Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Ọrùn Èèrà

Ọrùn Èèrà

ÌYÀLẸ́NU gbáà ló jẹ́ fún àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ nígbà tí wọ́n rí bí àwọn èèrà tín-tìn-tín ṣe ń gbé nǹkan tó wúwo jù wọ́n lọ. Kí wọ́n lè mọ bí èèrà ṣe ń rí agbára rẹ̀, àwọn onímọ̀ èrọ ní Ohio State University lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, lo ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà láti fi ṣe èèrà, gbogbo ẹ̀yà ara àti gbogbo ohun tí èèrà gidi lè ṣe náà ni èèrà orí kọ̀ǹpútà yìí ń ṣe. Ohun tí wọ́n fi ṣe èèrà náà jẹ́ kí wọ́n lè rí bó ṣe máa ń sakun nígbà tó bá ń gbé nǹkan.

Ibi tó gbàfiyèsí jù lára èèrà ni ọrùn rẹ̀, torí pé ibẹ̀ ni gbogbo ẹrù tó bá fẹnu gbé máa ń sinmi lé. Apá ibi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ lọ́rùn èèrà ló so orí rẹ̀ pọ̀ mọ́ ara rẹ̀, bí ìgbà téèyàn bá fi ìka ọwọ́ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá há ara wọn. Ọ̀kan lára àwọn olùṣèwádìí náà sọ pé: “Ọ̀nà àrà tí ibi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó wà lọ́rùn èèrà gbà so pọ̀ mọ ara rẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an. Òun ni kì í jẹ́ kí ọrùn wọ èèrà tó bá gbé nǹkan tó wúwo. Ọ̀nà àgbàyanu tí apá ibi tó fẹ́lẹ́ àti apá ibi tó le lára èèrà gbà lẹ̀ pọ̀ ló jẹ́ kí ọrùn rẹ̀ lágbára, tí kì í sì í jẹ́ kí ọrùn náà ré bọ́ nígbà tó bá gbé nǹkan ńlá.” Àwọn olùṣèwádìí sọ pé táwọn bá túbọ̀ lóye bí ọrùn èèrà ṣe ń ṣiṣẹ́, èyí máa mú kí ìtẹ̀síwájú bá ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ń ṣe ẹ̀rọ rọ́bọ́ọ̀tì.

Kí Lèrò Rẹ? Ṣé bí ọrùn èèrà ṣe lágbára láti gbé ohun to wúwo kàn ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?