Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Kò Kábàámọ̀ Ìpinnu Tó Ṣe Nígbà Èwe Rẹ̀

Kò Kábàámọ̀ Ìpinnu Tó Ṣe Nígbà Èwe Rẹ̀

Ẹ̀GBỌ́N ìyá bàbá mi ni Nikolai Dubovinsky. Lọ́dún díẹ̀ ṣáájú ikú rẹ̀, ó ṣe àkọsílẹ̀ ọ̀pọ̀ ìrírí tó ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, èyí tó mú un láyọ̀ àtèyí tó ní láwọn ìgbà tí nǹkan ò rọgbọ, ìyẹn nígbà tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa lábẹ́ ìjọba Soviet Union àtijọ́. Láìka àwọn ìṣòro tó ní láti fara dà sí, kò fi Jèhófà sílẹ̀ ó sì máa ń láyọ̀ nígbà gbogbo. Arákùnrin Nikolai máa ń sọ pé òun fẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́ gbọ́ ìtàn ìgbésí ayé òun, torí náà màá sọ díẹ̀ lára rẹ̀. Ọdún 1926 ni wọ́n bí Arákùnrin Nikolai, ní abúlé Podvirivka, ní ìlú Chernivtsi Oblast, lórílẹ̀-èdè Ukraine. Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ìdílé wọn sì ń ṣe.

NIKOLAI SỌ BÓ ṢE RÍ ÒTÍTỌ́

Arákùnrin Nikolai sọ pé: “Lọ́jọ́ kan ní ọdún 1941, ẹ̀gbọ́n mi tó ń jẹ́ Ivan mú ìwé Duru Ọlọrun àti The Divine Plan of the Ages wálé pẹ̀lú àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àtàwọn ìwé ìléwọ́ lóríṣiríṣi. Gbogbo wọn ni mo kà tán pátá. Ó yà mí lẹ́nu nígbà tí mo kà á pé Èṣù ló ń fa ìṣòro tó wà nínú ayé, kì í ṣe Ọlọ́run. Bí mo ṣe ń ka àwọn ìtẹ̀jáde náà ni mò ń ka àwọn ìwé Ìhìn Rere, mo sì wá mọ̀ pé mo ti rí òtítọ́. Kíá ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í fìtara sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn míì. Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé yìí ni mò ń lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì túbọ̀ ń wù mí gan-an láti di ìránṣẹ́ Jèhófà.

“Mo mọ̀ pé ìyà máa jẹ mí torí ohun tí mo gbà gbọ́. Ogun ń lọ lọ́wọ́ nígbà yẹn, mi ò sì fẹ́ bá wọn pààyàn. Torí náà, mo múra sílẹ̀ de ìdánwò ìgbàgbọ́ tí màá tó dojú kọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí í há àwọn ẹsẹ̀ Bíbélì bíi Mátíù 10:28 àti 26:52 sórí. Mo pinnu pé mi ò ní fi Jèhófà sílẹ̀ láé, kódà tó bá máa la ẹ̀mí mi lọ!

“Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] lọ́dún 1944, wọ́n ní kí n wá máa ṣiṣẹ́ ológun. Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí màá wà láàárín àwọn ará, ìyẹn àwọn arákùnrin tí wọ́n ti dàgbà tó láti wọṣẹ́ ológun, ibi tí wọ́n ti ń mú àwọn èèyàn wọṣẹ́ ológun ni wọ́n sì kó gbogbo wa sí. A sọ fáwọn aláṣẹ náà pé a ò ní lọ́wọ́ sógun láé, a ò sì ní yí ìpinnu wa pa dà. Inú bí ọ̀kan lára àwọn sójà tó wà níbẹ̀, ó wá sọ pé tá a bá kọ̀ láti jagun, àwọn á febi pa wá, àwọn á fipá mú wa gbẹ́ kòtò, tàbí káwọn tiẹ̀ yìnbọn fún wa. A fìgboyà sọ fún wọn pé: ‘Ohun tó bá wù yín ni kẹ́ ẹ fi wá ṣe. Àmọ́ ohun yòówù kẹ́ ẹ ṣe fún wa, àwa ò ní rú òfin Ọlọ́run tó sọ pé, “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ . . . pànìyàn.”’—Ẹ́kís. 20:13.

“Ó wá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n rán èmi àtàwọn arákùnrin méjì míì lọ sí orílẹ̀-èdè Belarus pé ká lọ máa tún àwọn ilé tó bà jẹ́ ṣe. Mo ṣì rántí bí ara mi ṣe bù máṣọ nígbà tí mo rí bí ogun náà ṣe ba àwọn ìlú tó wà ní àgbègbè ìlú Minsk jẹ́. Àwọn igi tó ti jóná kún ojú ọ̀nà. Òkú àwọn èèyàn àti òkú àwọn ẹṣin tó ti wú wà káàkiri nínú kòtò àti nínú igbó. Mo rí àwọn ọkọ̀ tí wọ́n fi ń kó àwọn ohun ìjà ogun àtàwọn àgbá ogun, mo sì tún rí àwókù ọkọ̀ òfuurufú kan. Mo fi ojú ara mi rí àbájáde rírú òfin Ọlọ́run.

 “Ọdún 1945 ni ogun náà parí, síbẹ̀ wọ́n ní ká lọ lo ọdún mẹ́wàá lẹ́wọ̀n torí pé a kọ̀ láti lọ́wọ́ sógun náà. Lọ́dún mẹ́ta àkọ́kọ́ tá a lò níbẹ̀, a ò ṣe ìpàdé kankan, a ò sì ní ìtẹ̀jáde tó ń ṣàlàyé Bíbélì. À ń kọ lẹ́tà sí àwọn arábìnrin kan, àmọ́ nígbà tó yá wọ́n mú àwọn náà, wọ́n sì ní kí wọ́n lọ lo ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́.

“Ká tó lò tó ọdún mẹ́wàá tí wọ́n dá fún wa, wọ́n dá wa sílẹ̀ lọ́dún 1950, a sì pa dà sílé. Nígbà tí màá fi tẹ̀wọ̀n dé, ìyá mi àti àbúrò mi obìnrin tó ń jẹ́ Maria ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin ò tíì di Ẹlẹ́rìí ní tiwọn, àmọ́ wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí pé mi ò dẹ́kun láti máa wàásù, àwọn ọlọ́pàá ìlú Soviet Union ń wá bí wọ́n ṣe máa rán mi pa dà sẹ́wọ̀n. Àwọn arákùnrin tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè náà wá ní kí n wá máa ṣèrànwọ́ níbi tí wọ́n ti ń tẹ ìwé wa lábẹ́ ilẹ̀. Ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún [24] ni mí nígbà yẹn.”

BÁ A ṢE Ń TẸ ÀWỌN ÌWÉ WA

“Àwọn Ẹlẹ́rìí sábà máa ń sọ nígbà yẹn pé, ‘Tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa lókè èèpẹ̀, a ó máa bá a lọ lábẹ́ ilẹ̀.’ (Òwe 28:28) Nígbà yẹn, ibi ìkọ̀kọ̀ kan tó wà ní abẹ́ ilẹ̀ la ti ń tẹ púpọ̀ nínú àwọn ìwé wa. Yàrá kan tí wọ́n kọ́ sí ìsàlẹ̀ ilé kan tí ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tó ń jẹ́ Dmitry ń gbé ni mo ti kọ́kọ́ ṣiṣẹ́. Nígbà míì, mo máa ń wà nínú yàrá náà fún ọ̀sẹ̀ méjì gbáko láì jáde rárá. Tí láńtà tí mò ń lò bá kú torí pé kò sí atẹ́gùn nínú yàrá náà mọ́, màá dùbúlẹ̀ títí tí atẹ́gùn á fi wọlé.

Àwòrán yàrá kékeré tó wà ní abẹ́ ilẹ̀, nílé tí Nikolai ti ń tẹ àwọn ìwé w

“Lọ́jọ́ kan, arákùnrin tá a jọ ń ṣiṣẹ́ bi mí pé, ‘Nikolai, ṣó o ti ṣèrìbọmi?’ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti sin Jèhófà fún ọdún mọ́kànlá nígbà yẹn, mi  ò tíì ṣèrìbọmi. Arákùnrin náà bá mi sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, mo sì ṣèrìbọmi lálẹ́ ọjọ́ yẹn nínú adágún omi kan. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26] ni mí lọ́dún yẹn. Ní ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, mo ní àǹfààní láti di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Orílẹ̀-èdè náà. Nígbà yẹn, tí wọ́n bá fàṣẹ ọba mú lára àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù lórílẹ̀-èdè náà, wọ́n á fi àwọn arákùnrin tí wọn ò tíì mú rọ́pò wọn. Iṣẹ́ ìwàásù náà sì ń tẹ̀ síwájú.”

ÀWỌN ÌṢÒRO TÁ A FARA DÀ BÁ A TI Ń ṢIṢẸ́ LÁBẸ́ ILẸ̀

“Iṣẹ́ títẹ ìwé lábẹ́ ilẹ̀ tún wá le ju kéèyàn wà lẹ́wọ̀n lọ! Ọdún méje ni mi ò fi lè lọ sí ìpàdé ìjọ kankan kí àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ má bàa rí mi, torí náà ṣe ni mo máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́ kí àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú Jèhófà má bàa bà jẹ́. Ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni mo máa ń rí àwọn èèyàn mi, ìyẹn nígbà tí mo bá lọ kí wọn. Síbẹ̀, àwọn náà mọ bí nǹkan ṣe rí, èyí sì máa ń fún mi ní ìṣírí. Torí pé gbogbo ìgbà ni mo gbọ́dọ̀ máa kíyè sára kí n sì máa ṣọ́ra, ó máa ń rẹ̀ mí gan-an. A ní láti wà lójúfò nígbà gbogbo torí pé ohunkóhun ló lè ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ọlọ́pàá méjì wá sí ilé tí mò ń gbé. Mo bá fò jáde láti ojú wíńdò, mo sì fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ, ó dinú igbó. Nígbà tí mo bọ́ sí pápá gbalasa, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ìró kan tó ṣàjèjì bíi pé ẹnì kan ń súfèé. Ìgbà tí mo gbọ́ tàù-tàù, ni mo tó wá mọ̀ pé ìró ọta ìbọn ni mò ń gbọ́! Ọ̀kan nínú àwọn tó ń lé mi bẹ́ sórí ẹṣin, ó ń sáré tẹ̀ lé mi, ó sì ń yìnbọn lù mí títí tí ọta fi tán nínú ìbọn rẹ̀. Ọta ìbọn kan bà mí lápá. Lẹ́yìn tí mo ti sáré kìlómítà márùn-ún (ibùsọ̀ 3), mo sá pa mọ́ sáàárín igbó kan, bí mo ṣe bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́ nìyẹn. Lẹ́yìn náà, nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ mi, wọ́n sọ pé ìgbà méjìlélọ́gbọ̀n [32] ni wọ́n yìnbọn lù mí.

“Torí pé abẹ́ ilẹ̀ ni mo máa ń wà ní gbogbo ìgbà, ara mi bẹ̀rẹ̀ sí í funfun. Èyí ló wá jẹ́ kí àwọn èèyàn tètè mọ irú iṣẹ́ tí mò ń ṣe. Torí náà, mo máa ń lọ yáàrùn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bó ṣe jẹ́ pé abẹ́ ilẹ̀ ni mo máa ń wà lọ́pọ̀ ìgbà tún kó bá ìlera mi. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí mo pa ìpàdé pàtàkì kan jẹ, torí pé ẹ̀jẹ̀ ń dà ní imú àti ẹnu mi.”

WỌ́N MÚ NIKOLAI

Ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ lọ́dún 1963, lórílẹ̀-èdè Mordvinia

“Ní January 26, ọdún 1957, wọ́n mú mi. Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Ukraine dá ẹjọ́ mi. Wọ́n dá ẹjọ́ ikú fún mi, wọ́n ní kí wọ́n lọ yìnbọn pa mí. Àmọ́, torí pé wọ́n ti fagi lé ẹjọ́ ikú lórílẹ̀-èdè yẹn, wọ́n yí ìdájọ́ ikú  náà sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25]. Wọ́n rán àwa mẹ́jọ lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà lórílẹ̀-èdè Mordvinia níbi tí àwọn Ẹlẹ́rìí tó tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] wà ni wọ́n rán wa lọ. Ńṣe la máa ń pín ara wa sí àwùjọ kéékèèké, àá wá pàdé níkọ̀kọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Lẹ́yìn tí ẹ̀ṣọ́ kan lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà ka àwọn kan lára àwọn ìwé ìròyìn wa tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé, ó sọ pé: ‘Tẹ́ ẹ bá ń ka àwọn ìwé yìí, kò sẹ́ni tó máa lè yí yín lérò pa dà lóòótọ́!’ A máa ń ṣiṣẹ́ kára, a tiẹ̀ máa ń ṣe kọjá iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún wa lọ́pọ̀ ìgbà. Síbẹ̀, olórí ẹ̀ṣọ́ àgọ́ náà sọ pé: ‘Iṣẹ́ tẹ́ ẹ̀ ń ṣe níbí kọ́ la fẹ́ jẹ, ohun tá a fẹ́ ni pé kẹ́ ẹ jà fún orílẹ̀-èdè yín.’”

“A máa ń ṣiṣẹ́ kára, a tiẹ̀ máa ń ṣe kọjá iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún wa lọ́pọ̀ ìgbà”

ÌGBÀGBỌ́ NIKOLAI KÒ YINGIN

Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní ìlú Velikiye Luki

Lẹ́yìn tí wọ́n dá Arákùnrin Nikolai sílẹ̀ ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ lọ́dún 1967, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò àwọn ìjọ ní orílẹ̀-èdè Estonia àti ní ìlú St. Petersburg lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1991, wọ́n fagi lé ẹjọ́ tí wọ́n dá fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ọdún 1957 torí kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé wọ́n ṣe ohun tó lòdì sófin. Lákòókò yẹn, wọ́n dá ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ti ṣe inúnibíni tó rorò sí láre. Lọ́dún 1996, Nikolai kó lọ sí ìlú Velikiye Luki ní ìpínlẹ̀ Pskov Oblast, tó tó nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] kìlómítà (300 ibùsọ̀) sí ìlú St. Petersburg. Ó ra ilé kékeré kan, nígbà tó sì di ọdún 2003, wọ́n kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan sórí ilẹ̀ tí ilé náà wà. Ìjọ méjì tó ń gbèrú ló ń pàdé nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba náà báyìí.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ni èmi àti ọkọ mi ti ń sìn. Ní oṣù March ọdún 2011, ìyẹn oṣù díẹ̀ ṣáájú ikú Arákùnrin Nikolai, ó wá kí wa nílé. Ìgbà yẹn la sì fojú kanra gbẹ̀yìn. Àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ wọ̀ wá lọ́kàn gan-an, ó fi ìdánilójú sọ fún wa pé: “Bí gbogbo nǹkan ṣe rí yìí, mo lè sọ pé ọjọ́ keje táwọn ọmọ Ísírẹ́lì yan yí ká odi Jẹ́ríkò ti bẹ̀rẹ̀.” (Jóṣ. 6:15) Ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́rin [85] ni nígbà tó kú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé nira fún un, ohun tó sọ nípa ìgbésí ayé rẹ̀ ni pé: “Inú mi má dùn o pé nígbà tí mo wà léwe, mo pinnu láti sin Jèhófà! Mi ò kábàámọ̀ rẹ̀ láé!”