Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ IKÚ NI ÒPIN ÌGBÉSÍ AYÉ Ẹ̀DÁ?

Ikú Kọ́ Ni Òpin Ìgbésí Ayé Ẹ̀dá!

Ikú Kọ́ Ni Òpin Ìgbésí Ayé Ẹ̀dá!

Ní ọ̀sẹ̀ mélòó kan ṣáájú ikú Jésù, ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan wáyé ní abúlé kékeré kan tó ń jẹ́ Bẹ́tánì, èyí tó wà ní nǹkan bíi kìlómítà mẹ́ta sí Jerúsálẹ́mù. (Jòhánù 11:18). Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ Jésù tó ń jẹ́ Lásárù ni àìsàn ṣàdédé kọlù, ó sì kú.

Nígbà tí Jésù kọ́kọ́ gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé Lásárù sùn, àmọ́ òun fẹ́ lọ síbẹ̀ láti lọ jí i. (Jòhánù 11:11) Jésù rí i pé ọ̀rọ̀ yẹn kò yé àwọn ọmọlẹ́yìn òun, ló bá kúkú là á mọ́lẹ̀ pé: “Lásárù ti kú.”—Jòhánù 11:14.

Ọjọ́ kẹrin lẹ́yìn tí wọ́n ti sin Lásárù ni Jésù dé sí Bẹ́tánì kó lè wá tu Màtá nínú, ìyẹn àbúrò Lásárù. Nígbà tí Màtá rí Jésù, ó sọ pé: “Ká ní o ti wà níhìn-ín ni, arákùnrin mi kì bá kú.” (Jòhánù 11:17, 21) Jésù dá a lóhùn pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè.”—Jòhánù 11:25.

“Lásárù, jáde wá!”

Kí Jésù lè fi hàn pé ohun tí òun sọ kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán, ó lọ sí ibojì ti Lásárù wà, ó sì kígbe pé: “Lásárù, jáde wá!” (Jòhánù 11:43) Nígbà tí Lásárù fẹsẹ̀ ara rẹ̀ rìn jáde láti inú ibojì náà, ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ṣojú wọn lọ́jọ́ náà.

Ó kéré tán, Jésù ti jí ẹni méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ dìde lọ́nà ìyanu ṣáájú ti Lásárù. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọmọbìnrin Jáírù kú, Jésù jí i dìde. Àmọ́ kó tó jí ọmọ náà dìde, ó sọ fún àwọn tó wà níbẹ̀ pé ọmọbìnrin náà ń sùn.—Lúùkù 8:52.

Kíyè sí i pé, nínú àkọsílẹ̀ àjíǹde méjèèjì yìí, Jésù sọ pé àwọn tó ti kú ń “sùn” nínú sàréè. Kí nìdí tí àfiwé yẹn fi báa mu gan-an? Ìdí ni pé tí èèyàn bá ti sùn kò mọ ohunkóhun mọ́, ńṣe ló dà bí ìgbà tí èèyàn ń sinmi láìsí ìrora àti ìyà. (Oníwàásù 9:5; wo àpótí tá a pe àkòrí rẹ̀ ní  “Ikú Dà Bí Oorun Àsùnwọra.”) Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ìgbàanì mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí èèyàn bá  kú. Ìwé kan tó ń jẹ Encyclopedia of Religion and Ethics sọ pé: “Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù gbà pé ikú dà bí oorun, sàréè sì jẹ́ ibi tí àwọn olóòótọ́ tó ti kú ti ń sinmi.” *

Ìtùnú ló jẹ́ fún wa láti mọ̀ pé àwọn òkú kò lọ jìyà, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni wọ́n ń sùn nínú sàréè. A ti wá rí i pé ikú kì í ṣe àdììtú, a ti mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí èèyàn bá kú, torí náà kò yẹ ká bẹ̀rù ikú mọ́.

“BÍ ÈÈYÀN BÁ KÚ, ǸJẸ́ Ó TÚN LÈ WÀ LÁÀYÈ?”

Lóòótọ́ a máa ń gbádùn oorun àsùnwọra, àmọ́ kò sẹ́ni tó wù pé kí òun sùn kó máà jí mọ́. Ǹjẹ́ ìrètí kankan tiẹ̀ wà pé àwọn tó ti kú máa tún pa dà wà láàyè bíi ti Lásárù àti ọmọbìnrin Jáírù bí?

Ohun tí baba ńlá náà Jóòbù béèrè nìyẹn nígbà tí ìnira rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ já sí ikú fún un. Ó ní: “Bí èèyàn bá kú, ǹjẹ́ ó tún lè wà láàyè?”—Jóòbù 14:14.

Jóòbù fúnra rẹ̀ dáhùn ìbéèrè náà nígbà tó sọ nípa Ọlọ́run Olódùmarè pé: “Nigba naa iwọ yoo pè, emi yoo sì dá ọ lóhùn; iwọ yoo sì nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ ọwọ rẹ.” (Jóòbù 14:15, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Ó dá Jóòbù lójú pé Jèhófà ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí Ó máa jí gbogbo ìránṣẹ́ Rẹ̀ olóòótọ́ dìde. Ṣé kì í ṣe pé Jóòbù kàn ń tan ara rẹ̀ jẹ? Kò jẹ́ rí bẹ́ẹ̀.

Bí Jésù ṣe jí àwọn òkú dìde jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run ti fún Jésù lágbára lórí ikú. Kódà, Bíbélì sọ pé ọwọ́ Jésù ni “kọ́kọ́rọ́ ikú” wà. (Ìṣípayá 1:18) Lọ́jọ́ iwájú, Jésù máa lo agbára tí Ọlọ́run fún un yìí láti jí àwọn òkú dìde, bó ṣe jí Lásárù dìde.

Léraléra ni Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe láti jí àwọn òkú dìde. Bí àpẹẹrẹ, áńgẹ́lì kan fi dá wòlíì Dáníẹ́lì lójú pé: “Ìwọ yóò sì sinmi, ṣùgbọ́n ìwọ yóò dìde fún ìpín rẹ ní òpin àwọn ọjọ́.” (Dáníẹ́lì 12:13) Jésù sọ fún àwọn Sadusí, ìyẹn àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù tí kò nígbàgbọ́ nínú àjíǹde pé: “Ẹ ṣàṣìṣe, nítorí ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ tàbí agbára Ọlọ́run.” (Mátíù 22:23, 29) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ní ìrètí sọ́dọ̀ Ọlọ́run, . . . pé àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—Ìṣe 24:15.

ÌGBÀ WO NI ÀWỌN ÒKÚ MÁA JÍǸDE?

Ìgbà wo gan-an ni àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yìí máa wáyé? Rántí pé áńgẹ́lì yẹn sọ fún wòlíì Dáníẹ́lì tó jẹ́ olódodo pé yóò dìde “ní òpin àwọn ọjọ́.” Màtá tó jẹ́ àbúrò Lásárù náà gbà pé ẹ̀gbọ́n òun máa “dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.”—Jòhánù 11:24.

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “Ọjọ́ ìkẹyìn” yìí àti ìṣàkóso Ìjọba Kristi wọnú ara wọn. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Nítorí òun [Kristi] gbọ́dọ̀ ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí Ọlọ́run yóò fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Ọ̀tá ìkẹyìn náà, ikú, ni a ó sọ di asán.” (1 Kọ́ríńtì 15:25, 26) Ìdí pàtàkì rèé tó fi yẹ ká máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, kí ìfẹ́ Ọlọ́run sì ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé. *

Ó dá Jóòbù lójú pé, ìfẹ́ inú Ọlọ́run ni láti jí àwọn òkú dìde. Nígbà tí ọjọ́ yẹn bá dé, ikú á di ohun asán. Kò tún ní sí ẹnì táá ṣe kàyéfì mọ́ pé, ‘Ǹjẹ́ Ikú ni òpin ìgbésí ayé ẹ̀dá?’

^ ìpínrọ̀ 8 Ọ̀rọ̀ náà, “itẹ́ òkú” wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “ilé oorun.”

^ ìpínrọ̀ 18 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa Ìjọba Ọlọ́run, ka orí 8 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é. Ó tún wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo.