Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì 5:1-21

  • Gbígbé ibùgbé ọ̀run wọ̀ (1-10)

  • Iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́ (11-21)

    • Ẹ̀dá tuntun (17)

    • Ikọ̀ fún Kristi (20)

5  Nítorí a mọ̀ pé tí ilé wa ní ayé bá wó,*+ ìyẹn àgọ́ yìí, Ọlọ́run máa fún wa ní ilé míì, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́,+ tó jẹ́ ti ayérayé ní ọ̀run.  Nítorí à ń kérora nínú ilé* yìí lóòótọ́, ó sì ń wù wá gan-an pé ká gbé èyí tó wà fún wa* láti ọ̀run* wọ̀,+  kí ó lè jẹ́ pé, nígbà tí a bá gbé e wọ̀, a ò ní wà ní ìhòòhò.  Kódà, àwa tí a wà nínú àgọ́ yìí ń kérora, ìdààmú bò wá mọ́lẹ̀, torí pé a ò fẹ́ bọ́ èyí kúrò, àmọ́ a fẹ́ gbé èkejì wọ̀,+ kí ìyè lè gbé èyí tó lè kú mì.+  Ọlọ́run ni ẹni tó múra wa sílẹ̀ fún ohun yìí gan-an,+ ó fún wa ní ẹ̀mí láti fi ṣe àmì ìdánilójú ohun tó ń bọ̀.*+  Nítorí náà, a jẹ́ onígboyà nígbà gbogbo, a sì mọ̀ pé nígbà tí ilé wa ṣì wà nínú ara yìí, a kò sí lọ́dọ̀ Olúwa,+  nítorí à ń rìn nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa ohun tí à ń rí.  A jẹ́ onígboyà, ó sì tẹ́ wa lọ́rùn pé kí a má ṣe wà nínú ara, kí a sì fi ọ̀dọ̀ Olúwa ṣe ilé wa.+  Torí náà, bóyá a wà nílé pẹ̀lú rẹ̀ àbí a ò sí lọ́dọ̀ rẹ̀, ohun tí a fẹ́ ni pé kó tẹ́wọ́ gbà wá. 10  Nítorí gbogbo wa ló máa fara hàn* níwájú ìjókòó ìdájọ́ Kristi, kí kálukú lè gba èrè àwọn ohun tó ṣe nígbà tó wà nínú ara, ì báà jẹ́ rere tàbí búburú.*+ 11  Torí náà, nígbà tí a ti mọ ohun tí ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́, à ń yí àwọn èèyàn lérò pa dà, àmọ́ Ọlọ́run mọ̀ wá dáadáa.* Síbẹ̀, mo lérò pé ẹ̀rí ọkàn ẹ̀yin náà mọ̀ wá dáadáa.* 12  Kì í ṣe pé a tún ń dámọ̀ràn ara wa fún yín, àmọ́ à ń fún yín ní ohun tí á mú kí ẹ máa fi wá yangàn, kí ẹ lè rí nǹkan sọ fún àwọn tó ń fi ohun tó wà lóde yangàn,+ tí kì í ṣe ohun tó wà nínú ọkàn. 13  Tí orí wa bá yí,+ nítorí Ọlọ́run ni; tí orí wa bá pé, nítorí tiyín ni. 14  Nítorí ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di dandan fún wa, torí ohun tí a ti pinnu nìyí, pé ọkùnrin kan kú fún gbogbo èèyàn;+ nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo wọn ti kú. 15  Ó sì kú fún gbogbo wọn kí àwọn tó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́,+ bí kò ṣe fún ẹni tó kú fún wọn, tí a sì gbé dìde. 16  Nítorí náà, láti ìsinsìnyí lọ, a ò fojú tara wo ẹnikẹ́ni mọ́.+ Bí a tilẹ̀ ń fojú tara wo Kristi tẹ́lẹ̀, ó dájú pé a ò fojú yẹn wò ó mọ́.+ 17  Nítorí náà, tí ẹnikẹ́ni bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi, ó ti di ẹ̀dá tuntun; àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ;+ wò ó! àwọn ohun tuntun ti dé. 18  Àmọ́ ohun gbogbo wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tó tipasẹ̀ Kristi mú wa pa dà bá ara rẹ̀ rẹ́,+ tó sì fún wa ní iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́,+ 19  ìyẹn ni pé Ọlọ́run mú ayé kan pa dà bá ara rẹ̀ rẹ́ nípasẹ̀ Kristi,+ kò ka àwọn àṣemáṣe wọn sí wọn lọ́rùn,+ ó sì fi ọ̀rọ̀ ìpadàrẹ́ sí ìkáwọ́ wa.+ 20  Nítorí náà, a jẹ́ ikọ̀+ tó ń dípò fún Kristi,+ bíi pé Ọlọ́run ń pàrọwà nípasẹ̀ wa. Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń dípò fún Kristi, a bẹ̀bẹ̀ pé: “Ẹ pa dà bá Ọlọ́run rẹ́.” 21  Ẹni tí kò mọ ẹ̀ṣẹ̀+ ni ó sọ di ẹ̀ṣẹ̀* fún wa, kí a lè di olódodo lójú Ọlọ́run nípasẹ̀ rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “yọ́.”
Tàbí “ibùgbé.”
Tàbí “gbé ibùgbé wa.”
Tàbí “ibùgbé wa ọ̀run.”
Tàbí “àsansílẹ̀; ìdánilójú (ẹ̀jẹ́) ohun tó ń bọ̀.”
Tàbí “fara hàn kedere.”
Tàbí “ibi.”
Tàbí “a ò pa mọ́ fún Ọlọ́run.”
Tàbí “a ò pa mọ́ fún ẹ̀rí ọkàn ẹ̀yin náà.”
Tàbí “ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.”