Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Kí Ni Ọlọ́run Ń Wò?”

“Kí Ni Ọlọ́run Ń Wò?”

“GBOGBO ÌGBÀ NI MO MÁA Ń BÉÈRÈ PÉ: KÍ NI ỌLỌ́RUN Ń WÒ?”​—Póòpù Benedict Kẹrìndínlógún, ló sọ̀rọ̀ yìí nígbà tó lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà ní Auschwitz, Poland.

TÍ ÀJÁLÙ BÁ ṢẸLẸ̀, ṢÉ O MÁA Ń RÒ Ó PÉ ‘KÍ NI ỌLỌ́RUN Ń WÒ TÍ IRÚ NǸKAN BÁYÌÍ FI ṢẸLẸ̀?’ ÀBÍ ṢÉ OHUN KAN TI ṢẸLẸ̀ SÍ Ẹ RÍ TÓ MÚ KÓ O BẸ̀RẸ̀ SÍ Í RONÚ PÉ BÓYÁ NI ỌLỌ́RUN BÌKÍTÀ NÍPA RẸ?

Ó ṣeé ṣe kó máa ṣe ẹ́ bíi ti ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Sheila tó wá láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí ìdílé rẹ̀ sì fẹ́ràn ẹ̀sìn gan-an. Ọ̀dọ́bìnrin náà sọ pé: “Láti kékeré ni mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run ló dá wa. Síbẹ̀ mi ò sún mọ́ ọn. Mo mọ̀ pé ó ń rí mi àmọ́ kò sún mọ́ mi. Kò ṣe mí bíi pé Ọlọ́run kórìíra mi, àmọ́ mi ò rò pé ó bìkítà nípa mi.” Kí nìdí tí kò fi dá Sheila lójú pé Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ̀? Ó sọ pé: “Ṣe là ń tinú ìṣòro kan bọ́ sí òmíràn nínú ìdílé wa, ó wá dà bíi pé Ọlọ́run ò rí tiwa rò rárá.”

Bíi ti Sheila, ìwọ náà lè gbà pé Ọlọ́run wà, àmọ́ ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kò rí tìẹ rò. Lóòótọ́, olódodo ni Jóòbù, ó sì ní ìgbàgbọ́ nínú agbára àti ọgbọ́n Ọlọ́run, síbẹ̀ bọ́rọ̀ ṣe rí lára òun náà nìyẹn. (Jóòbù 2:3; 9:4) Nígbà tó ń ti inú ìṣòro kan bọ́ sínú òmíràn, tí kò sì dájú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára, ó bi Ọlọ́run pé: “Èé ṣe tí o fi ojú rẹ gan-an pa mọ́, tí o sì kà mí sí ọ̀tá rẹ?”​—Jóòbù 13:24.

Kí ni Bíbélì sọ? Ṣé Ọlọ́run ló yẹ ká máa dá lẹ́bi tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀? Ṣé ẹ̀rí kankan wà tó fi hàn pé Ọlọ́run bìkítà fún gbogbo èèyàn àti fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa? Ṣé ohun kan wà tó lè jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run mọ̀ wá, ṣé ó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa, ṣé ó ń bá wa kẹ́dùn, ṣé ó ń ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ní ìṣòro?

Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá ṣe lè jẹ́ ká mọ̀ bóyá ó bìkítà nípa wa. (Róòmù 1:20) Lẹ́yìn náà, a tún máa wo ohun tí Bíbélì sọ, ká lè mọ̀ bóyá Ọlọ́run bìkítà nípa wa. Bí ìṣẹ̀dá àti Bíbélì ṣe túbọ̀ ń jẹ́ kó o mọ Ọlọ́run, á túbọ̀ se kedere sí ẹ pé “ó bìkítà fún” ẹ.​—1 Jòhánù 2:3; 1 Pétérù 5:7