Jeremáyà 43:1-13

  • Àwọn èèyàn ṣàìgbọràn, wọ́n lọ sí Íjíbítì (1-7)

  • Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Jeremáyà ní Íjíbítì (8-13)

43  Nígbà tí Jeremáyà parí gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run wọn ní kó sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà, ìyẹn gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run wọn fi rán an sí wọn,  Asaráyà ọmọ Hóṣáyà àti Jóhánánì+ ọmọ Káréà pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin tó jẹ́ agbéraga wá sọ fún Jeremáyà pé: “Irọ́ lò ń pa! Jèhófà Ọlọ́run wa kò rán ọ kí o sọ pé, ‘Ẹ má lọ sí Íjíbítì láti máa gbé ibẹ̀.’  Bárúkù+ ọmọ Neráyà ló ń dẹ ọ́ sí wa láti fi wá lé ọwọ́ àwọn ará Kálídíà, kí wọ́n lè pa wá tàbí kí wọ́n kó wa lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì.”+  Torí náà, Jóhánánì ọmọ Káréà àti gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun pẹ̀lú gbogbo àwọn èèyàn náà kò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà pé kí wọ́n dúró sí ilẹ̀ Júdà.  Dípò bẹ́ẹ̀, Jóhánánì ọmọ Káréà àti gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun kó gbogbo àṣẹ́kù Júdà tó pa dà láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí a fọ́n wọn ká sí, láti máa gbé ní ilẹ̀ Júdà.+  Wọ́n kó àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọbìnrin ọba, pẹ̀lú gbogbo àwọn* tí Nebusarádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́ fi sílẹ̀ sọ́dọ̀ Gẹdaláyà+ ọmọ Áhíkámù+ ọmọ Ṣáfánì,+ wọ́n sì tún mú wòlíì Jeremáyà àti Bárúkù ọmọ Neráyà.  Wọ́n wọ ilẹ̀ Íjíbítì, nítorí wọn kò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà, wọ́n sì lọ títí dé Tápánẹ́sì.+  Nígbà náà, Jèhófà bá Jeremáyà sọ̀rọ̀ ní Tápánẹ́sì, ó ní:  “Fi ọwọ́ rẹ kó òkúta ńlá, kí o kó wọn pa mọ́ sí ibi onípele tí wọ́n fi bíríkì ṣe tó wà ní ẹnu ọ̀nà ilé Fáráò ní Tápánẹ́sì níṣojú àwọn ọkùnrin Júù, kí o sì fi amọ̀ bò wọ́n mọ́ ibẹ̀. 10  Kí o wá sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Wò ó, màá ránṣẹ́ pe Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, ìránṣẹ́ mi,+ màá sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ lé orí àwọn òkúta tí mo fi pa mọ́ yìí, á sì na àgọ́ ìtẹ́ rẹ̀ lé wọn lórí.+ 11  Ó máa wọlé, á sì kọ lu ilẹ̀ Íjíbítì.+ Ẹni tó bá yẹ fún àjàkálẹ̀ àrùn ni àjàkálẹ̀ àrùn máa pa, ẹni tó bá yẹ fún oko ẹrú ló máa lọ sí oko ẹrú, ẹni tó bá sì yẹ fún idà ni idà máa pa.+ 12  Màá sọ iná sí ilé* àwọn ọlọ́run Íjíbítì, ọba náà á sun wọ́n,+ á sì kó wọn lọ sí oko ẹrú. Á da ilẹ̀ Íjíbítì bora bí olùṣọ́ àgùntàn ti ń da ẹ̀wù bo ara rẹ̀, á sì jáde kúrò níbẹ̀ ní àlàáfíà.* 13  Á fọ́ àwọn òpó* Bẹti-ṣémẹ́ṣì* tó wà nílẹ̀ Íjíbítì sí wẹ́wẹ́, á sì dáná sun ilé* àwọn ọlọ́run Íjíbítì.”’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “àwọn tẹ́ńpìlì.”
Tàbí “láìséwu.”
Tàbí “òpó ìrántí onígun mẹ́rin.”
Tàbí “Ilé (Tẹ́ńpìlì) Oòrùn,” ìyẹn Hẹlipólísì.
Tàbí “àwọn tẹ́ńpìlì.”