Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìsìn Tòótọ́ Ń Kọ́ni Láti Máa Bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ìsìn Tòótọ́ Ń Kọ́ni Láti Máa Bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ìsìn Tòótọ́ Ń Kọ́ni Láti Máa Bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

JÉSÙ fi hàn pé ó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún Bíbélì tó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èyí hàn nínú bó ṣe fèsì nígbà tí Èṣù ń dẹ ẹ́ wò. (Mátíù 4:4-11) Bí àpẹẹrẹ, báwo ni Jésù ṣe fèsì nígbà tí Sátánì sọ fún un pé kó sọ òkúta di búrẹ́dì? Jésù kọ̀ jálẹ̀ láti ṣohun tí Sátánì ní kó ṣe yìí nípa fífa ọ̀rọ̀ yọ látinú ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí Mósè láti kọ, o lè ka ọ̀rọ̀ yìí nínú ìwé Diutarónómì 8:3. Nígbà tí Èṣù sì ní òun máa fún Jésù ní ìṣàkóso gbogbo ilẹ̀ ayé tí Jésù bá ṣáà lè jọ́sìn òun lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, kí ni Jésù fi dá a lóhùn? Ó kọ̀ jálẹ̀ nípa títọ́ka sí ìlànà Ìwé Mímọ́ nínú ìwé Diutarónómì 6:13.

Àbó ò rí nǹkan! Pẹ̀lú pé Jésù jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, síbẹ̀ Bíbélì ló gbára lé gẹ́gẹ́ bí ọlá àṣẹ nígbà tó bá ń kọ́ni. Ó sì dájú pé kò fìgbà kankan pa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tì torí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn èèyàn. (Jòhánù 7:16-18) Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ìsìn nígbà ayé Jésù ni kò nírú ọ̀wọ̀ tí Jésù ní fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yìí. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n ti jẹ́ kí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn èèyàn ṣe pàtàkì sí wọn ju Ìwé Mímọ́ Ọlọ́wọ̀ lọ. Jésù ò fọ̀rọ̀ bò fáwọn aṣáájú ìsìn yẹn, ó ní: ‘Ẹ́ fi àṣà ìbílẹ̀ yín yí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run po. Ẹ̀yin àgàbàgebè! Òtítọ́ ni Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa yín nígbà tí ó wí pé: ‘Ọlọ́run sọ pé ẹnu lásán ni àwọn ènìyàn yìí fi ń bọlá fún mi, ọkàn wọn jìnnà púpọ̀ sí mi. Asán ni sísìn tí wọ́n ń sìn mí, ìlànà ènìyàn ni wọ́n fi ń kọ́ni bí òfin Ọlọ́run.’’—Mátíù 15:6-9, Ìròhìn Ayọ̀.

Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìsìn tó wà láyé, ìyẹn àwọn ìsìn Kristẹni àtàwọn tí kò jẹ mọ́ ìsìn Kristẹni, ló máa ń fẹnu lásán sọ pé àwọ́n bọ̀wọ̀ fún Bíbélì. Àmọ́, ẹ̀sìn mélòó lo mọ̀ tó máa pa àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ kan tì, torí pé ó ta ko àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan tó ṣe kedere? Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ méjì péré yẹ̀ wò.

ÀKÒRÍ: Àwọn orúkọ oyè tí wọ́n máa ń lò nínú ìsìn.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ́NI: Jésù bá àwọn aṣáájú ìsìn ìgbà ayé rẹ̀ wí torí bí wọ́n ṣe fẹ́ràn àwọn orúkọ oyè àti bí ipò ọlá ṣe máa ń gbà wọ́n lọ́kàn. Ó sọ pé àwọn ọkùnrin yìí fẹ́ràn ‘ipò ọlá ní ibi àsè àti ibùjókòó ọlá ní sínágọ́gù àti ìkíni ní ọjà àti káwọn ènìyàn lè máa pè wọ́n ní ‘Rábì.’ Jésù wá sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: ‘Kí á má ṣe pe ẹ̀yin ní Rábì, nítorí ẹnì kan ni Olùkọ́ yín, ará sì ni gbogbo yín. Ẹ má sì ṣe pe ẹnìkan ní baba yín ní ayé, nítorí ẹnìkan ni Baba yín, ẹni tí ń bẹ ní ọ̀run.’—Mátíù 23:1-10, Bibeli Yoruba Atọ́ka.

ÌBÉÈRÈ: Ṣáwọn aṣáájú ìsìn tó o mọ̀ yìí máa ń ní káwọn èèyàn máa fàwọn orúkọ oyè tó ń buyì kúnni pe àwọn, tí wọ́n sì máa ń wá ipò ọlá láàárín ìlú, àbí wọ́n ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù tó sọ pé kéèyàn ṣọ́ra fún irú nǹkan bẹ́ẹ̀?

ÀKÒRÍ: Lílo ère nínú ìjọsìn.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ́NI: ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ yá ère fún ara rẹ tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ lókè ọ̀run tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ tàbí ti ohun kan ti ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ sìn wọ́n.’—Ẹ́kísódù 20:4, 5, Bibeli Mimọ.

Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé sáwọn Kristẹni, ó ní: “Ẹ gbọ́dọ̀ ta kété sí ìbọ̀ríṣà.”—1 Jòhánù 5:21, ìtúmọ̀ Contemporary English Version.

ÌBÉÈRÈ: Ṣé ìsìn tó o mọ̀ yìí ń ṣègbọràn sí àṣẹ Bíbélì tó ṣe kedere pé ká ṣọ́ra fún lílo ère àti òrìṣà nínú ìjọsìn Ọlọ́run?

O Lè Rí Ìsìn Tòótọ́

Láìka àìmọye ìsìn èké tí ẹ̀kọ́ wọn ń ṣini lọ́nà tó wà lóde òní sí, o lè rí ìsìn tó máa jẹ́ kó o ní ìyè. Àwọn àmì tó o fi lè mọ “ìsìn tó mọ́, tó sì jẹ́ aláìléèérí níwájú Ọlọ́run” pọ̀ lọ jàńtìrẹrẹ. (Jákọ́bù 1:27, ìtúmọ̀ New Revised Standard Version) Àwọn Ìwé Mímọ́ tá a jíròrò nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí dà bí atọ́ka tó máa jẹ́ kó o mọ ìsìn náà.

O ò ṣe ní káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣàlàyé ìdáhùn tiwọn sáwọn ìbéèrè tó wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí fún ẹ. Bó o ṣe ń ronú lórí ohun tí wọ́n sọ, tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere àwọn tó gbé láyé ní ọ̀rúndún kìíní nílùú Bèróà. Lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ìwàásù àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tán, “wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ kí wọ́n lè mọ̀ bóyá òótọ́ ni ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ.” (Ìṣe 17:11, ìtúmọ̀ Today’s English Version) Bíi tàwọn ará Bèróà, tó o bá bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó o sì fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, wàá mọ ìsìn tòótọ́. Ó wá kù sọ́wọ́ ẹ láti pinnu bóyá wàá ṣe ìsìn tòótọ́ àbí o ò ní ṣe é.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

Ìsìn wo ló máa ń gba àwọn èèyàn níyànjú pé kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ kí wọ́n lè rí i bóyá òótọ́ lohun tí wọ́n ń kọ́?