Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Má Ṣe Gbàgbé Iṣẹ́ Ìwàásù Ilé-dé-Ilé”

“Má Ṣe Gbàgbé Iṣẹ́ Ìwàásù Ilé-dé-Ilé”

“Má Ṣe Gbàgbé Iṣẹ́ Ìwàásù Ilé-dé-Ilé”

Gẹ́gẹ́ bí Jacob Neufeld ṣe sọ ọ́

“Ohun yòówù tí ì báà ṣẹlẹ̀, má ṣe gbàgbé iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé.” Gbólóhùn yìí ń ró gbọnmọgbọnmọ létí mi bí mo ṣe ń rin ìrìn nǹkan bíi kìlómítà márùn-ún lọ sí abúlé tó sún mọ́ wa jù lọ. Nígbà tí mo débẹ̀, ìbẹ̀rù ò jẹ́ kí n lè wọ ilé àkọ́kọ́. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ akitiyan, mo lọ sínú igbó, mo sì gbàdúrà kíkankíkan sí Ọlọ́run pé kó fún mi ní ìgboyà láti wàásù. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, mo nígboyà láti padà sẹ́nu ọ̀nà ilé àkọ́kọ́, mo sì wàásù fún wọn.

KÍ LÓ gbé mi dé abúlé yẹn tó wà láṣálẹ̀ lórílẹ̀-èdè Paraguay níbi tí mo ti ń gbìyànjú láti wàásù lémi nìkan? Ẹ jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀. Orílẹ̀-èdè Ukraine ni wọ́n bí mi sí ní oṣù November, ọdún 1923 lábúlé Kronstalʹ táwọn ẹlẹ́sìn Menno ti ilẹ̀ Jámánì fi ṣe ibùgbé. Ọdún bíi mélòó kan ṣáájú ọdún 1800 làwọn ẹlẹ́sìn Menno ṣí lọ sórílẹ̀-èdè Ukraine láti orílẹ̀-èdè Jámánì. Wọ́n sì fún wọn láwọn àǹfààní kan, bí òmìnira ìsìn (ṣùgbọ́n wọn kò fún wọn láyè láti wàásù fáwọn èèyàn pé kí wọ́n wá dara pọ̀ mọ́ wọn), wọ́n lè ṣe ìjọba tiwọn láàárín ara wọn, wọn kì í sì í ṣiṣẹ́ ológun.

Àmọ́, nígbà tí Ẹgbẹ́ Òṣèlú Kọ́múníìsì dé orí àlééfà, gbogbo àǹfààní yẹn ni wọ́n gbà lọ́wọ́ wọn. Ní nǹkan bí ọdún mélòó kan ṣáájú ọdún 1930, ìjọba bẹ̀rẹ̀ sí í darí àwọn oko tó lọ bí ilẹ̀ bí ẹní tó jẹ́ tàwọn ẹlẹ́sìn Menno, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn oníǹkan náà ló ṣì ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Wọ́n febi pa àwọn èèyàn náà títí tí wọ́n fi gbà pẹ̀lú ìjọba, wọ́n sì ń fi palaba ìyà jẹ èyíkéyìí tó bá fẹ́ ṣorí kunkun. Láàárín ọdún 1930 sí 1939, àwọn ọlọ́pàá KGB, ìyẹn àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ti ìjọba Soviet, ń kó ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin. Òru sì ni wọ́n sábàá máa ń wá kó wọn, tó fi jẹ́ pé ìwọ̀nba àwọn ọkùnrin kéréje ló ṣẹ́ kù sí ọ̀pọ̀ nínú àwọn abúlé náà. Bí wọ́n ṣe gbé baba mi náà lọ nìyẹn lọ́dún 1938 nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá, mi ò fojú kàn án bẹ́ẹ̀ ni mi ò gbúròó rẹ̀ mọ́ látìgbà náà. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, wọ́n tún gbé ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin náà lọ.

Nígbà tó di ọdún 1941, orílẹ̀-èdè Ukraine bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọmọ ogún Hitler. Inú tàwa ṣì ń dùn pé a bọ́ lọ́wọ́ ìjọba Kọ́múníìsì. Àfi bí odindi ìdílé mẹ́jọ tó jẹ́ kìkì àwọn Júù tó ń gbé lábúlé wa ṣe ṣàdédé dàwátì. Gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ kí n máa bi ara mi lọ́pọ̀ ìbéèrè. Irú bíi: Kí nìdí táwọn nǹkan wọ̀nyí fi ń ṣẹlẹ̀?

Jíjẹ́ Tí Mo Jẹ́ Olóòótọ́ Kó Mi Yọ

Lọ́dún 1943, àwọn ọmọ ogun Jámánì fi orílẹ̀-èdè Ukraine sílẹ̀, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lọ lára ìdílé àwọn ọmọ ilẹ̀ Jámánì ni wọ́n kó pẹ̀lú ìdílé wọn kí wọ́n bàa lè rí àwọn ẹni tó máa tì wọ́n lẹ́yìn nínú ogun tí wọ́n ń jà. Kódà wọ́n kó àwọn ará ilé mi tó kù. Ní gbogbo àkókò yẹn, wọ́n ti fipá mú mi wọnú iṣẹ́ ológún, wọ́n sì sọ mí di ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ ilẹ̀ Jámánì (tí wọ́n ń pé ní Schutzstaffel tó ń ṣojú Hitler) ní orílẹ̀-èdè Romania. Nǹkan kékeré kan ṣẹlẹ̀ lákòókò yẹn tó di nǹkan ńlá nínú ayé mi.

Ọ̀gá tó wà ní ìsọ̀rí tí wọ́n pín mi sí fẹ́ dán mi wò kó lè mọ̀ bóyá mo jẹ́ olóòótọ́. Ó ní kí n kó aṣọ iṣẹ́ òun lọ sọ́dọ̀ ẹni tó máa ń bá wa fọṣọ. Ó ti kó owó sínú ọ̀kan lára àpò aṣọ rẹ̀, mo sì rí owó náà nígbà tí mò ń kó aṣọ náà lọ. Nígbà tí mo dá owó náà padà, ó sọ pé òun ò gbàgbé nǹkan kan sínú aṣọ náà. Àmọ́ mo ṣáà ń tẹnu mọ́ ọn pé inú àpò rẹ̀ ni mo ti rí owó náà. Kò pẹ́ sígbà yẹn, ni wọ́n fi mí jẹ igbá kejì ọ̀gá yìí, wọ́n sì ní kí n máa bójú tó iṣẹ́ ọ́fíìsì, irú bíi gbígbé àwọn ẹ̀ṣọ́ láti ibì kan sí ibòmíràn àti bíbójú tó owó tó wà fún ìsọ̀rí wa.

Lóru ọjọ́ kan, ọwọ́ àwọn ọmọ ogún orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tẹ gbogbo ẹ̀ṣọ́ tó wà ní ìsọ̀rí tiwa, àyàfi èmi nìkan, torí mo ṣì wà níbi iṣẹ́ láti parí àwọn iṣẹ́ kan tí ọ̀gá wa gbé fún mi. Débi tí mo rí i dé, èmi nìkan lọ́wọ́ wọn ò tẹ̀, ìdí ẹ̀ sì ni pé mo jẹ́ olóòótọ́ tí wọ́n sì tìtorí bẹ́ẹ̀ fún mi ní iṣẹ́ kan tó yàtọ̀. Bí ò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ọwọ́ wọn ì bá tẹ èmi náà.

Bí mo ṣe dédé gba ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ ológun nìyẹn lọ́dún 1944, tí kò sì lọ́jọ́ tí máa padà sẹ́nu iṣẹ́. Ni mo bá padà sílé láti lọ wo màmá mi. Bí mo ṣe ń dúró dìgbà tí wọ́n máa pè mí padà, mo lọ kọ́ṣẹ́ mọlémọlé, iṣẹ́ tí mo kọ́ yẹn sì padà wá wúlò gan-an nígbà tó yá. Lóṣù April ọdún 1945, àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà gba ìlú wa tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìlú Magdeburg. Oṣù kan lẹ́yìn náà ni wọ́n kéde pé ogún ti parí. A dúpẹ́ pé ẹ̀mí wa rẹ́yìn ogun. Ó sì dà bíi pé a ò tún ní rógun mọ́.

Lọ́jọ́ kan lóṣù June, a gbọ́ ìkéde kan látọ̀dọ̀ akéde ìlú, pé: “Kére o! Àwọn ọmọ ogun Amẹ́ríkà ti lọ lóru àná, àmọ́ àwọn ọmọ ogun Rọ́ṣíà máa dé ní agogo mọ́kànlá àárọ̀ yìí.” Inú wa bà jẹ́ nígbà tá a rí i pé a tún ti kó sọ́wọ́ ìjọba Kọ́múníìsì. Lójú ẹsẹ̀, èmi àti ọmọ àbúrò bàbá mi bẹ̀rẹ̀ sí í gbèrò bá a ṣe máa wábi sá gbà lọ. Kó tó di ìparí oṣù tó tẹ̀ lé e, a ti sọdá sí àgbègbè tó wà lábẹ́ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lẹ́yìn náà, lóṣù November, pẹ̀lú bó ṣe léwu tó, a tún padà wọ àgbègbè tó jẹ́ ti orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, a sì dọ́gbọ́n kó àwọn ìdílé wa kọjá ẹnubodè.

“Máa La Etí Ẹ Sílẹ̀ Dáadáa Kó O Lè Mọ Ìyàtọ̀”

Ibi tó ń jẹ́ orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn Jámánì là ń gbé nígbà yẹn. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì. Lọ́jọọjọ́ Sunday, mo máa ń lọ sínú igbó láti ka Bíbélì, àmọ́ àwọn ohun tí mò ń kà ṣàjèjì sí mi, wọ́n dà bí àwọn ìtàn àtọdún gbọ́nhan. Mo tún máa ń lọ sáwọn ilé ẹ̀kọ́ katikísìmù, torí pé mo fẹ́ ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́sìn Menno. Ó yà mí lẹ́nu gan-an nígbà tí mo rí ọ̀rọ̀ yìí nínú ìwé katikísìmù, pé: “Ọlọ́run ni Baba, Ọlọ́run ni Ọmọ, Ọlọ́run sì ní Ẹ̀mí Mímọ́.” Ìbéèrè yìí wá tẹ̀ lé e pé: “Ṣé Ọlọ́run mẹ́ta ló wà ni?” Ìdáhùn tí wọ́n tẹ̀ sísàlẹ̀ rẹ̀ ni pé: “Rárá o, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí jẹ́ ọ̀kan.” Mo bi àlùfáà nípa bí èyí ṣe lè rí bẹ́ẹ̀. Ohun tó sọ fún mi ni pé, “Àwé, kò yẹ kéèyàn máa dara ẹ̀ láàmù jù lórí àwọn ọ̀ràn yìí, orí àwọn míì ti yí torí pé wọ́n ń ronú púpọ̀ jù nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀.” Lójú ẹsẹ̀ níbẹ̀ ni mo pinnu pé mi ò ní ṣèrìbọmi mọ́.

Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, mo gbọ́ tí àjèjì kan ń bá ọmọ ẹ̀gbọ́n bàbá mi sọ̀rọ̀. Torí pé èmi náà fẹ́ mọ ohun tí wọ́n ń sọ, mo lọ jókòó tì wọ́n, mo sì béèrè àwọn ìbéèrè díẹ̀. Mi ò mọ orúkọ àjèjì yìí nígbà yẹn, àmọ́ mo wá mọ̀ ọ́n sí Erich Nikolaizig nígbà tó yá. Ó wà lára àwọn tí kò kú sínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà nílùú Wewelsburg. Ó bi mí bí mo bá fẹ́ lóye Bíbélì. Nígbà tí mo sọ pé bẹ́ẹ̀ ni, ó fi dá mi lójú pé àtinú Bíbélì tèmi gangan lòun ti máa ṣàlàyé gbogbo ohun tóun máa kọ́ mi.

Kò pẹ́ púpọ̀ tí Arákùnrin Nikolaizig bẹ̀rẹ̀ sí í wá sọ́dọ̀ mi, tó sì pè mí sí àpéjọ àgbègbè àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àpéjọ yìí wà lára èyí tí mo mọ̀ pé wọ́n kọ́kọ́ ṣe lẹ́yìn ogun. Àpéjọ náà mórí mi wú gan-an. Mo kọ gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ táwọn olùbánisọ̀rọ̀ kà àti èyí tí wọ́n mẹ́nu kàn sílẹ̀. Láìpẹ́, mo kíyè sí i pé ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo ń kọ́ á mú kó pọn dandan fún mi láti ṣe àwọn nǹkan kan, ni mo bá pinnu láti dá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró. Ó tún ṣòro fún mi láti gbà pé ẹ̀sìn tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà. Nígbà tí Arákùnrin Nikolaizig rí i pé mo ti pinnu láti padà sínú ṣọ́ọ̀ṣì tí mo wà tẹ́lẹ̀, ó fún mi ní ìmọ̀ràn yìí, pé, “Máa la etí ẹ sílẹ̀ dáadáa kó o lè mọ ìyàtọ̀.”

Kò ju ẹ̀ẹ̀mejì péré lọ tí mo lọ rí àwọn àlùfáà wa tí mo fi mọ̀ pé ohun tí wọ́n ń sọ gan-an ò yé àwọn alára àti pé irọ́ pátápátá gbáà ni wọ́n fi ń kọ́ àwọn èèyàn. Mo kọ̀wé sí ọ̀pọ̀ àlùfáà láti bi wọ́n láwọn ìbéèrè nípa Bíbélì. Ọ̀kan fèsì pé: “O ò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ torí o kò tíì di àtúnbí.”

Ọmọbìnrin kan tí mò ń fẹ́ nígbà yẹn sún mi débi tí mo fi ní láti ṣe ìpinnu kan tó ṣòro gan-an. Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ya ẹ̀sìn Menno tí wọ́n ń pe ara wọn ní àtúnbí ni ọmọbìnrin ọ̀hún. Torí pé àwọn ìdílé rẹ̀ kórìíra àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n kó sí i nínú, ó sì sọ fún mi pé tí mo bá ti mọ̀ pé mi ò ní pa ẹ̀sìn tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ yìí tì, kí oníkálukú máa lọ nílọ tiẹ̀. Ojú tèmi sì ti là dáadáa nígbà yẹn láti rí i pé kò sí àbùjá lọ́rùn ọ̀pẹ, bí mi ò ṣe fẹ́ ẹ mọ́ nìyẹn.

Láìpẹ́, Arákùnrin Nikolaizig padà wá bẹ̀ mí wò. Ó sọ fún mi pé ètò wà láti ṣèrìbọmi fáwọn kan lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀, ó sì béèrè bóyá èmi náà á fẹ́ ṣèrìbọmi. Mo ti wá gbà báyìí pé òtítọ́ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ni, mo sì fẹ́ láti sin Jèhófà Ọlọ́run. Nítorí náà, mo gbà láti ṣèrìbọmi, wọ́n sì ṣèrìbọmi fún mi nínú ọpọ́n ìwẹ̀ lóṣù May ọdún 1948.

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi tán, gbogbo ìdílé wa pinnu láti kó lọ sórílẹ̀-èdè Paraguay, tó wà ní Amẹ́ríkà ti Gúúsù, màmá mi sì bẹ̀ mí pé kí n ká lọ. Mi ò fẹ́ lọ torí mo ṣì fẹ́ máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí mo ń gbà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ lọ. Nígbà tí mo lọ ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Wiesbaden, mo pàdé Arákùnrin August Peters. Ó rán mi létí pé ojúṣe mi ni láti bójú tó ìdílé mi. Ó tún gbà mí níyànjú báyìí pé: “Ohun yòówù tí ì báà ṣẹlẹ̀, má ṣe gbàgbé iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. Tó o bá lọ gbàgbé ẹ̀, o ò ní yàtọ̀ sáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì yòókù.” Títí dòní olónìí ni mo ṣì máa ń rántí bí ìmọ̀ràn tó fún mi ṣe ṣe pàtàkì tó àti ìdí tó fi yẹ kí n máa wàásù láti “ilé dé ilé,” tàbí láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà.—Ìṣe 20:20, 21.

Wọ́n Pè Mí Ní Wòlíì Èké Lórílẹ̀-Èdè Paraguay

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí mo pàdé Arákùnrin August Peters lèmi àtàwọn ìdílé mi wọkọ̀ ojú omi lọ sí Amẹ́ríkà ti Gúúsù. Àgbègbè Gran Chaco tó bọ́ sí orílẹ̀-èdè Paraguay la kó lọ, bí mo tún ṣe bá ara mi láàárín àwọn ẹlẹ́sìn Menno lẹ́ẹ̀kan sí i nìyẹn. Ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn tá a débẹ̀ ni mo rìnrìn àjò tí mo sọ pé ó mu mí lómi yẹn lọ sábúlé tó wà nítòsí wa níbi tí mo ti fẹ́ máa wàásù lémi nìkan. Kíákíá ló ti tàn kálẹ̀ pé “wòlíì èké” kan wà láàárín àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé.

Àkókò yìí ni iṣẹ́ mọlémọlé tí mo kọ́ ṣẹ̀ṣẹ̀ wá wúlò gan-an. Olúkúlùkù ìdílé tó kó wá síbẹ̀ ló nílò ilé tí wọ́n á máa gbé. Bíríkì alámọ̀ àti koríko ni wọ́n fi ń kọ́lé níbẹ̀, koríko ni wọ́n sì fi ń ṣe òrùlé. Láàárín oṣù mẹ́fà tó tẹ̀ lé e làwọn tó fẹ́ gbéṣẹ́ ilé kíkọ́ fún mi fi ń fà mí lọ́tùn-ún lósì, èyí sì jẹ́ kí n ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti wàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà. Àwọn èèyàn kọ́kọ́ ń ṣe dáadáa sí mi, àmọ́ gbàrà tí ilé wọn bá ti dókè tán, wọ́n máa ń fẹ́ kí n tètè máa bá tèmi lọ.

Ọkọ̀ òkun tún ń kó ọ̀pọ̀ àwọn míì tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn Menno tí wọ́n kúrò ní orílẹ̀-èdè Jámánì dé. Lára wọn ni ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Katerina Schellenberg. Òun náà ti bá àwọn Ẹlẹ́rìí pàdé fírí nígbà kan, ó sì tètè rí i pé òtítọ́ Bíbélì ni wọ́n fi ń kọ́ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì ṣèrìbọmi, ó ti ń sọ bí wọ́n ṣe ń bọ̀ nínú ọkọ̀ ojú omi pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun. Nítorí ìyẹn, wọn ò jẹ́ kó bá wọn dé àgbègbè táwọn ọmọ ilẹ̀ Jámánì wà. Wọ́n já a sílẹ̀ lóun nìkan sílùú Asunción, olú ìlú orílẹ̀-èdè Paraguay, ó ríṣẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀, ó kọ́ èdè Sípáníìṣì, ó wá àwọn Ẹlẹ́rìí kàn, ó sì ṣèrìbọmi. Ọ̀dọ́bìnrin alákíkanjú yẹn di ìyàwó mi lóṣù October, ọdún 1950. Ó dúró tì mí gbágbáágbá, ó sì ti ràn mí lọ́wọ́ púpọ̀ nínú àwọn ohun tójú wa ti rí láti ọdún yìí wá.

Ní ìwọ̀nba àkókò díẹ̀, mo ti tọ́jú owó tó pọ̀ tó láti ra kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹṣin méjì, mo sì ń lò ó fún iṣẹ́ ìwàásù. Ìdí ni pé gbọnmọgbọnmọ ni ìmọ̀ràn Arákùnrin Peters ń ró létí mi. Nígbà yẹn, àbúrò mi obìnrin tóun náà ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà dara pọ̀ mọ́ wa. A jọ máa ń lọ ni, a sábà máa ń jí láago mẹ́rin ìdájí, a máa ń rìnrìn àjò wákàtí mẹ́rin, àá wàásù fún wákátì méjì tàbí mẹ́ta, àá sì padà sílé.

Mo ti kà nínú àwọn ìwé wa pé wọ́n máa ń sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn, torí náà, èmi náà ṣètò àsọyé kan. Mi ò ti lọ sípàdé ìjọ rí lórílẹ̀-èdè Jámánì, mo kàn ṣètò ẹ̀ bí mo ṣe rò pé ó yẹ kó rí ni, mo sì ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn mẹ́jọ ló wá sípàdé yìí, èyí sì bí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Menno nínú gan-an. Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í polongo láti gba gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a ti fún àwọn èèyàn, wọ́n sì sọ fáwọn èèyàn náà pé wọn ò gbọ́dọ̀ kí wa.

Lẹ́yìn náà, alábòójútó ìjọba àgbègbè náà ní kí n wá sí ọ́fíìsì àwọn, ọ̀pọ̀ wákàtí sì lòun àtàwọn àlùfáà méjì tó wá láti orílẹ̀-èdè Kánádà fi ń da oríṣiríṣi ìbéèrè bò mí. Níkẹyìn, ọ̀kan nínú wọn sọ pé, “Ọ̀gbẹ́ni, o lè gba ohunkóhun tó bá wù ẹ́ gbọ́, àmọ́, o gbọ́dọ̀ ṣèlérí pé o ò ní bá ẹnikẹ́ni sọ ohun tó o gbà gbọ́ mọ́.” Irú ìlérí báyẹn kọjá ohun tí mo lè ṣe. Nítorí náà, wọ́n sọ pé kí n kúrò lágbègbè náà, torí pé àwọn ò fẹ́ “wòlíì èké” láàárín “àwọn arákùnrin olóòótọ́.” Nígbà tí mo kọ̀, wọ́n láwọn máa sanwó ọkọ̀ gbogbo ìdílé wa. Mo dúró lórí ọ̀rọ̀ mi, mo sì kọ̀ jálẹ̀ pé mi ò lọ.

Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1953 yẹn, mo lọ sí àpéjọ àgbègbè kan ní ìlú Asunción. Mo pàdé Arákùnrin Nathan Knorr, tó wá láti orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn ní ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, mo sì ṣàlàyé bí nǹkan ṣe rí fún un. Ó dábàá pé kí n kó wá sí Asunción, kí n sì máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwùjọ àwọn míṣọ́nnárì kékeré tí wọ́n yàn síbẹ̀, pàápàá níwọ̀n bí iṣẹ́ ìwàásù wa ò ti fi bẹ́ẹ̀ sèso lágbègbè àwọn ẹlẹ́sìn Menno.

A Fi Ìjọba Ọlọ́run Sípò Àkọ́kọ́

Gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lórílẹ̀-èdè Paraguay ò ju márùndínlógójì lọ nígbà yẹn. Mo bá ìyàwó mi sọ ọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ fara mọ́ ká kó lọ sílùú ńlá, àmọ́ ó múra tán láti tún bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésí ayé míì ní ìlú ńlá. Lọ́dún 1954, èmi àti Katerina ìyàwó mi kọ́ ilé oníbíríkì, kò sì ju èmi àti ẹ̀ náà lọ, àwọn àkókó tọ́wọ́ wa dilẹ̀ la sì fi kọ́ ọ. A ò pa ìpàdé kankan jẹ, a sì máa ń sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì fáwọn èèyàn lópin ọ̀sẹ̀.

Ọ̀kan lára àǹfààní tí mo ní ni pé kí n máa tẹ̀ lé alábòójútó àyíká, ìyẹn òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò, kí n lè máa ṣe ògbufọ̀ fún un nígbà tó bá ń ṣèbẹ̀wò sáwọn àgbègbè tí wọ́n ti ń sọ èdè Jámánì lórílẹ̀-èdè Paraguay. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé díẹ̀ ni mo gbọ́ nínú èdè Sípáníìṣì, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ọjọ́ tí màá bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ àsọyé láti èdè Sípáníìṣì sí èdè Jámánì ni mo ṣiṣẹ́ tó le jù lọ rí.

Nítorí àìlera aya mi, a kó lọ sí orílẹ̀-èdè Kánádà lọ́dún 1957. Nígbà tó sì di ọdún 1963, a kó lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ibi yòówù ká wà, gbogbo ìgbà la máa ń sapá láti fi ire Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa. (Mátíù 6:33) Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run pé ó jẹ́ kí n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ látinú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ látìgbà tí mo ti wà lọ́dọ̀ọ́. Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo gbà ti ràn mí lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ní gbogbo ìgbésí ayé mi.

Àǹfààní gidi ló jẹ́ fún mi pé mo ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ àgbàyanu òtítọ́ inú Bíbélì, ó sì tù mí nínú gan-an. Ìdùnnú tó tún wá kúnnú ọkàn mi ni pé gbogbo àwọn ọmọ mi àtàwọn ọmọ ọmọ mi ni wọ́n ti gba ẹ̀kọ́ Bíbélì látìgbà ọmọdé jòjòló. Gbogbo wọn ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Arákùnrin Peters fún mi lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn pé: “Ohun yòówù tí ì báà ṣẹlẹ̀, má ṣe gbàgbé iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé.”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]

Ìdùnnú tó tún wá kúnnú ọkàn mi ni bí mo ṣe ń rí gbogbo àwọn ọmọ mi àtàwọn ọmọ ọmọ mi tí wọ́n ti gba ẹ̀kọ́ Bíbélì látìgbà ọmọdé jòjòló

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

Èmi àti Katerina ìyàwó mi rèé ṣáájú ìgbéyàwó wa lọ́dún 1950

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Èmi, ìyàwó mi àti àkọ́bí wa nílé wa lórílẹ̀-èdè Paraguay, lọ́dún 1952

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Èmi àtàwọn ọmọ mi àtàwọn ọmọ ọmọ mi rèé báyìí

[Credit Line]

Fọ́tò látọwọ́ Keith Trammel © 2000

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]

Fọ́tò látọwọ́ Keith Trammel © 2000