Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Jésù Ni Ọlọ́run?

Ṣé Jésù Ni Ọlọ́run?

Ṣé Jésù Ni Ọlọ́run?

Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló gbà pé ‘òpómúléró lára ẹ̀kọ́ Kristẹni’ ni ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan. Àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ Mẹ́talọ́kan gbà gbọ́ pé Baba, Ọmọ àti ẹ̀mí mímọ́ ló para pọ̀ jẹ́ Ọlọ́run kan. Ọ̀gbẹ́ni John O’Connor tó jẹ́ Kádínà nínú ìsìn Kátólíìkì sọ nípa ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan pé: “A mọ̀ pé àdììtú ni ẹ̀kọ́ yìí, a ò sì mọ ojútùú ẹ̀.” Kí nìdí tí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan fi ṣòroó lóye tó bẹ́ẹ̀?

Ìwé atúmọ̀ èdè kan tó ń jẹ́ The Illustrated Bible Dictionary sọ ìdí kan tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀. Ìwé yìí sọ nípa ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan pé: “Kì í ṣe ẹ̀kọ́ Bíbélì torí pé kò sí ẹsẹ kankan nínú Ìwé Mímọ́ tó ṣàlàyé nípa rẹ̀.” Torí pé ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan “kì í ṣe ẹ̀kọ́ Bíbélì,” àwọn tó nígbàgbọ́ nínú ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ti ń wá gbogbo ọ̀nà tí wọ́n á fi ráwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n máa fi ti ẹ̀kọ́ yìí lẹ́yìn, kódà wọ́n ṣe tán láti yí ìtumọ̀ àwọn ẹsẹ Bíbélì kan po kó lè dà bíi pé wọ́n ti ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan lẹ́yìn.

Ṣé Ẹsẹ Bíbélì Tó Ti Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan Lẹ́yìn Wà Lóòótọ́?

Ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n sábà máa ń ṣì lóye ni Jòhánù 1:1. Nínú Bíbélì Mímọ́, ẹsẹ yẹn kà pé: ‘Ní àtètèkọ́ṣe ni Ọ̀rọ̀ wà, Ọ̀rọ̀ sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run [lédè Gíríìkì, ton the·onʹ], Ọlọ́run [the·osʹ] sì ni Ọ̀rọ̀ náà.’ Nínú ẹsẹ yìí, ọ̀nà méjì ni wọ́n gbà kọ the·osʹ tó jẹ́ ọ̀rọ̀ orúkọ kan lédè Gíríìkì, ọlọ́run ló sì túmọ̀ sí. Ọ̀nà àkọ́kọ́ ni the·onʹton, tí wọ́n fi ń ṣàpèjúwe àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtó lédè Gíríìkì, máa ń wà ṣáájú ẹ̀, ìyẹn ló sì jẹ́ kí the·onʹ túmọ̀ sí Ọlọ́run Olódùmarè. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń ṣàpèjúwe àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtó lédè Gíríìkì ò ṣáájú the·osʹ tó jẹ́ ọ̀nà kejì. Ṣó wá lè jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n gbàgbé láti fi ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń ṣàpèjúwe àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtó lédè Gíríìkì ṣáájú ọ̀nà kejì ni?

Ẹ̀ka èdè Gíríìkì tí wọ́n ń pè ní Koine ni wọ́n fi kọ Ìwé Ìhìn Rere Jòhánù, èdè yìí sì láwọn òfin tó de bí wọ́n ṣe gbọ́dọ̀ máa lo àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń ṣàpèjúwe àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtó. Ọ̀mọ̀wé A. T. Robertson tó máa ń ṣèwádìí Bíbélì ti rí i pé tí gbólóhùn tó ń pọ́n ọ̀rọ̀ orúkọ àti ọ̀rọ̀ orúkọ fúnra ẹ̀ bá ní ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń ṣàpèjúwe àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtó, a jẹ́ pé “ọ̀rọ̀ orúkọ tó ṣe pàtó làwọn méjèèjì nìyẹn, wọ́n bára mu, a sì lè fi wọ́n rọ́pò ara wọn.” Ọ̀gbẹ́ni Robertson fi ìwé Mátíù 13:38 ṣàpẹẹrẹ, ó kà pé: “Pápá náà [ho a·grosʹ lédè Gíríìkì] ni ayé [ho koʹsmos lédè Gíríìkì].” Àlàyé tí Ọ̀gbẹ́ni Robertson ṣe ti jẹ́ ká mọ̀ pé ayé ni pápá náà.

Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé, bó ṣe wà nínú Jòhánù 1:1, ọ̀rọ̀ orúkọ nìkan ló ní ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń ṣàpèjúwe àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtó àmọ́ tí gbólóhùn tó ń pọ́n ọn ò ní in? Ọ̀mọ̀wé James Allen Hewett fi ẹsẹ Bíbélì yẹn kan náà ṣàpẹẹrẹ, ó ní: “Gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ yẹn ṣe kà, gbólóhùn tá a fi pọ́n ọ̀rọ̀ orúkọ yẹn kì í ṣe nǹkan kan náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ orúkọ tó wà nínú gbólóhùn yẹn, wọn ò bára mu, a ò sì lè fi wọ́n rọ́pò ara wọn.”

Ọ̀gbẹ́ni Hewett fi 1 Jòhánù 1:5 ṣe àpèjúwe, ẹsẹ yẹn kà pé: “Ọlọ́run [ho the·osʹ] jẹ́ ìmọ́lẹ̀ [phos].” Nínú ẹsẹ Bíbélì yìí lédè Gíríìkì, ho the·osʹ túmọ̀ sí “Ọlọ́run,” ìdí sì ni pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń ṣàpèjúwe àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtó wà ṣáájú ẹ̀. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń ṣàpèjúwe àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtó ò ṣáájú phos tó túmọ̀ sí “ìmọ́lẹ̀.” Ọ̀gbẹ́ni Hewett sọ pé: “A lè sọ pé . . . Ọlọ́run ń gbénú ìmọ́lẹ̀, àmọ́ a ò lè sọ pé ìmọ́lẹ̀ ń gbénú Ọlọ́run.” Àwọn àpẹẹrẹ míì wà nínú Jòhánù 4:24, ó ní: “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí” àti 1 Jòhánù 4:16, ó ní: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” Nínú ẹsẹ Bíbélì méjèèjì wọ̀nyí, àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ tó wà níbẹ̀ ní ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń ṣàpèjúwe àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtó lédè Gíríìkì, àmọ́, àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi pọ́n wọn, ìyẹn “Ẹ̀mí” àti “ìfẹ́” ò ní. Torí náà, a ò lè fàwọn ọ̀rọ̀ orúkọ àtàwọn ọ̀rọ̀ tó ń pọ́n wọn rọ́pò ara wọn nínú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí. Àwọn ẹsẹ yìí ò nìtúmọ̀ lédè Gíríìkì bí wọ́n bá sọ pé “Ẹ̀mí ni Ọlọ́run” tàbí “ìfẹ́ ni Ọlọ́run.”

Bá A Ṣe Lè Dá “Ọ̀rọ̀ Náà” Mọ̀

Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọ̀mọ̀wé ilẹ̀ Gíríìsì àtàwọn tó túmọ̀ Bíbélì gbà pé ànímọ́ pàtàkì kan nípa “Ọ̀rọ̀ náà” ni Jòhánù 1:1 ń sọ kì í ṣe bá a ṣe máa dá a mọ̀. Ọ̀gbẹ́ni William Barclay tó jẹ́ atúmọ̀ Bíbélì sọ pé: “Nítorí pé [àpọ́sítélì Jòhánù] ò fi ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń ṣàpèjúwe àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtó lédè Gíríìkì síwájú theos, ó fi hàn pé ó fi ń ṣàpèjúwe ni . . . Jòhánù ò sọ pé Ọ̀rọ̀ náà ni Ọlọ́run Olódùmarè. Ká kúkú sọ ọ́ lọ́nà tó rọrùn, Jòhánù ò sọ pé Jésù ni Ọlọ́run.” Ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ Jason David BeDuhn náà sọ pé: “Lédè Gíríìkì, téèyàn ò bá fi ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń ṣàpèjúwe àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtó ṣáájú theos, bí irú èyí tó wà nínú Jòhánù 1:1d, àwọn tó ń kà á máa gbà pé ‘ọlọ́run kan’ lẹni náà ní lọ́kàn. . . . Àmọ́, bí ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń ṣàpèjúwe àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtó lédè Gíríìkì ò ṣe wà ṣáájú theos ló jẹ́ kó yàtọ̀ pátápátá sí ho theos tó ní ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń ṣàpèjúwe àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtó lédè Gíríìkì, irú ìyàtọ̀ yìí ló sì wà láàárín ‘ọlọ́run kan’ àti ‘Ọlọ́run’ lédè Gẹ̀ẹ́sì.” Bó sì ṣe rí lédè Yorùbá náà nìyẹn. Ọ̀gbẹ́ni BeDuhn ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ pé: “Ọ̀rọ̀ náà tó wà nínú Jòhánù 1:1 kì í ṣe Ọlọ́run Olódùmarè, àmọ́ ó jẹ́ ọlọ́run kan tàbí ẹ̀dá ẹ̀mí kan.” A sì lè sọ ọ́ bí ọ̀mọ̀wé Joseph Henry Thayer tó wà lára àwọn tó túmọ̀ Bíbélì American Standard Version ṣe sọ ọ́, ó ní: “Ọ̀run ni Logos [tàbí Ọ̀rọ̀ náà] ti wá, àmọ́ òun kọ́ ni Olú Ọ̀run.”

Ṣó wá yẹ kọ́rọ̀ àtimọ Ọlọ́run jẹ́ “àdììtú”? Rárá o, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ fún Jésù. Nínú àdúrà tí Jésù gbà sí Bàbá rẹ̀, ó jẹ́ kó ṣe kedere pé ìyàtọ̀ wà láàárín òun àti Bàbá òun, ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Tá a bá gba Jésù gbọ́, tá a sì lóye ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ṣe kedere yìí, a máa bọ̀wọ̀ fún un torí pó jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run. A sì tún máa jọ́sìn Jèhófà torí pé òun ni “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]

Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé ìyàtọ̀ wà láàárín òun àti Bàbá òun

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]

Kí nìdí tí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan fi ṣòroó lóye tó bẹ́ẹ̀?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]

Ṣọ́ọ̀ṣì tó wà nílùú Tagnon, lórílẹ̀-èdè Faransé