Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Nǹkan Tó Rọ̀ Mọ́ Mímọ Orúkọ Ọlọ́run

Àwọn Nǹkan Tó Rọ̀ Mọ́ Mímọ Orúkọ Ọlọ́run

Àwọn Nǹkan Tó Rọ̀ Mọ́ Mímọ Orúkọ Ọlọ́run

ǸJẸ́ orúkọ rẹ ní ìtumọ̀ pàtó kan? Láwọn apá ibì kan láyé, àṣà àwọn kan ni láti máa fún àwọn ọmọ wọn lórúkọ tó nítumọ̀ tó kún rẹ́rẹ́. Àwọn orúkọ bẹ́ẹ̀ lè fi ìgbàgbọ́ àti ohun tí àwọn òbí náà kà sí pàtàkì hàn tàbí ohun tí wọ́n ń fẹ́ kí ọmọ wọn dà lọ́jọ́ iwájú.

Àṣà fífúnni lórúkọ tó nítumọ̀ kì í ṣe tuntun. Lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, wọ́n sábà máa ń fún àwọn èèyàn lórúkọ nítorí ìtumọ̀ táwọn orúkọ náà ní. Orúkọ lè jẹ́ ká mọ ohun tí wọ́n retí pé kí ẹnì kan gbé ṣe lọ́jọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà ń sọ fún Dáfídì nípa ohun tí Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ máa ṣe lọ́jọ́ iwájú, Ó sọ pé: “Sólómọ́nì [tó túmọ̀ sí Àlàáfíà] ni orúkọ rẹ̀ yóò jẹ́, àlàáfíà àti ìdákẹ́jẹ́ẹ́ ni èmi yóò sì fi jíǹkí Ísírẹ́lì ní àwọn ọjọ́ rẹ̀.”—1 Kíróníkà 22:9.

Láwọn àkókò kan, Jèhófà fún àwọn èèyàn tó máa kó ipa pàtàkì kan ní orúkọ tuntun kan. Ó fún ìyàwó Ábúráhámù tó yàgàn ní orúkọ náà, Sárà, èyí tó túmọ̀ sí “Ìyá Ọba.” Kí nìdí? Jèhófà ṣàlàyé pé: “Èmi yóò sì bù kún un, èmi yóò sì tún fi ọmọkùnrin kan fún ọ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀; èmi yóò sì bù kún un, òun ó sì di àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn ọba àwọn ènìyàn yóò sì wá láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 17:16) Kò sí àní-àní pé, tá a bá lóye ìdí tí Ọlọ́run fi fún Sárà lórúkọ tuntun yìí, ìyẹn máa jẹ́ ká mọ ipa pàtàkì tó máa kó.

Jèhófà tó jẹ́ orúkọ tó ju gbogbo orúkọ lọ ńkọ́? Kí ló túmọ̀ sí? Nígbà tí Mósè béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run nípa orúkọ yẹn, Jèhófà Ọlọ́run dá a lóhùn pé: “Èmi yóò jẹ́ ohun tí èmi yóò jẹ́.” (Ẹ́kísódù 3:14) Bíbélì Rotherham túmọ̀ ẹsẹ yìí sí: “Èmi yóò di ohunkóhun tó bá wù mí.” Orúkọ náà, Jèhófà, fi hàn pé ó jẹ́ Ọlọ́run tó ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan. Àkàwé kan tó lè jẹ́ ká lóye ọ̀rọ̀ náà rèé: Ó lè pọn dandan fún ìyá kan láti máa ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ lójoojúmọ́ nítorí kó lè bójú tó àwọn ọmọ rẹ̀, ó lè jẹ́ nọ́ọ̀sì, alásè, olùkọ́, ìyẹn sì sinmi lórí ohun tí ìyá náà fẹ́ ṣe fún wọn. Bí ọ̀rọ̀ Jèhófà náà ṣe rí nìyẹn, àmọ́ lọ́nà tí kò lẹ́gbẹ́. Kó bàa lè ṣe ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé, ó lè di ohunkóhun tó bá wù ú, kó lè ṣe ohunkóhun tó yẹ. Torí náà, mímọ ẹni tí Jèhófà jẹ́ rọ̀ mọ́ lílóye ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń ṣe, kéèyàn sì mọrírì wọn.

Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn tí kò mọ orúkọ Ọlọ́run kò lè mọ àwọn ànímọ́ rẹ̀ tó fani mọ́ra. Àmọ́ ṣá o, kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa jẹ́ kéèyàn mọrírì àwọn nǹkan tí Jèhófà ń ṣe. Díẹ̀ lára wọn ni pé, ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n Olùgbani-nímọ̀ràn, Olùgbàlà tó lágbára àti Olùpèsè tó jẹ́ ọ̀làwọ́. Àgbàyanu ni ìtumọ̀ orúkọ náà, Jèhófà, ìtumọ̀ rẹ̀ sì kún rẹ́rẹ́.

Àmọ́ ṣá o, kì í fi gbogbo ìgbà rọrùn láti mọ orúkọ Ọlọ́run. Àpilẹ̀kọ tó kàn máa jẹ́ ká mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.