Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tá A Fi Ń Lo Orúkọ Ọlọ́run Nígbà Tá Ò Mọ Bí Wọ́n Ṣe Ń Pè É?

Kí Nìdí Tá A Fi Ń Lo Orúkọ Ọlọ́run Nígbà Tá Ò Mọ Bí Wọ́n Ṣe Ń Pè É?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé

Kí Nìdí Tá A Fi Ń Lo Orúkọ Ọlọ́run Nígbà Tá Ò Mọ Bí Wọ́n Ṣe Ń Pè É?

Lóde òní, kò sẹ́ni tó mọ bí wọ́n ṣe ń pe orúkọ Ọlọ́run gan-an lédè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ó gbàfiyèsí pé orúkọ Ọlọ́run gan-an fara hàn ní nǹkan bí ìgbà ẹgbẹ̀rún méje [7,000] nínú Bíbélì. Jésù fi orúkọ Ọlọ́run hàn nígbà tó wà láyé, ó sì kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́. (Mátíù 6:9; Jòhánù 17:6) Nítorí náà, ohun kan tó dájú ni pé, ó ṣe pàtàkì gan-an pé káwọn Kristẹni máa lo orúkọ Ọlọ́run. Kí wá nìdí tó fi jẹ́ pé, lóde òní, a ò lè sọ pé báyìí ni wọ́n ṣe ń pe orúkọ Ọlọ́run ní ìpilẹ̀ṣẹ̀? Ìdí pàtàkì méjì wà tó fi rí bẹ́ẹ̀.

Àkọ́kọ́, ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ọdún sẹ́yìn, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í dáṣà kan, wọ́n ní ó lòdì láti máa pe Ọlọ́run lórúkọ. Àṣà wọn yìí ló mú kó di pé, tí òǹkàwé kan bá ti pàdé orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì, “Olúwa” ló máa pè dípò rẹ̀. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ bó ṣe di pé àwọn èèyàn gbàgbé bí wọ́n ṣe ń pe orúkọ Ọlọ́run nìyẹn, torí pé wọn ò lo orúkọ yẹn mọ́ fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún.

Ìkejì, wọn kì í fi fáwẹ̀lì sáàárín ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n ń kọ sílẹ̀ látijọ́. Tí ẹnì kan bá ń kàwé, fúnra rẹ̀ ló máa fi fáwẹ̀lì tó yẹ sáàárín àwọn ọ̀rọ̀ tó ń kà. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n wá dọ́gbọ́n kan tí kò ní jẹ́ kí wọ́n gbàgbé bí wọ́n ṣe ń pe àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù pátápátá. Wọ́n ń fi àmì fáwẹ̀lì ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan sáàárín ibi tó yẹ kó wà nínú Bíbélì tí wọ́n kọ lédè Hébérù. Àmọ́ ní ti orúkọ Ọlọ́run, ńṣe ni wọ́n ń fi àwọn àmì fáwẹ̀lì tó máa rán ẹni tó ń kàwé létí pé kó pe “Olúwa” níbẹ̀ dípò orúkọ Ọlọ́run, tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ fi àmì fáwẹ̀lì kankan sí i.

Fún ìdí yìí, kìkì ohun táwọn èèyàn ń rí nínú àkọsílẹ̀ ni kọ́ńsónáǹtì Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run. Ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé kọ́ńsónáǹtì Hébérù mẹ́rin yẹn túmọ̀ sí “lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tí wọ́n sábà máa ń kọ báyìí YHWH tàbí JHVH, èyí tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run gan-an nínú Bíbélì.” Èyí jẹ́ ká tètè rí ìdí tí JHVH tí wọ́n fi fáwẹ̀lì sí ṣe di èyí tá à ń pè ní “Jèhófà” lédè Yorùbá.

Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan dábàá pé “Yáwè” ni kí wọ́n máa pe orúkọ Ọlọ́run. Ṣé ìyẹn ló wá sún mọ́ bí wọ́n ṣe ń pè é ní ìpilẹ̀ṣẹ̀? Kò sẹ́ni tó lè sọ. Ńṣe làwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ míì tiẹ̀ tún ṣàlàyé ìdí táwọn kò fi lo “Yáwè.” Ohun kan tá a mọ̀ ni pé, báwọn èèyàn ṣe ń pe àwọn orúkọ inú Bíbélì lóde òní yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe ń pè é lédè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀, àwọn èèyàn kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ jiyàn. Ìdí ni pé, a ti ń pe àwọn orúkọ yìí bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ lédè tiwa, ó sì máa ń yé wa. Bẹ́ẹ̀ náà ni orúkọ náà Jèhófà ṣe rí.

Bíbélì pe àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní àwọn ènìyàn kan fún orúkọ Ọlọ́run. Wọ́n ń wàásù nípa orúkọ Jèhófà fáwọn èèyàn, wọ́n sì ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa ké pe orúkọ yẹn. (Ìṣe 2:21; 15:14; Róòmù 10:13-15) Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run fẹ́ ká máa lo orúkọ òun láìkà èdè yòówù ká máa sọ sí, ká mọyì orúkọ yẹn, ká sì máa gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tí kò ní tàbùkù sórúkọ náà.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 31]

Ó gbàfiyèsí pé orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gan-an fara hàn ní nǹkan bí ìgbà ẹgbẹ̀rún méje [7,000] nínú Bíbélì