Jeremáyà 41:1-18

  • Íṣímáẹ́lì pa Gẹdaláyà (1-10)

  • Íṣímáẹ́lì fẹsẹ̀ fẹ bó ṣe rí Jóhánánì (11-18)

41  Ní oṣù keje, Íṣímáẹ́lì+ ọmọ Netanáyà ọmọ Élíṣámà, tó wá láti ìdílé ọba,* tó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèyàn sàràkí-sàràkí ọba, wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá míì sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ọmọ Áhíkámù ní Mísípà.+ Bí wọ́n ṣe ń jẹun lọ́wọ́ ní Mísípà,  Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tó wà pẹ̀lú rẹ̀ dìde, wọ́n sì fi idà pa Gẹdaláyà ọmọ Áhíkámù ọmọ Ṣáfánì. Nípa bẹ́ẹ̀, ó pa ẹni tí ọba Bábílónì yàn ṣe olórí ilẹ̀ náà.  Íṣímáẹ́lì tún pa gbogbo àwọn Júù tó wà pẹ̀lú Gẹdaláyà ní Mísípà àti àwọn ọmọ ogun Kálídíà tó wà níbẹ̀.  Ní ọjọ́ kejì lẹ́yìn tí wọ́n ti pa Gẹdaláyà, kí ẹnikẹ́ni tó mọ̀ nípa rẹ̀,  ọgọ́rin (80) ọkùnrin wá láti Ṣékémù,+ láti Ṣílò+ àti láti Samáríà.+ Wọ́n fá irùngbọ̀n wọn, wọ́n ti fa ẹ̀wù wọn ya, wọ́n sì ti kọ ara wọn lábẹ,+ ọrẹ ọkà àti oje igi tùràrí+ sì wà ní ọwọ́ wọn tí wọ́n mú wá sí ilé Jèhófà.  Torí náà, Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà jáde kúrò ní Mísípà láti lọ pàdé wọn, ó ń sunkún bó ṣe ń rìn lọ. Nígbà tó pàdé wọn, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ọmọ Áhíkámù.”  Ṣùgbọ́n bí wọ́n ṣe wọnú ìlú náà, Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà àti àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ pa wọ́n, ó sì sọ òkú wọn sínú kòtò omi.  Ṣùgbọ́n mẹ́wàá lára àwọn ọkùnrin náà sọ fún Íṣímáẹ́lì pé: “Má pa wá, nítorí pé a ní àlìkámà,* ọkà bálì, òróró àti oyin ní ìpamọ́ nínú oko.” Torí náà, ó dá wọn sí, kò sì pa wọ́n pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn.  Íṣímáẹ́lì wá sọ òkú gbogbo àwọn ọkùnrin tó pa sínú kòtò omi ńlá kan tí Ọba Ásà ṣe nítorí Ọba Bááṣà ti Ísírẹ́lì.+ Inú kòtò omi yìí ni Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà kó òkú àwọn tó pa sí títí ó fi kún. 10  Íṣímáẹ́lì mú gbogbo àwọn tó kù ní Mísípà lẹ́rú,+ títí kan àwọn ọmọbìnrin ọba àti gbogbo èèyàn tó ṣẹ́ kù ní Mísípà, àwọn tí Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ ti fi sí ìkáwọ́ Gẹdaláyà+ ọmọ Áhíkámù. Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà mú wọn lẹ́rú, ó sì lọ láti sọdá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì.+ 11  Nígbà tí Jóhánánì+ ọmọ Káréà àti gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun tó wà pẹ̀lú rẹ̀ gbọ́ gbogbo ohun búburú tí Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà ti ṣe, 12  wọ́n kó gbogbo ọkùnrin, wọ́n sì lọ láti bá Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà jà, wọ́n rí i lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi ńlá* tó wà ní Gíbíónì. 13  Inú gbogbo àwọn èèyàn tó wà pẹ̀lú Íṣímáẹ́lì dùn nígbà tí wọ́n rí Jóhánánì ọmọ Káréà àti gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun tó wà pẹ̀lú rẹ̀. 14  Ni gbogbo àwọn tí Íṣímáẹ́lì ti mú lẹ́rú láti Mísípà bá yíjú pa dà,+ wọ́n sì bá Jóhánánì ọmọ Káréà pa dà. 15  Àmọ́ Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà àti mẹ́jọ lára àwọn ọkùnrin rẹ̀ sá mọ́ Jóhánánì lọ́wọ́, wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì. 16  Jóhánánì ọmọ Káréà àti gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun tó wà pẹ̀lú rẹ̀ kó àwọn èèyàn tó ṣẹ́ kù ní Mísípà, ìyẹn àwọn tó gbà sílẹ̀ lọ́wọ́ Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà, lẹ́yìn tó ti pa Gẹdaláyà+ ọmọ Áhíkámù. Wọ́n kó àwọn ọkùnrin, àwọn ọmọ ogun, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé àti àwọn òṣìṣẹ́ ààfin pa dà dé láti Gíbíónì. 17  Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lọ, wọ́n sì dé sí ibùwọ̀ Kímúhámù tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ láti lọ sí Íjíbítì+ 18  torí àwọn ará Kálídíà. Ẹ̀rù wọn ń bà wọ́n, nítorí Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà ti pa Gẹdaláyà ọmọ Áhíkámù, ẹni tí ọba Bábílónì yàn ṣe olórí ilẹ̀ náà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “látinú èso ìjọba náà.”
Tàbí “wíìtì.”
Tàbí kó jẹ́, “odò ńlá.”