KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ IKÚ NI ÒPIN ÌGBÉSÍ AYÉ Ẹ̀DÁ?
Aráyé Ń Sapá Kí Wọ́n Lè Ṣẹ́gun Ikú
Ọ̀tá tó ń bani lẹ́rù ni ikú jẹ́ fún àwa èèyàn. Ọjọ́ sì ti pẹ́ tí aráyé ti ń jà fitafita kí wọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Àmọ́, ńṣe ló máa ń dà bí àlá lójú wa tí ẹni tá a fẹ́ràn bá kú. Abájọ tó fi jẹ́ pé ní gbogbo àkókò tá a fi wà láàyè, pàápàá nígbà tá a ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, a lè máà ronú kan ikú, ká máa wò ó pé títí láé la ó máa wà, àmọ́ ẹ̀tàn lásán ni irú èrò bẹ́ẹ̀.
Bí àpẹẹrẹ, àwọn Fáráò àtijọ́ sapá gan-an kí wọ́n lè máa wà láàyè lẹ́yìn tí wọ́n bá kú, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹni tó tíì ṣakitiyan tó wọn lórí ọ̀rọ̀ yìí. Gbogbo ayé wọn ni wọ́n sì fi ń wá bí wọ́n ṣe lè borí ikú, kódà ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn òṣìṣẹ́ wọn ló kú sínú kìràkìtà náà. Bí àpẹẹrẹ ní ilẹ̀ Íjíbítì, itẹ́-òkú àwọn ọba tí wọ́n kọ́ jẹ́ ẹ̀rí pé wọ́n sapá kí wọ́n lè máa wà láàyè lọ, àmọ́ pàbó ni gbogbo ìsapá wọn já sí.
Bákan náà, àwọn olú ọba ilẹ̀ Ṣáínà tiraka kí wọ́n lè máa gbélé ayé kánrin kése, ọ̀nà míì làwọn tún gbé tiwọn gbà, oògùn àìkú ni wọ́n ń wá kiri. Bí àpẹẹrẹ, Olú-ọba Qin Shi Huang pàṣẹ pé káwọn oníṣègùn bá òun ṣe oògùn gbékú dè. Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn egbòogi tí wọ́n pò pọ̀ ló ní nǹkan olóró nínú. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn egbòogi tí wọ́n fún un ló ṣe ikú pa á.
Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún márùn-ún sẹ́yìn, ọmọ ilẹ̀ Sípéènì kan tó máa ń ṣèwádìí káàkiri tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ponce de León fi ọkọ̀ ojú omi rin ìrìn àjò lọ sí agbègbè Caribbean. Ìtàn sọ pé ìsun omi àjídèwe kan ló ń wá kiri. Lẹ́nu ìrìn àjò náà, ó dé ibi tí ìpínlẹ̀ Florida wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lóde òní. Àmọ́, lẹ́yìn ìjà ráńpẹ́ tó wáyé láàárín òun àtàwọn ọmọ Ìbílẹ̀ Amẹ́ríkà, ó pàpà kú náà ni. Kò sì sẹ́ni tó tíì rí ìsun omi àjídèwe kankan títí dòní, torí pé kò síbì tá a ti lè rí i.
Gbogbo àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí ló jà fitafita kí wọ́n lè ṣẹ́gun ikú. Àmọ́ bá ò tiẹ̀ fara mọ́ àwọn ọ̀nà tí wọ́n ń gbé e gbà, ta ni nínú wa ni kò wù kó bọ́ lọ́wọ́ ikú? Ká sòótọ́ kò sẹ́ni tó fẹ́ kú.
ǸJẸ́ A LÈ ṢẸ́GUN IKÚ?
Kí nìdí tí àwa èèyàn kì í fẹ́ kú? Bíbélì sọ ìdáhùn náà, ó ní Jèhófà * Ọlọ́run tó ṣẹ̀dá wa ti “ṣe ohun gbogbo ní rèterète ní ìgbà tirẹ̀. Àní àkókò tí ó lọ kánrin ni ó ti fi sínú ọkàn-àyà [aráyé] wọn.” (Oníwàásù 3:11) Kò wu àwa èèyàn pé kí á kàn gbé láyé fún ọgọ́rin [80] ọdún tàbí ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ ká sì kú, ohun tí a fẹ́ ni pé ká máa gbádùn àwọn ohun mèremère tó ń mú ilé ayé wuni títí láé. (Sáàmù 90:10) Ohun tí ó wù wá gan-an nìyẹn.
Kí nìdí tí Ọlọ́run ṣe fi “àkókò tí ó lọ kánrin” sí wa lọ́kàn? Ṣé ó kàn fẹ́ fìyẹn mú ayé sú wa ni? Ọlọ́run ò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ṣèlérí pé òun máa ṣẹ́gun ikú. Léraléra, ni Bíbélì sọ pé kò ní sí ikú mọ́, ó tún sọ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé a máa wà láàyè títí láé.—Wo àpótí tá a pè àkòrí rẹ̀ ní “Ọlọ́run Máa Ṣẹ́gun Ikú.”
Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Torí náà, ká má ṣe sọ̀rètí nù pé kò sẹ́ni tó lè ṣẹ́gun ikú, ó ṣe tán, Jésù fi dá wa lójú pé Ọlọ́run nìkan ló lè ṣẹ́gun ikú.
^ ìpínrọ̀ 9 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.