Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Kọ́ Ọmọ Yín Láti Kékeré

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Kọ́ Ọmọ Yín Láti Kékeré

BÍBÉLÌ sọ pé: “Wò ó! Àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà; èso ikùn jẹ́ èrè.” (Sm. 127:3) Nígbà náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu tí àwọn òbí Kristẹni bá ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí wọ́n bá bí ọmọ tuntun.

Àmọ́, báwọn òbí ṣe ń yọ̀ náà ló ṣe yẹ kí wọ́n máa rántí pé, iṣẹ́ ń bẹ lọ́wọ́ àwọn. Kí ọmọ kan tó lè dàgbà, kí ara rẹ̀ sì dá ṣáṣá, ó gba pé kí àwọn òbí máa fi oúnjẹ aṣaralóore bọ́ ọ ní gbogbo ìgbà. Bákan náà, kí ọmọ kan tó dàgbà di ẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àwọn òbí gbọ́dọ̀ máa fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ ọ, kí wọ́n máa tọ́ ọ sọ́nà, kí wọ́n sì máa sapá láti gbin ìtọ́ni Jèhófà sí i lọ́kàn. (Òwe 1:8) Ìgbà wo ló yẹ kí òbí kan bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọmọ rẹ̀, kí ló sì yẹ kí ó kọ́ ọmọ náà?

Ẹ̀YIN ÒBÍ NÍLÒ ÌTỌ́NI

Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ ọkùnrin kan ní Ísírẹ́lì ìgbàanì yẹ̀ wò. Orúkọ rẹ̀ ni Mánóà. Ìdílé Dánì ló ti wá, ó sì ń gbé nílùú Sórà. Ańgẹ́lì Jèhófà sọ fún ìyàwó rẹ̀ tó ya àgàn pé ó máa bí ọmọkùnrin kan. (Oníd. 13:2, 3) Ṣe ni inú ọkùnrin olóòótọ́ yìí àti ìyàwó rẹ̀ dùn gan-an nígbà tí wọ́n gbọ́ ìròyìn ayọ̀ náà. Àmọ́, ohun kan wà tó kó ìrònú bá wọn. Torí náà, Mánóà gbàdúrà pé: “Dákun, Jèhófà. Ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ tí o ṣẹ̀ṣẹ̀ rán wá, jọ̀wọ́, jẹ́ kí ó tún tọ̀ wá wá, kí ó sì fún wa ní ìtọ́ni ní ti ohun tí ó yẹ kí a ṣe sí ọmọ náà tí a óò bí.” (Oníd. 13:8) Mánóà àti ìyàwó rẹ̀ ń ronú nípa bí wọ́n ṣe máa tọ́ ọmọ wọn dàgbà. Kò sí àní-àní pé wọ́n kọ́ Sámúsìnì ọmọ wọn ní òfin Ọlọ́run, ìsapá wọn ò sì já sásán. Bíbélì sọ pé “Nígbà tí ó ṣe, ẹ̀mí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí sún [Sámúsìnì] ṣiṣẹ́.” Èyí sì mú kí Sámúsìnì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára nígbà tó wà nípò gẹ́gẹ́ onídàájọ́ Ísírẹ́lì.—Oníd. 13:25; 14:5, 6; 15:14, 15.

Mánóà gbàdúrà pé kí Ọlọ́run tọ́ àwọn sọ́nà nípa bí wọ́n ṣe máa tọ́ ọmọ tí wọ́n máa bí

Ìgbà wo gan-an ló yẹ kí ẹ̀yin òbí bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ yín? “Láti ìgbà ọmọdé jòjòló” ni ìyá Tímótì, ìyẹn Yùníìsì àti ìyá rẹ̀ àgbà Lọ́ìsì ti kọ́ ọ ní “ìwé mímọ́.” (2 Tím. 1:5; 3:15) Ó ṣe kedere pé Tímótì ṣì kéré gan-an nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi Ìwé Mímọ́ kọ́ ọ.

Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé kí ẹ̀yín òbí gbàdúrà pé kí Jèhófà tọ́ yín sọ́nà, kẹ́ ẹ sì ṣe ètò tó ṣe gúnmọ́ kó lè ṣeé ṣe fún yín láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọmọ yín “láti ìgbà ọmọdé jòjòló.” Ó ṣe tán, Òwe 21:5 ṣáà sọ pé: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.” Látìgbà tí aláboyún bá ti wà nínú oyún lòun àti ọkọ rẹ̀ á ti máa múra sílẹ̀. Wọ́n tiẹ̀ lè ṣe àkọsílẹ̀ àwọn nǹkan tí wọ́n mọ̀ pé ọmọ náà máa nílò. Bẹ́ẹ̀ náà ló tún ṣe pàtàkì pé kí wọ́n ṣètò bí wọ́n ṣe máa pèsè ohun tọ́mọ náà nílò nípa tẹ̀mí. Ó yẹ kí wọ́n ní in lọ́kàn pé láti kékeré làwọn ti máa bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ ní ọ̀nà Ọlọ́run.

Ìwé kan tí wọ́n pè ní Early Childhood Counts—A Programming Guide on Early Childhood Care for Development sọ pé: “Báwọn òbí bá ṣe tọ́jú ọmọ wọn látìgbà tí wọ́n bá ti bí i títí di oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà ló máa pinnu bí ọpọlọ ọmọ náà ṣe máa ṣiṣẹ́ sí. Ní àkókò yìí, fọ́nrán iṣan inú ọpọlọ tó ń mú kéèyàn lè kọ́ nǹkan tuntun máa ń túbọ̀ pọ̀ sí i ní ìlọ́po ogún.” Ẹ wo bó ṣe bọ́gbọ́n mu tó pé kí àwọn òbí lo àkókò kúkúrú yìí láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ àtàwọn ìlànà Ọlọ́run!

Ìyá kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sọ nípa ọmọ rẹ̀ pé: “Látìgbà tó ti wà lọ́mọ oṣù kan ni mo tí máa ń gbé e lọ sóde ẹ̀rí. Lóòótọ́, kò lóye ohun tó ń lọ, àmọ́ mo gbà pé bí mo ṣe ń gbé e lọ sóde láti kékeré yẹn ṣe é láǹfààní gan-an. Nígbà tó fi máa pé ọmọ ọdún méjì, kì í bẹ̀rù láti fún àwọn èèyàn ní ìwé àṣàrò kúkúrú lóde ẹ̀rí.”

Ó máa ń dára gan-an téèyàn bá tètè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọmọ láti kékeré. Àmọ́, ọ̀pọ̀ òbí ló ti rí i pé, àwọn ìṣòro kan wà téèyàn máa ń kojú tó bá fẹ́ kọ́ ọmọ kan ní ọ̀nà Ọlọ́run láti kékeré.

‘Ẹ RA ÀKÓKÒ TÍ Ó RỌGBỌ PA DÀ’

Olórí ohun tó sábà máa ń jẹ́ ìṣòro fún àwọn òbí ni pé, ara àwọn ọmọdé kì í balẹ̀, ìwọ̀nba àkókò ni wọ́n sì lè fi jókòó jẹ́ẹ́ kí wọ́n sì pọkàn pọ̀ sórí nǹkan. Nítorí pé wọ́n máa ń fẹ́ láti mọ̀ nípa gbogbo nǹkan tó wà láyìíká wọn, ọkàn wọn máa ń tètè kúrò lórí ohun kan bọ́ sí òmíràn. Kí wá ni àwọn òbí lè ṣe kí àwọn ọmọ wọn lè máa pọkàn pọ̀ sórí ohun tí wọ́n ń kọ́ wọn?

Ẹ jẹ́ ká gbé ohun tí Mósè sọ yẹ̀ wò. Ìwé Diutarónómì 6:6, 7 sọ pe: “Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ; kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.” Gbólóhùn náà “fi ìtẹnumọ́ gbìn” túmọ̀ sí kéèyàn máa kọ́ni ní gbogbo ìgbà, kó máa sọ ọ́ lásọtúnsọ. Àwọn ọmọdé dà bí igi kékeré kan tó nílò kéèyàn máa bu omi sí i déédéé kó bàa lè dàgbà dáadáa. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àsọtúnsọ máa ń mú kí àwọn àgbàlagbà pàápàá rántí àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì, ó dájú pé àsọtúnsọ máa ran àwọn ọmọdé náà lọ́wọ́.

Káwọn òbí tó lè máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ ọmọ, àfi kí wọ́n máa lo àkókò pẹ̀lú wọn. Nínu ayé kòókòó jàn-ánjàn-án yìí, ó máa ń ṣòro fún àwọn òbí láti wá àyè kí wọ́n lè wà pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Àmọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé kí a ‘ra àkókò tí ó rọgbọ pa dà’ láti máa lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni. (Éfé. 5:15, 16) Báwo làwọn òbí ṣe lè ṣe é? Àpẹẹrẹ kan rèé, arákùnrin kan wà tó jẹ́ alàgbà, ó ní ọmọbìnrin kan, ó ní iṣẹ́ tó ń bójú tó nínú ìjọ, ó sì tún ń ṣiṣẹ́ láti gbọ́ bùkátà. Yàtọ̀ síyẹn, aṣáájú-ọ̀nà ni ìyàwó rẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ sì máa ń dí ní gbogbo ìgbà. Kí ní arákùnrin yìí ṣe tí ìkan ò fi pa ìkan lára? Báwo ni wọ́n ṣe máa ń ráyè kọ́ ọmọbìnrin wọn? Bàbá yẹn sọ pé: “Láràárọ̀ kí n tó lọ sí ibi iṣẹ́, èmi àti ìyàwó mi máa ń ka Ìwé Ìtàn Bíbélì tàbí Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ sí i létí. Kó tó sùn lálẹ́, a tún máa ń rí i dájú pé a kàwé sí i létí. Tá a bá sì ń lọ sóde ẹ̀rí a máa ń rí i dájú pé a gbé e dání. A fẹ́ tètè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ ní ìlànà Ọlọ́run láti ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀.”

‘ÀWỌN ỌMỌ DÀ BÍ ỌFÀ’

Ó dájú pé a fẹ́ kí àwọn ọmọ wa yàn kí wọ́n yanjú. Àmọ́, ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká kọ́ wọn ní pé a fẹ́ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run látọkànwá.—Máàkù 12:28-30.

Ìwé Sáàmù 127:4 sọ pé: “Bí àwọn ọfà ní ọwọ́ alágbára ńlá, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ìgbà èwe.” Nípa bẹ́ẹ̀, ṣe làwọn ọmọ dà bí àwọn ọfà tó yẹ kí tafàtafà kán fara balẹ̀ ta sí ibi tó tọ́, kó má sì tàsé. Tí tafàtafà kan bá ti ta ọfà kan, ó ti ta á nìyẹn o, tó bá sì tàsé ibi tó yẹ kó lọ, bí ìgbà téèyàn ṣe àṣedànù ló jẹ́. Bí ọfà làwọn ọmọ rí lọ́wọ́ àwọn òbí, ìgbà díẹ̀ sì ni àwọn òbí ní láti fi ta ọfà yìí síbi tó wù wọ́n. Ó sì yẹ kí wọ́n tètè lo ìwọ̀nba àkókò náà láti gbin àwọn ìlànà Jèhófà sí àwọn ọmọ wọn lọ́kàn.

Àpọ́sítélì Jòhánù sọ nípa àwọn ọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí pé: “Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” (3 Jòh. 4) Àwọn òbí náà le ṣọpẹ́ tí wọ́n bá rí àwọn ọmọ wọn tí wọ́n “ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.”