Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

‘Ìhìn Rere fún Gbogbo Èèyàn ní Èdè Wọn’

Èdè tí wọ́n ń sọ láyé báyìí jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti ọgọ́rùn-ún méje (6,700). Torí náà, kí ìhìn rere ìhìn rere tó wà nínú Bíbélì tó lè délé-dóko, àfi ká ṣiṣẹ́ ìtúmọ̀. Tó o bá wo fídíò yìí, wàá rí ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn láyé lè gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.