọn. (Jákọ́bù 1:19) Ẹ máa ro bí ọ̀rọ̀ ṣe ń rí lára àwọn ọmọ yín. Bí àwọn ọmọ bá tiẹ̀ sọ ohun kan tó kù díẹ̀ káàtó pàápàá, ẹ má ṣe kó ọ̀rọ̀ wọn dànù.—Ka Númérì 11:11, 15.

Báwo lo ṣe lè tọ́ àwọn ọmọ rẹ yanjú?

Ojúṣe ẹ̀yin òbí ni láti máa fún àwọn ọmọ yín ní ìlànà tí wọ́n á máa tẹ̀ lé. (Éfésù 6:1) Ó máa dáa kẹ́ ẹ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà. Ọ̀nà kan tí Jèhófà gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwa ọmọ rẹ̀ ni pé, ó fún wa ní àwọn ìlànà tó ṣe kedere. Ó sì sọ ohun tó máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ tá a bá ṣe àìgbọ́ràn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:3) Ọlọ́run kì í fipá mú wa láti tẹ̀ lé òfin rẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló jẹ́ ká mọ àǹfààní tá a máa rí tí a bá ń ṣe ohun tó tọ́.—Ka Aísáyà 48:18, 19.

Pinnu pé wà á tọ́ àwọn ọmọ rẹ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n lè máa ṣe ohun tó tọ́, kódà bí wọn kò bá sí lọ́dọ̀ rẹ. Bí Ọlọ́run ṣe máa ń fi àpẹẹrẹ rẹ̀ kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ kó o máa fi ìwà rere rẹ kọ́ àwọn ọmọ rẹ lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.—Ka Diutarónómì 6:5-7; Éfésù 4:32; 5:1.