Ǹjẹ́ O Mọ Ṣáfánì àti Ìdílé Rẹ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ Ṣáfánì àti Ìdílé Rẹ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ Ṣáfánì àti Ìdílé Rẹ̀?

BÓ O ṣe ń ka Bíbélì rẹ, ǹjẹ́ o ti fìgbà kan rí kíyè sí ibi tá a ti dárúkọ Ṣáfánì àti àwọn kan nínú ìdílé rẹ̀ tó lókìkí? Ta làwọn èèyàn yìí? Kí ni wọ́n ṣe? Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára wọn?

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa “Ṣáfánì ọmọkùnrin Asaláyà ọmọkùnrin Méṣúlámù” nígbà tó ń sọ bí Jòsáyà ṣe mú ìjọsìn mímọ́ padà bọ̀ sípò ní nǹkan bí ọdún 642 ṣáájú Sànmánì Tiwa. (2 Àwọn Ọba 22:3) Láàárín ọdún mẹ́rìndínlógójì tó tẹ̀ lé e títí dìgbà ìparun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Tiwa, a sọ fun wa nípa àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, Áhíkámú, Élásà, Gemaráyà, àti Jaasáyà. (Wo ṣáàtì tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí.) Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Judaica, sọ pé: “Ìdílé Ṣáfánì ló pọ̀ jù ní ipò àkóso [nínú ìjọba Júdà] àwọn ló sì di ipò akọ̀wé ọba mú látìgbà Jòsáyà títí dìgbà tá a kó wọn lọ sígbèkùn.” Ṣíṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa Ṣáfánì àti ìdílé rẹ̀ á jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì bí wọ́n ṣe ṣètìlẹ́yìn fún Jeremáyà àti fún ìjọsìn tòótọ́ Jèhófà.

Ṣáfánì Ṣètìlẹ́yìn fún Ìjọsìn Tòótọ́

Ṣáfánì ni akọ̀wé ọba àti adàwékọ lọ́dún 642 ṣáájú Sànmánì Tiwa, nígbà tí Jòsáyà Ọba wà ní nǹkan bí ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. (Jeremáyà 36:10) Kí lèyí ní nínú? Ìwé tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ tá a mẹ́nu kàn lókè yìí sọ pé ẹni tó bá jẹ́ adàwékọ àti akọ̀wé láàfin máa ń jẹ́ bọ́bajíròrò tó sún mọ́ ọba gan-an, òun ló máa ń bójú tó ọ̀ràn ìṣúnná owó, á jẹ́ ẹni tó mọ ọgbọ́n mẹ̀bẹ́mẹ̀yẹ̀, tó mọ béèyàn ṣe ń bójú tó ọ̀ràn ilẹ̀ òkèèrè, tó sì mọ òfin orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn àti ọ̀ràn ìṣòwò. Nítorí náà, jíjẹ́ tí Ṣáfánì jẹ́ akọ̀wé láàfin mú kó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèyàn tó wà ní ipò ńlá jù lọ ní ilẹ̀ náà.

Ọdún mẹ́wàá ṣáájú àkókò yìí ni Jòsáyà ti “bẹ̀rẹ̀ sí wá Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ̀.” Ẹ̀rí fi hàn pé gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ni Ṣáfánì fi ju Jòsáyà lọ, èyí ló ní láti mú kó tóótun láti lè fún Jòsáyà nímọ̀ràn lórí ọ̀ràn ìjọsìn, tó sì tún dúró tì í gbágbáágbá nígbà tí Jòsáyà kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ akitiyan láti mú ìjọsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò ní ilẹ̀ náà. a2 Kíróníkà 34:1-8.

Nígbà tí wọ́n ń ṣàtúnṣe tẹ́ńpìlì, wọ́n rí “ìwé òfin gan-an,” Ṣáfánì sì “bẹ̀rẹ̀ sí kà á níwájú ọba.” Ọkàn Jòsáyà gbọgbẹ́ nígbà tó gbọ́ ohun tó wà nínú ìwé náà, ó sì rán ikọ̀ kan tó jẹ́ àwọn ọkùnrin tó ṣe é fọkàn tán lọ sọ́dọ̀ wòlíì obìnrin Húlídà láti wádìí nípa ìwé náà lọ́dọ̀ Jèhófà. Ọba fi hàn pé òun fọkàn tán Ṣáfánì àti Áhíkámù ọmọ rẹ̀ nípa yíyàn wọ́n sínú ikọ̀ náà.—2 Àwọn Ọba 22:8-14; 2 Kíróníkà 34:14-22.

Ibì kan ṣoṣo tá a ti mẹ́nu ba ohun tí Ṣáfánì fúnra rẹ̀ ṣe rèé nínú Ìwé Mímọ́. Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó kù kàn ń pè é ní baba tàbí babańlá ni. Àwọn ọmọ Ṣáfánì sún mọ́ wòlíì Jeremáyà gan-an ni.

Áhíkámù àti Gẹdaláyà

Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ, ìgbà tá à ń sọ̀rọ̀ ikọ̀ tá a rán lọ sọ́dọ̀ wòlíì obìnrin Húlídà ni ìgbà àkọ́kọ́ tá a mẹ́nu kan Áhíkámù ọmọ Ṣáfánì. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Òótọ́ ni pé a ò sọ ipò tí Áhíkámù wà nínú Bíbélì èdè Hébérù, àmọ́ ó hàn gbangba pé ipò gíga ló wà.”

Nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni ẹ̀mí Jeremáyà wà nínú ewu. Nígbà tó sọ fún àwọn èèyàn pé Jèhófà fẹ́ pa Jerúsálẹ́mù run, “àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn ènìyàn náà gbá a mú, wọ́n wí pé: ‘Dájúdájú, ìwọ yóò kú.’” Kí ló tẹ̀yìn èyí jáde? Àkọsílẹ̀ náà sọ síwájú pé: “Ọwọ́ Áhíkámù ọmọkùnrin Ṣáfánì ni ó wà pẹ̀lú Jeremáyà, kí a má bàa fi í lé àwọn ènìyàn náà lọ́wọ́ láti ṣe ikú pa á.” (Jeremáyà 26:1-24) Kí lèyí fi hàn? Ìwé atúmọ̀ èdè náà, The Anchor Bible Dictionary sọ pé: “Kì í ṣe pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí fi hàn pé Áhíkámù jẹ́ èèyàn pàtàkì nìkan ni, àmọ́ ó tún fi hàn pé òun àtàwọn tó kù nínú ìdílé Ṣáfánì, wà lẹ́yìn Jeremáyà gbágbáágbá.”

Ní nǹkan bí ogún ọdún lẹ́yìn náà, lẹ́yìn tí àwọn ará Bábílónì ti pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Tiwa tí wọ́n sì kó èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn èèyàn náà nígbèkùn, Gẹdaláyà ọmọ ọmọ Ṣáfánì, tí Áhíkámù bí ni wọ́n yàn láti ṣàkóso àwọn Júù tó ṣẹ́ kù. Ǹjẹ́ òun náà tọ́jú Jeremáyà gẹ́gẹ́ bí àwọn ará ilé Ṣáfánì tó kù ṣe ṣe? Àkọsílẹ̀ Bíbélì kà pé: “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jeremáyà wá sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ọmọkùnrin Áhíkámù ní Mísípà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé pẹ̀lú rẹ̀.” Kò ju oṣù bíi mélòó kan tí wọ́n pa Gẹdaláyà, àwọn Júù tó kù sì mú Jeremáyà dání nígbà tí wọ́n ṣí lọ sí Íjíbítì.—Jeremáyà 40:5-7; 41:1, 2; 43:4-7.

Gemaráyà àti Mikáyà

Gemaráyà ọmọ Ṣáfánì àti Mikáyà tí í ṣe ọmọ ọmọ rẹ̀ kó ipa tó jọjú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà ní Jeremáyà orí 36. Nǹkan bí ọdún 624 ṣáájú Sànmánì Tiwa lọ̀ràn náà, ní ọdún kárùn-ún tí Jèhóákímù Ọba gorí ìtẹ́. Bárúkù tí í ṣe akọ̀wé Jeremáyà ka ọ̀rọ̀ Jeremáyà tó wà nínú ìwé náà sókè ketekete nínú ilé Jèhófà, “ní yàrá ìjẹun Gemaráyà ọmọkùnrin Ṣáfánì.” Báyìí ni “Mikáyà ọmọkùnrin Gemaráyà ọmọkùnrin Ṣáfánì sì wá gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà láti inú ìwé náà.”—Jeremáyà 36:9-11.

Mikáyà sọ fún bàbá rẹ̀ àtàwọn ọmọ ọba tó kù nípa àkájọ ìwé náà, gbogbo wọn sì fẹ́ gbọ́ ohun tó wà nínú rẹ̀. Kí ni wọ́n wá ṣe? “Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé gbàrà tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ náà, wọ́n wo ara wọn tìbẹ̀rùbojo; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún Bárúkù pé: ‘Láìkùnà, àwa yóò sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún ọba.’” Àmọ́ kí wọ́n to sọ fún ọba, wọ́n sọ fún Bárúkù pé: “Lọ, fi ara rẹ pa mọ́, ìwọ àti Jeremáyà, tí ẹnì kankan kò fi ní mọ ibi tí ẹ wà.”—Jeremáyà 36:12-19.

Ohun tí wọ́n retí pé á ṣẹlẹ̀ náà ló ṣẹlẹ̀, ọba ò fara mọ́ ohun tó wà nínú ìwé náà páàpáà ó sì finá sun ún lọ́kọ̀ọ̀kan. Àwọn kan lára àwọn ọmọ ọba, títí kan Gemaráyà ọmọ Ṣáfánì “rọ ọba pé kí ó má fi iná sun àkájọ náà, ṣùgbọ́n kò fetí sí wọn.” (Jeremáyà 36:21-25) Ìwé Jeremiah—An Archaeological Companion, parí ọ̀rọ̀ pé: “Gbágbáágbá ni Gemaráyà ti Jeremáyà lẹ́yìn ní àgbàlá Jèhóákímù Ọba.”

Élásà àti Jaasánáyà

Ní ọdún 617 ṣáájú Sànmánì Tiwa, Bábílónì bẹ̀rẹ̀ sí darí ìjọba Júdà. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Júù, “gbogbo ọmọ aládé àti gbogbo akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin . . . àti gbogbo oníṣẹ́ ọnà àti àwọn tí ń kọ́ àwọn odi ààbò pẹ̀lú,” títí kan wòlíì Ìsíkíẹ́lì ni wọ́n kó lọ sígbèkùn. Matanáyà, tí àwọn ará Bábílónì yí orúkọ rẹ̀ padà sí Sedekáyà wá di ọba tuntun lábẹ́ àkóso wọn. (2 Àwọn Ọba 24:12-17) Nígbà tó yá, Sedekáyà rán ìgbìmọ̀ kan lọ sí Bábílónì, Élásà ọmọ Ṣáfánì wà lára ìgbìmọ̀ náà. Jeremáyà mú lẹ́tà kan tó ní ìhìn pàtàkì tí Jèhófà ní fún àwọn Júù tó wà lóko ẹrú nínú fún Élásà.—Jeremáyà 29:1-3.

Àkọsílẹ̀ inú Bíbélì fi hàn pé Ṣáfánì àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta, àti méjì lára àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ fi ipò ńlá tí wọ́n wà ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn tòótọ́ àti fún Jeremáyà, wòlíì tòótọ́ náà. Jaasánáyà wá ńkọ́, tóun náà jẹ́ ọmọ Ṣáfánì? Òun ní tiẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí àwọn yòókù nínú ìdílé Ṣáfánì, òrìṣà ló ń bọ ràì. Ní ọdún kẹfà tí Ìsíkíẹ́lì ti wà nígbèkùn ní Bábílónì, tàbí ní nǹkan bí ọdún 612 ṣáájú Sànmánì Tiwa, wòlíì yìí ríran kan nínú èyí tó ti rí àádọ́rin ọkùnrin tí wọ́n ń sun tùràrí sáwọn òrìṣà nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. Jaasánáyà jẹ́ ọ̀kan lára wọn, òun nìkan la sì dárúkọ rẹ̀. Èyí fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ abẹnugan lára àwọn èèyàn yìí. (Ìsíkíẹ́lì 8:1, 9-12) Àpẹẹrẹ Jaasánáyà kọ́ wa pé títọ́ èèyàn dàgbà nínú ìdílé tó bẹ̀rù Ọlọ́run kì í ṣe ẹ̀rí ìdánilójú pé onítọ̀hún á di olùjọsìn tòótọ́ fún Jèhófà. Olúkúlùkù ló máa pinnu ohun tóun máa ṣe.—2 Kọ́ríńtì 5:10.

Ìtàn Ṣáfánì àti Ìdílé Rẹ̀

Àwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí lo òǹtẹ̀ dáadáa ní Júdà lákòókò tí Ṣáfánì àti ìdílé rẹ̀ kópa nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé ní Jerúsálẹ́mù. Wọ́n máa ń lo òǹtẹ̀ láti sàmì sí ohun tó jẹ́ tẹni tàbí láti buwọ́ lùwé. Òkúta iyebíye, mẹ́táàlì, eyín erin tàbí gíláàsì ni wọ́n fi ń ṣe é. Wọ́n sábàá máa ń kọ orúkọ ẹni tó ni òǹtẹ̀ náà, orúkọ bàbá rẹ̀ àti lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, orúkọ oyè ẹni náà sára òǹtẹ̀ ọ̀hún.

Ọgọ́rọ̀ọ̀rún nǹkan táwọn Hébérù fi òǹtẹ̀ tẹ̀ sára àwọn ohun tí wọ́n fi amọ̀ ṣe láwọn èèyàn ti rí. Ọ̀jọ̀gbọ́n Nahman Avigad, tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ nípa àwọn àkọlé Hébérù ayé ọjọ́un, sọ pé: “Àwọn àkọlé ara òǹtẹ̀ nìkan ṣoṣo ni àkọsílẹ̀ Hébérù ìgbàanì tó dárúkọ àwọn èèyàn tá a mọ̀ nínú Bíbélì.” Ǹjẹ́ wọ́n tíì rí òǹtẹ̀ èyíkéyìí tórúkọ Ṣáfánì tàbí ti àwọn ará ilé rẹ̀ wà? Bẹ́ẹ̀ ni o, orúkọ Ṣáfánì àti ti ọmọ rẹ̀ Gemaráyà wà lára òǹtẹ̀ tó wà lójú ìwé 19 àti 21.

Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tún sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn mẹ́rin mìíràn nínú ìdílé rẹ̀ làwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú àwọn òǹtẹ̀ kan ń tọ́ka sí. Àwọn ni: Asaláyà baba Ṣáfánì; Áhíkámú ọmọ Ṣáfánì; Gemaráyà ọmọ Ṣáfánì; àti Gẹdaláyà tí àkọlé ara òǹtẹ̀ kan pè ní “alákòóso Ilé”. Wọ́n sọ pé Gẹdaláyà, ọmọ ọmọ Ṣáfánì ló ní láti ni ìkẹrin lára àwọn òǹtẹ̀ yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ Áhíkámù bàbá rẹ̀ ò sí níbẹ̀. Orúkọ oyè rẹ̀ tó wà lára òǹtẹ̀ náà fi hàn pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olóyè jàǹkàn-jàǹkàn nílùú lákòókò náà.

Ẹ̀kọ́ Wo La Lè Rí Kọ́ Lára Wọn?

Àpẹẹrẹ dáradára ni Ṣáfánì àti ìdílé rẹ̀ fi lélẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe fi ipò ńlá tí wọ́n wà ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn tòótọ́ àti fún wòlíì olóòótọ́ náà Jeremáyà! Àwa náà lè fi ohun ìní wa àti ipò wa ṣètìlẹ́yìn fún ètò àjọ Jèhófà àti àwọn tá a jọ ń jọ́sìn.

Kì í ṣe kíka Bíbélì déédéé nìkan, àmọ́ ṣíṣàyẹ̀wò rẹ̀ jinlẹ̀jinlẹ̀ àti dídi ojúlùmọ̀ àwọn ẹlẹ́rìí fún Jèhófà láyé ọjọ́hun, ìyẹn àwọn bíi Ṣáfánì àti ìdílé rẹ̀, ló ń gbéni ró tó sì ń fún ìgbàgbọ́ ẹni lókun. Àwọn náà wà lára “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí” tó pọ̀ gan-an, tá a lè fara wé àpẹẹrẹ wọn.—Hébérù 12:1.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ni Ṣáfánì á fi ju Jòsáyà lọ lóòótọ́ nítorí pé Áhíkámù tó jẹ́ ọmọ Ṣáfánì ti di àgbàlagbà nígbà tí Jòsáyà ṣì wà ní nǹkan bí ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n.—2 Àwọn Ọba 22:1-3, 11-14.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]

Húlídà—Wòlíì Obìnrin Tó Gbajúmọ̀

Nígbà tí Jòsáyà Ọba gbọ́ ohun tí wọ́n kà jáde látinú “ìwé òfin gan-an,” ó pàṣẹ pé kí Ṣáfánì àtàwọn ọkùnrin mẹ́rin mìíràn tí wọ́n wà nípò gíga lọ “wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà” nípa ìwé náà. (2 Àwọn Ọba 22:8-20) Ibo làwọn tá a rán níṣẹ́ yìí á ti lọ ṣèwádìí náà? Júdà ni Jeremáyà, gbogbo àwọn wòlíì àtàwọn tó kọ Bíbélì ń gbé lákòókò náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ibẹ̀ náà ni Náhúmù àti Sefanáyà pẹ̀lú ń gbé. Àmọ́, ọ̀dọ̀ Húlídà wòlíì obìnrin làwọn èèyàn yìí lọ.

Ìwé Jerusalem—An Archaeological Biography sọ pé: “Ohun kan tó gbàfiyèsí nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni pé kò sẹ́ni tó ka ọ̀rọ̀ ẹ̀yà akọ tàbí ẹ̀yà abo tó wà nínú ọ̀ràn yìí sí nǹkan bàbàrà. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò sẹ́ni tó kà á sí nǹkan bàbàrà pé ìgbìmọ̀ tó jẹ́ kìkì ọkùnrin mú Àkájọ ìwé Òfin lọ sọ́dọ̀ obìnrin-bìnrìn láti mọ ọ̀rọ̀ ẹni tó wà nínú rẹ̀. Nígbà tí obìnrin náà sì sọ fún wọn pé ọ̀rọ̀ Olúwa ni, kò sí ẹnikẹ́ni lára wọn tó bi í léèrè pé àṣẹ wo ló ní láti sọ bẹ́ẹ̀. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ sábà máa ń gbójú fo ìṣẹ̀lẹ̀ yìí dá nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa bí ipò àwọn obìnrin ṣe ṣe pàtàkì tó ní Ísírẹ́lì ìgbàanì.” Láìsí àní-àní, ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìhìn tí wọ́n rí gbà náà ti wá.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Ìlà Ìdílé Ṣáfánì

Méṣúlámù

Asaláyà

Ṣáfánì

↓ ↓ ↓ ↓

Áhíkámú Élásà Gemaráyà Jaasánáyà

↓ ↓

Gẹdaláyà Mikáyà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Gemaráyà àtàwọn èèyàn mìíràn bẹ Jèhóákímù pé kó má finá sun àkájọ ìwé tó gbà lọ́wọ́ Jeremáyà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìdílé Ṣáfánì ni Jaasánáyà ti wá, síbẹ̀ wọ́n rí i tó ń jọ́sìn òrìṣà nínú ìran

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Israel Antiquities Authority

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 21]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Israel Antiquities Authority