Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọwọ́ Ẹ Ló Kù Sí

Ọwọ́ Ẹ Ló Kù Sí

Ọwọ́ Ẹ Ló Kù Sí

“Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a; akọ àti abo ni ó dá wọn.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:27.

ÀWỌN ọ̀rọ̀ tọ́pọ̀ èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó yìí, tó wà nínú ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run “ti ṣe rèterète ní ìgbà tirẹ̀,” ìyẹn dídá tó dá Ádámù àti Éfà, tọkọtaya àkọ́kọ́ lẹ́ni pípé. (Oníwàásù 3:11) Torí pé Jèhófà Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá wọn, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.

Àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ló fi jẹ́ káwọn tọkọtaya àkọ́kọ́ mohun tó ní lọ́kàn láti ṣe. Ó ní kí wọ́n máa bí sí i, kí wọ́n sì bójú tó ilẹ̀ ayé, ó fẹ́ kí wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ sọ gbogbo ayé yìí di Párádísè táwọn àtàwọn ọmọ wọn á máa gbé. Ọlọ́run ò kádàrá pé ìgbà kankan wà tí wọ́n fi máa wà láàyè kò sì kádàrá ikú mọ́ wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ ló ṣèlérí fún wọn. Tí wọ́n bá ṣèpinnu tó tọ́ tí wọ́n sì ń ṣèfẹ́ Ọlọ́run, wọ́n á ní àlááfíà àti ayọ̀ ayérayé.

Àmọ́, ìpinnu tí wọ́n ṣe burú jáì, ìyẹn ló sì fà á táwa èèyàn fi ń darúgbó, tá a sì ń kú. Jóòbù, tó jẹ́ baba ńlá pàápàá sọ pé: “Ènìyàn, tí obìnrin bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, ó sì kún fún ṣìbáṣìbo.” (Jóòbù 14:1) Kí nìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀?

Bíbélì ṣàlàyé pé: “Ìdí nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Ádámù ni “ènìyàn kan” tó mọ̀ọ́mọ̀ tàpá sófin tó rọrùn tó sì ṣe kedere tí Ọlọ́run fún wọn yẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Ohun tí Ádámù ṣe yẹn ni ò jẹ́ kó láǹfààní láti gbé títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Kò tún jẹ́ káwọn àtọmọdọ́mọ ẹ̀ láǹfààní tó ṣeyebíye yìí, dípò ìyẹn, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ló fi sílẹ̀ fún wọn láti jogún. Ó wá dà bíi pé kò sọ́nà àbáyọ mọ́. Ṣáwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù ṣì lè rọ́nà gbé e gbà báyìí?

Ìgbà Ọ̀tun Ń Bọ̀!

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn ni Ọlọ́run mí sí ọ̀kan lára àwọn tó kọ Sáàmù láti kọ̀wé pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) Ọlọ́run fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé, ìlérí tóun ṣe nínú ọgbà Édẹ́nì máa ṣẹ dandan, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ ká mohun tó má ṣe láìpẹ́, ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, ó ní: “Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” Ọlọ́run fúnra rẹ̀ wá fi kún un pé: “Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.”—Ìṣípayá 21:4, 5.

Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé ohun gbogbo làkókò wà fún, ìbéèrè kan tó wá yẹ ká bi ara wa ni pé, Ìgbà wo gan-an nìgbà ọ̀tun tá à ń wí yìí máa dé táwọn ìlérí àgbàyanu Ọlọ́run wọ̀nyí sì máa ṣẹ? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a ṣe ìwé ìròyìn yìí ti ń sọ fáwọn èèyàn pé àsìkò tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí àti pé àsìkò tí Ọlọ́run máa “sọ ohun gbogbo di tuntun” ti dé tán. (2 Tímótì 3:1) A gbà ẹ́ níyànjú láti ka Bíbélì, kó o sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìlérí àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣe tíwọ náà lè jàǹfààní nínú rẹ̀. A tún rọ̀ ẹ́ pé kíwọ náà ṣe ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ, ó ní: “Ẹ wá Jèhófà, nígbà tí ẹ lè rí i. Ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.” (Aísáyà 55:6) Kádàrá kọ́ ló ń darí ìgbésí ayé ẹ o, ọwọ́ ẹ ló kù sí láti ṣohun tó máa jẹ́ kí ìgbésí ayé ẹ dùn bí oyin tó sì máa jẹ́ kó o lè wà láàyè títí láé!

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

“Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun”