Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣòótọ́ Ni Ọlọ́run Máa Ń Pa Àwọn Ọmọdé Kó Lè Sọ Wọ́n Di Áńgẹ́lì Lọ́run?

Ṣòótọ́ Ni Ọlọ́run Máa Ń Pa Àwọn Ọmọdé Kó Lè Sọ Wọ́n Di Áńgẹ́lì Lọ́run?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé

Ṣòótọ́ Ni Ọlọ́run Máa Ń Pa Àwọn Ọmọdé Kó Lè Sọ Wọ́n Di Áńgẹ́lì Lọ́run?

Nígbà tí ọmọ kan bá kú, àwọn ọ̀rẹ́ ìdílé tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà lè máa tù wọ́n nínú nípa sísọ pé, “Ọlọ́run nílò áńgẹ́lì míì lọ́rùn.” Ṣọ́rọ̀ yìí mọ́gbọ́n dání lójú ẹ?

Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run máa ń pa àwọn ọmọdé torí pé ó nílò àwọn áńgẹ́lì púpọ̀ sí i lọ́run lóòótọ́, á jẹ́ pé kò lójú àánú nìyẹn, ìkà sì ni pẹ̀lú. Àmọ́, ohun tí Bíbélì sọ yàtọ̀ síyẹn. (Jóòbù 34:10) Ọlọ́run tó jẹ́ Bàbá aláàánú ò ní ṣàdédé gba ọmọ kan kúrò lọ́wọ́ àwọn òbí ẹ̀ torí pó kàn fẹ́ kí ìdílé tiẹ̀ pọ̀ sí i. Tí kò bá sí bàbá kankan tó máa ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé Jèhófà ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ nìyẹn, torí pé kò sí òbí kankan tó lójú àánú ju Jèhófà lọ, kódà ìfẹ́ ló ta yọ jù lọ lára àwọn ànímọ́ Jèhófà. (1 Jòhánù 4:8) Ojúlówó ìfẹ́ tó ní sáwa èèyàn ò ní jẹ́ kó hu irú ìwà òǹrorò yẹn.

Bi ara ẹ pé, ‘Ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run nílò àwọn áńgẹ́lì púpọ̀ sí i lọ́run?’ Bíbélì sọ pé gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run ló dára tó sì pé pérépéré. (Diutarónómì 32:4) Òun fúnra ẹ̀ ló dá ọ̀kẹ́ àìmọye áńgẹ́lì sọ́run, wọ́n pọ̀ tó bó ṣe fẹ́, wọ́n sì pé pérépéré. (Dáníẹ́lì 7:10) Ṣó wá lè jẹ́ pé Ọlọ́run ṣàṣìṣe nínú iye àwọn áńgẹ́lì tó nílò ni? Ká má rí i! Ó dájú pé Ọlọ́run Olódùmarè ò lè ṣerú àṣìṣe bẹ́ẹ̀. Òótọ́ ni pé Ọlọ́run ti yan àwọn èèyàn kan láti di ẹ̀dá ẹ̀mí kí wọ́n lè jọba pẹ̀lú Jésù Kristi lọ́run, àmọ́ wọn ò ní jẹ́ ọmọdé lásìkò tí wọ́n bá máa kú.—Ìṣípayá 5:9, 10.

Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run ò lè mú àwọn ọmọdé láti wá di áńgẹ́lì rẹ̀ torí pé ìyẹn ò bá ìfẹ́ Ọlọ́run fáwọn ọmọdé mu. Ọlọ́run sọ fún Ádámù àti Éfà nínú ọgbà Édẹ́nì pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run làwọn ọmọdé, Ọlọ́run sì ti ṣètò pé káwọn èèyàn máa bímọ kí ìfẹ́ Ọlọ́run láti fàwọn olódodo kún ilẹ̀ ayé lè nímùúṣẹ. Kò fìgbà kan rí ní i lọ́kàn pé káwọn ọmọdé máa kú ní rèwerèwe kí wọ́n bàa lè di ẹ̀dá ẹ̀mí lọ́run. Bíbélì gan-an jẹ́rìí sí i pé “ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà” làwọn ọmọ. (Sáàmù 127:3) Ṣé Jèhófà, Ọlọ́run ìfẹ́ á wá gba ẹ̀bùn tó ti fáwọn òbí pa dà ni? Ó dájú pé kò ní ṣe bẹ́ẹ̀!

Bọ́mọ bá kú ní rèwerèwe, ó máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn, ìbànújẹ́ àti ìrora tó pọ̀ gan-an báwọn òbí. Ìrètí wo wá làwọn òbí tọ́mọ wọn ti kú ní? Bíbélì ṣèlérí pé Ọlọ́run máa jí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn òkú dìde sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Rò ó wò ná, àwọn ọmọdé tó ti kú tún máa wà pẹ̀lú àwọn èèyàn wọn, ara wọn á sì ti jí pépé nígbà yẹn. (Jòhánù 5:28, 29) Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé káwọn ọmọ dàgbà, kí wọ́n gbádùn ìgbésí ayé wọn, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àtohun tó ní lọ́kàn láti ṣe fún ilẹ̀ ayé. Torí náà, àwọn ọmọ tó ti kú kò lọ di áńgẹ́lì lọ́run, àmọ́ ìgbà ń bọ̀ tí wọ́n máa jíǹde sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Tó bá dìgbà yẹn, lọ́lá Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́, inú àwọn ọmọdé àtàgbà á túbọ̀ máa dùn láti máa jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run títí ayérayé.