Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Oúnjẹ Tó Gbòdì Lára Àtèyí Tí Kò Báni Lára Mu—Ṣó Yàtọ̀ Síra??

Oúnjẹ Tó Gbòdì Lára Àtèyí Tí Kò Báni Lára Mu—Ṣó Yàtọ̀ Síra??

Emily: “Bí mo ṣe ń jẹun lọ́wọ́, ẹnu bẹ̀rẹ̀ sí í yún mi, ahọ́n mí sì ń wú. Mo fi oúnjẹ sílẹ̀, síbẹ̀ ará ń ni mí, ọkàn mi ò sì balẹ̀ mọ́ torí mi ò lè mí délẹ̀ dáadáa. Kí n tó ṣẹ́jú pẹ́, ọrùn àti apá mi ti pọ́n, ó sì ń yún mi gidigidi. Mo wò ó pé kọ́rọ̀ yìí tó di nǹkan míì, àfi kí n tètè gba ilé ìwòsàn lọ!”

KÒ SÍ oúnjẹ táwọn kan ò lè jẹ. Àmọ́ fún àwọn ẹlòmíì, àwọn oúnjẹ kan wà tó máa ń gbòdì lára wọn, wọ́n ka irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ sí “ọ̀tá” wọn. Àpẹẹrẹ ẹnì kan ni Emily tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ yẹn. Ohun tó ṣe Emily tí oúnjẹ fi gbòdì lára rẹ̀ yìí ni àwọn oníṣègùn ń pè ní anaphylaxis, ipò tó sì léwu gan-an ni. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo èèyàn ni ipò wọn máa ń léwu bíi ti Emily.

Láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ìròyìn nípa àwọn tí oúnjẹ gbòdì lára wọn tàbí tí kò bá lára mu túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Àmọ́, ìwádìí fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn tó rò pé àwọn ní ìṣòro yìí ni kò tíì ṣàyẹ̀wò nílé ìwòsàn láti mọ̀ bóyá àwọn ní in.

Ohun Tó Máa Ń Mú Oúnjẹ Gbòdì Lara Ẹni

Nínú ìwé The Journal of the American Medical Association, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan tó ń jẹ́ Dr. Jennifer J. Schneider Chafen sọ pé: “Kò tíì sí àlàyé kan pàtó tó ṣe kedere fún bí oúnjẹ ṣe ń gbòdì lára èèyàn.” Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ gbà pé àwọn èròjà tó ń dènà àrùn nínú ara ló máa ń mú kí oúnjẹ gbòdì lára àwọn kan.

Fún àwọn tí oúnjẹ ń gbòdì lára wọn, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ni pé èròjà protein tó wà nínú oúnjẹ tí wọ́n jẹ kò bá wọn lára mu. Torí pé àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ń gbógun ti àrùn nínú ara wọn ti ka irú èròjà protein yẹn sí ohun tó lè ṣàkóbá fún wọn. Bí irú èròjà protein bẹ́ẹ̀ bá wọnú ara wọn, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni sẹ́ẹ̀lì tó ń dènà àrùn á tú èròjà tí wọ́n pè ní Immunoglobulin E (IgE) jáde láti lẹ̀ mọ́ èròjà protein náà tí á sì gbógun tì í. Tí ẹni náà bá tún jẹ irú oúnjẹ yẹn lọ́jọ́ míì, àwọn èròjà tó tú jáde nígbà àkọ́kọ́ á wá tú kẹ́míkà kan jáde tí wọ́n pè ní histamine, èyí sì lè fa ọ̀pọ̀ ìnira.

Iṣẹ́ bàǹtàbanta ni histamine yìí ń ṣe lára. Àmọ́ fún àwọn ìdí kan tí kò yéni, ara àwọn míì máa ń tú kẹ́míkà yìí jáde tí wọn bá jẹ àwọn oúnjẹ kan tó ní èròjà protein kan tí ara wọn kọ̀. Èyí ló máa ń mú kí oúnjẹ náà gbòdì lára wọn.

Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà àkọ́kọ́ tẹ́nì kan bá jẹ irú oúnjẹ kan, ó lè má gbòdì lára rẹ̀, àmọ́ tó bá jẹ ẹ́ nígbà míì, ó lè gbòdì lára rẹ̀.

Ohun Tó Lè Mú Kí Oúnjẹ Má Báni Lára Mu

Bí èròjà Protein inú oúnjẹ ṣe máa ń mú kí oúnjẹ gbòdì lára àwọn kan, bẹ́ẹ̀ ló ṣe jẹ́ pé èròjà inú oúnjẹ kan lè má bá àwọn míì lára mu. Ìyàtọ̀ tó kàn wà níbẹ̀ ni pé kì í ṣe sẹ́ẹ̀lì tó ń gbógun ti àrùn ló ń fà á tí àwọn oúnjẹ kan kì í fi í bá àwọn míì lára mu. Ó sábà máa ń jẹ́ pé òòlọ̀ inú ni kò lọ oúnjẹ náà bó ṣe yẹ tàbí kó jẹ́ pé àwọn kẹ́míkà inú oúnjẹ yẹn lágbára jù tàbí kí ara má ní kẹ́míkà tó lè mú kí irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ dà nínú ara. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè mu mílíìkì, kí inú rẹ̀ sì dàrú, ohun tó fà á ni pé ara ẹni náà kò ní kẹ́míkà tó máa ń mú kí ṣúgà tó wà nínú mílíìkì dà nínú ara.

Ìgbà àkọ́kọ́ tí èèyàn bá jẹ oúnjẹ tí kò bá a lára mu ló máa ti mọ̀ ọ́n lára. Ó lè jẹ́ pé bí oúnjẹ tó jẹ ṣe pọ̀ tó wà lára ohun tó fà á. Ó ṣeé ṣe kí irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ má yọ ọ́ lẹ́nu ká ní ìwọ̀nba ló jẹ́. Èyí yàtọ̀ sí bó ṣe máa ń ṣe ẹni tí oúnjẹ máa ń gbòdì lára rẹ̀, kódà kó jẹ́ ṣíbí kan péré ló bù nínú oúnjẹ tó lè gbòdì lára rẹ̀, ó lẹ̀ gbẹ̀mí ẹni náà tí kò bá múra.

Báwo Lèèyàn Ṣe Lè Dá Èyí Tó Ń Ṣe Òun Mọ̀?

Tí oúnjẹ kan bá ń gbòdì lára ẹni, díẹ̀ lára àwọn àmì tẹ́ni náà máa rí rèé: ara rẹ̀ á pọ́n á sì máa yún un; ojú, ahọ́n àti ọ̀nà ọ̀fun rẹ̀ á máa wú; èébì lè máa gbé e tàbí kó máa bì tàbí kó máa yàgbẹ́ gbuuru; kódà ó lè le débi pé ìfúnpá rẹ̀ á lọọlẹ̀, kí òòyì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ tàbí kó dákú tàbí kí ọkàn rẹ̀ dáṣẹ́ dúró. Láàárín ìṣẹ́jú akàn, nǹkan lè yíwọ́ kí ipò ẹni náà sì burú gan-an.

Kò sí oúnjẹ tí kò lè gbòdì lára èèyàn. Àmọ́ àwọn oúnjẹ tó sábà máa ń gbòdì lára ni àwọn oúnjẹ kéékèèké bíi mílíìkì, ẹyin, ẹja, edé, alákàn, ẹ̀pà, ẹ̀wà sóyà, ẹ̀pà inú èso àti wíìtì. Ìwádìí fi hàn pé àìsàn yìí lè ṣe ọmọdé ó sì lè ṣe àgbà. Kódà, àwọn ọmọ lè jogún àìsàn yìí lára àwọn òbí wọn. Síbẹ̀, wọ́n lè borí ẹ̀, kó má sì ṣe wọ́n mọ́.

Ṣùgbọ́n, àwọn ohun tá a sọ yìí yàtọ̀ sí bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ẹni tí oúnjẹ kò bá lára mu. Lára àwọn àmì téèyàn á fi mọ̀ tí oúnjẹ kò bá báni lára mu ni pé: inú lè máa runni, kéèyàn máa só, kí àyà máa tani, kí ara máa yúnni, kí orí máa fọ́ni tàbí kí inú máa kanni tàbí kó máa rẹni ṣáá. Àwọn oúnjẹ tí kì í sábà bá àwọn kan lára mu ni kéèkì, wàrà, bọ́tà, ẹyin, mílíìkì, wíìtì, ọtí àti yeast.

Bó O Ṣe Lè Ṣàyẹ̀wò Ara Rẹ Tàbí Tọ́jú Ara Rẹ

Tó o bá rí i pé àwọn oúnjẹ kan máa ń gbòdì lára rẹ tàbí pé kò bá ẹ lára mu, á dáa kó o lọ ṣàyẹ̀wò nílé ìwòsàn. Tó o bá dá tinú ẹ ṣe tàbí tó o kọ àwọn oúnjẹ kan sílẹ̀ pé o kò ní máa jẹ wọ́n láìjẹ́ pé ilé ìwòsàn ni wọ́n ti sọ fún ẹ bẹ́ẹ̀, èyí lè ṣàkóbá fún ìlera rẹ torí pé ńṣe lò ń fi àwọn èròjà aṣaralóore tí ara nílò du ara rẹ.

Tí àwọn oúnjẹ kan bá gbòdì lára ẹni tàbí tí kò báni lára mu, àfi kéèyàn má jẹ irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ mọ́, yàtọ̀ síyẹn kò dájú pé ọ̀nà kan pàtó wà tí wọ́n fi ń mú àìsàn yìí kúrò. * Àmọ́ tó bá jẹ́ pé bó ṣe ń ṣe ẹni náà kò fi bẹ́ẹ̀ le, ẹni náà lè dín bó ṣe ń jẹ oúnjẹ yẹn kù, kó máa jẹ ẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Láwọn ìgbà míì ṣá, ẹni náà lè pinnu pé òun kò ní jẹ irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ mọ́, tàbí kó jẹ́ kó ṣe díẹ̀ kó tó tún jẹ ẹ́. Ṣùgbọ́n bó bá ṣe le tó ló máa pinnu ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa ṣe.

Torí náà, tí oúnjẹ kan bá ń gbòdì lára rẹ tàbí tí kò bá ẹ lára mu, má jáyà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ní irú ìṣòro yìí tí wọ́n sì kọ́ bí wọ́n á ṣe máa tọ́jú ara wọn. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, wọ́n ń gbádùn oríṣiríṣi oúnjẹ aládùn tó ń ṣara wọn lóore.

^ ìpínrọ̀ 19 Àwọn tí oúnjẹ bá ń gbòdì lára wọn máa ń mú oògùn àti abẹ́rẹ́ kan dání tí máa ń gún fúnra wọn tọ́rọ̀ bá di pàjáwìrì, èyí máa ń jẹ́ kí ọkàn wọn ṣiṣẹ́ dáadáa. Àwọn dókítà kán sọ pé ó dáa kí àwọn ọmọdé tó ní àìsàn yìí máa so àmì ìdánimọ̀ kan mọ́ ọwọ́ tàbí aṣọ wọn tí àwọn olùkọ́ tàbí ẹni tó ń tọ́jú wọn máa fi mọ irú ipò tí wọ́n wà.