Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | OHUN MÁRÙN-ÚNTÓ MÁA MÚ KÍ ÌLERA RẸ DÁRA SÍ I

Ohun Tó Máa Mú Kí Ìlera Rẹ Dára Sí I

Ohun Tó Máa Mú Kí Ìlera Rẹ Dára Sí I

GBOGBO èèyàn ló gbà pé ìlera loògùn ọ̀rọ̀, torí náà kò sẹ́ni tó fẹ́ ṣàìsàn. Ìdí ni pé ìrora ni àìsàn máa ń fà, ó sì máa ń náni lówó. Yàtọ̀ sí pé ara á máa ni ẹ́, o kò ní lè lọ ibi iṣẹ́ débi tí wàá fi rówó gbọ́ bùkátà. Tó o bá sì jẹ́ ọmọléèwé, ara rẹ lè má gbé àtilọ sí ilé ìwé. Ó sì tún lè gba pé kí ẹnì kan dúró tì ẹ́ nílé, wàá sì tún ná owó gọbọi láti tọ́jú ara rẹ.

Òwe kan sọ pé, igi ganganran má gùn mi lójú, òkèèrè la ti í lọ̀ ọ́. Òótọ́ ni pé àwọn àìsàn kan wà tí a ò lè yẹra fún pátápátá, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nǹkan la lè ṣe láti dènà àìsàn. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun márùn-ún tá a lè ṣe kí ìlera wa lè sunwọ̀n sí i.

1 JẸ́ ONÍMỌ̀Ọ́TÓTÓ

ÀJỌ kan tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìlera, ìyẹn Mayo Clinic sọ pé, “ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà dènà àrùn” ni pé ká máa fọ ọwọ́ wa déédéé. Tí èèyàn bá ń fi ọwọ́ tó dọ̀tí gbo ojú tàbí imú, ó lè jẹ́ kí èèyàn tètè kó àwọn àrùn bíi kàtá. Ṣùgbọ́n tá a bá ń fọ ọwọ́ wa déédéé, èyí máa jẹ́ ká lè dènà àìsàn. Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ìmọ́tótó ló lè ṣẹ́gun àrùn gbogbo, téèyàn bá jẹ́ onímọ̀ọ́tótó, ó máa jẹ́ kéèyàn lè dènà àwọn àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí, irú bíi òtútù àyà àti ìgbẹ́ gbuuru. Lọ́dọọdún, àwọn àìsàn yìí máa ń ṣekú pa ohun tó lé ní mílíọ̀nù méjì àwọn ọmọ tí kò tíì pé ọdún márùn-ún. Kódà, tí èèyàn bá ń fọwọ́ déédéé, ó lè dín bí àrùn Ebola ṣe ń gbèèràn kù.

Àwọn ìgbà kan wà tó pọn dandan pé ká fọ ọwọ́ wa tí a kò bá fẹ́ kó àrùn, tí a ò sì fẹ́ kó àrùn ran àwọn ẹlòmíì. Àwọn ìgbà tá a gbọ́dọ̀ fọ ọwọ́ wa rèé:

 • Lẹ́yìn tá a bá ṣe ìgbọ̀nsẹ̀.

 • Tá a bá pààrọ̀ ìtẹ́dìí ọmọ tàbí ṣan ìdí ọmọ.

 • Ká tó fọ ojú egbò àti lẹ́yìn tá a bá fọ̀ ọ́ tán.

 • Ká tó lọ sọ́dọ̀ ẹni tó ń ṣàìsàn àti nígbà tá a bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

 • Ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í dáná, lẹ́yìn tá a bá dáná tán àti ká tó jẹun.

 • Tá a bá sín, tá a bá fọwọ́ bo ẹnu wa nígbà táa húkọ́ tàbí tá a fọn imú.

 • Lẹ́yìn tá a bá fọwọ́ kan ẹranko tàbí ìgbẹ́ ẹran.

 • Lẹ́yìn tá a bá dalẹ̀ nù.

Máa rí i dájú pé ò ń fọ ọwọ́ rẹ mọ́ tónítóní ní gbogbo ìgbà. Ìwádìí fi hàn pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń lo ilé ìtura tó wà fún gbogbo gbòò kì í fọ ọwọ́ wọn tí wọ́n bá ṣe tán, àwọn míì kì í sì fọ̀ ọ́ mọ́. Báwo ló ṣe yẹ kó o máa fọ ọwọ́ rẹ?

 • Bú omi tó mọ́ sí ọwọ́, kó o sì fi ọṣẹ sí i.

 • Fi ọwọ́ méjèèjì gbo ara wọn títí tí ọṣẹ náà á fi hó, fọ abẹ́ èékánná, àtàǹpàkò, ẹ̀yìn ọwọ́ àti àárín àwọn ìka rẹ.

 • Fi ọwọ́ rẹ gbo ara wọn fún nǹkan bí ààbọ̀ ìṣẹ́jú.

 • Kó o wá fi omi tó mọ́ fọ ọwọ́ rẹ. Ṣùgbọ́n o, ńṣe ni kó o bu omi náà sí ọwọ́, má ṣe fọ ọwọ́ sínú omi tó wà nínú ike ìṣanwọ́.

 • Lẹ́yìn náà, fi aṣọ ìnuwọ́ tó mọ́ nu ọwọ́ rẹ.

Àwọn ohun tá a sọ yìí kò fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan, àmọ́ ó lè dènà àrùn, kó sì gba ẹ̀mí wa là.

2 MÁA LO OMI TÓ MỌ́

NÍ Ọ̀PỌ̀ ibi, ara iṣẹ́ ilé ni pípọn omi sílé. Àmọ́, rírí omi tó mọ́ lè di ìṣòro níbikíbi láyé. Ìdí ni pé, nígbà tí ìjábá bá ṣẹlẹ̀, irú bí omíyalé, ó lè ṣòro láti rí omi tó mọ́, páìpù tó gbé omi wọ ìlú sì lè bẹ́ tàbí kí nǹkan míì ṣẹlẹ̀. Tí èèyàn bá ń lo omi tí kò mọ́ tàbí omi tí wọn ò tọ́jú dáadáa, ó lè fa àrùn kọ́lẹ́rà, ìgbẹ́ gbuuru, ibà jẹ̀funjẹ̀fun, àrùn mẹ́dọ̀wú àtàwọn àrùn míì. Wọ́n fojú bù ú pé, nǹkan bíi bílíọ̀nù kan àti mílíọ̀nù méje (1.7 bílíọ̀nù) èèyàn ló máa ń kó àìsàn ìgbẹ́ gbuuru lọ́dọọdún, torí pé wọ́n ń mu omi tí kò mọ́.

Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè ṣe láti dènà àìsàn

Àwọn èèyàn sábà máa ń kó àrùn kọ́lẹ́rà tí wọ́n bá ṣèèṣì mu omi tàbí tí wọ́n jẹ oúnjẹ tí ìgbẹ́ tàbí ìtọ̀ ẹni tó ní àrùn náà ti kàn. Kí lo lè ṣe láti dènà àrùn yìí àti àwọn àrùn míì téèyàn lè kó látàrí lílo omi tí kò mọ́, pàápàá lẹ́yìn tí ìjábá bá wáyé?

 • Omi tó mọ́ ni kó o máa lò ní gbogbo ìgbà. Ó lè jẹ́ omi ìjọba, omi inú ọ̀rá tàbí omi inú ike láti iléeṣẹ́ tó ń ta omi. Rí i dájú pé omi tó mọ́ lò ń mu, lo fi ń fọ eyín, lo fi ń ṣe omi dídì ìyẹn búlọ́ọ̀kù tí wọ́n fi omi tútù ṣe, lo fi ń fọ oúnjẹ àti abọ́, tó o sì fi ń dáná.

 • Tó o bá kíyè sí i pé páìpù omi rẹ ti bẹ́ níbì kan, se omi náà kó o tó lò ó tàbí kó o fi kẹ́míkà apakòkòrò inú omi sí i.

 • Tó o bá ń lo kẹ́míkà apakòkòrò èyíkéyìí, rí i dájú pé o tẹ̀ lé ìtọ́ni tí wọ́n lẹ̀ mọ́ ara ike kẹ́míkà náà.

 • Máa lo asẹ́ omi tó dáa tó bá wà lágbègbè rẹ.

 • Tí kò bá sí kẹ́míkà apakòkòrò tó ṣe é fi sínú omi ní àdúgbò rẹ, o lè lo bleach, ìyẹn kẹ́míkà kan tí wọ́n fi ń fọ aṣọ funfun. Fi ẹ̀kán bleach méjì sínú lítà omi kan, mì í pọ̀ dáadáa, kó o sì jẹ́ kó silẹ̀ fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú kó o tó lò ó.

 • Tọ́jú omi tó o bá ti sẹ́ sínú ike tó ní ọmọrí, kí kòkòrò má baà tún pa dà wọnú rẹ̀.

 • Rí i dájú pé àwọn ike ìbomi rẹ mọ́.

 • Má ṣe fi ọwọ́ ìdọ̀tí di ike omi mú, má sì ki ọwọ́ bọ inú omi mímu.

3 MÁA ṢỌ́ OHUN TÓ Ò Ń JẸ

OÚNJẸ lọ̀rẹ́ àwọ̀. Ìyẹn ni pé tó o bá ń jẹ oúnjẹ aṣaralóore, ìlera rẹ máa dára sí i. Máa ṣọ́ ìwọ̀n iyọ̀, ọ̀rá àti ṣúgà tó ò ń jẹ, má sì jẹ àjẹkì. Máa jẹ onírúurú èso àti ewébẹ̀, má sì máa jẹ oríṣi oúnjẹ kan ní gbogbo ìgbà. Tó o bá fẹ́ ra oúnjẹ sílé, rí i dájú pé èyí tó jẹ́ ojúlówó tí àwọn èròjà aṣaralóore inú rẹ̀ ṣì pé lo rà. Èyí sàn ju àwọn tí wọ́n ti yọ àwọn èròjà inú rẹ̀. Láfikún sí i, ìwọ̀nba ẹran, ẹyin àti adìyẹ ni kó o máa jẹ, tó bá sì ṣeé ṣe, máa jẹ ẹja lóòrèkóòrè. Bákan náà, o tún lè rí àwọn èròjà aṣaralóore nínú àwọn ewébẹ̀.

Tó o bá ń jẹ ṣúgà àti ọ̀rá jù, ó lè mú kó o sanra jọ̀kọ̀tọ̀. Kí èyí má baà ṣẹlẹ̀ sí ẹ, máa mu omi dípò àwọn ohun mímú ẹlẹ́rìndòdò. Kàkà kó o máa jẹ́ ìpápánu oníṣúgà, á dáa kó o máa jẹ èso. Bákan náà, rọra máa jẹ àwọn nǹkan bí sọ́sééjì, ẹran, bọ́tà, kéèkì, wàràkàṣì àti bisikíìtì. Dípò tí wàá fi máa fi òróró tí ọ̀rá pọ̀ nínú rẹ̀ dáná, á sàn kó o lò èyí tí kò ní ọ̀rá rárá.

Tó o bá ń jẹ iyọ̀ jù, ó lè fa ẹ̀jẹ̀ ríru. Tó o bá ní ìṣòro yìí, ó máa dáa kó o dín iyọ̀ tó ò ń jẹ kù. Dípò tí wàá fi gbọ́n iyọ̀ sínú oúnjẹ, o lè lo àwọn èròjà amóúnjẹ dùn míì.

Bó o ṣe ń ṣọ́ irú oúnjẹ tó ò ń jẹ, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ kó o máa ṣọ́ ìwọ̀n oúnjẹ rẹ. Torí náà, má ṣe máa jẹun lórí mo yó, tó o bá ti yó, ṣíwọ́ oúnjẹ.

Ohun míì tó tún ṣe pàtàkì tó yẹ ká fi sọ́kàn ni pé, oúnjẹ téèyàn ò bá sè dáadáa tàbí téèyàn ò tọ́jú bó ṣe yẹ lè ṣàkóbá fún ìlera. Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé, lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló ń ṣàìsàn látàrí jíjẹ oúnjẹ tí kò dáa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara ọ̀pọ̀ nínú wọn máa ń yá lẹ́yìn àìsàn náà, síbẹ̀ ó máa ń pa àwọn míì. Báwo lo ṣe lè dáàbò bo ara rẹ?

 • Wọ́n sábà máa ń fi ajílẹ̀ gbin ewébẹ̀, torí náà, fọ̀ ọ́ dáadáa kó o tó sè é.

 • Kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í dáná, fi ọṣẹ àti omi gbígbóná fọ ọwọ́ rẹ, orí tábìlì tó o ti máa dáná àti gbogbo ohun tó o máa fi dáná, irú bí abọ́, ṣíbí, ọ̀bẹ, pátákó tí wọ́n fi ń gé nǹkan àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

 • Kó tó di pé o bu oúnjẹ sí abọ́, rí i dájú pe o kọ́kọ́ fọ abọ́ náà, pàápàá tí o bá ti kó nǹkan tí o kò tíì sè, irú bí ẹyin tútù, adìyẹ, ẹran tàbí ẹja sínú rẹ̀.

 • Rí i dájú pé o sè oúnjẹ rẹ jiná dáadáa, kó o sì tètè gbé èyí tí o kò ní jẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ sínú fìríìjì.

 • Má ṣe jẹ oúnjẹ tó o bá ti gbé kalẹ̀ fún ohun tó ju wákàtí kan sí méjì, pàápàá níbi tí ooru bá wà.

4 MÁA ṢE ERÉ ÌMÁRALE

LÁÌKA ọjọ́ orí rẹ sí, o ní láti máa ṣe eré ìmárale déédéé kí ara rẹ lè le dáadáa. Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn kì í ṣe eré ìmárale tó bó ṣe yẹ. Kí nìdí tí eré ìmárale fi ṣe pàtàkì? Àwọn àǹfààní tí wàá rí nínú ṣíṣe eré ìmárale nìyí:

 • Wàá sùn dáadáa.

 • Ara rẹ á jí pépé.

 • Eegun rẹ á lè, iṣan rẹ á sì ki.

 • O kò ní sanra jọ̀kọ̀tọ̀.

 • Kò ní jẹ́ kó o máa soríkọ́ ní gbogbo ìgbà.

 • Ó lè dènà ikú àìtọ́jọ́.

Àwọn tí kì í ṣe eré ìmárale lè ko àwọn ìṣòro yìí:

 • Àrùn ọkàn.

 • Àrùn àtọ̀gbẹ.

 • Ẹ̀jẹ̀ ríru.

 • Àpọ̀jù ọ̀rá lára.

 • Àrùn rọpárọsẹ̀.

Ọjọ́ orí rẹ àti ìlera rẹ ló máa pinnu irú eré ìmárale tó dáa jù lọ fún ẹ. Torí náà, á dáa kó o kọ́kọ́ lọ rí dókítà rẹ kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe eré ìmárale. Àwọn tó mọ̀ nípa eré ìmárale sọ pé, ó yẹ kí àwọn tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún máa ṣe eré ìmárale fún wákàtí kan lójoojúmọ́. Kí àwọn tó sì ti lé ní ogún ọdún máa ṣe eré ìmárale tó mọ níwọ̀n fún wákàtí méjì ààbọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tàbí kí wọ́n ṣe eré ìmárale tó gba agbára fún ohun tó lé ní wákàtí kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

Yan eré ìmárale tó o fẹ́ràn. Onírúurú eré ìmárale ló wà tó o lè ṣe, irú bíi, bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀, tẹníìsì, bọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá, rírìn kánmọ́kánmọ́, gígun kẹ̀kẹ́, oko ríro, igi gígé, lílúwẹ̀ẹ́, wíwa ọkọ̀ ọlọ́pọ́n, sísáré kúṣẹ́kúṣẹ́, tàbí eré ìmárale míì tó máa ń jẹ́ kéèyàn lè mí gúlegúle. Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá eré ìmárale kan mọ níwọ̀n tàbí pé ó gba agbára? Eré ìmárale tó mọ níwọ̀n máa jẹ́ kó o làágùn, àmọ́ eré ìmárale tó gba agbára kò ní jẹ́ kó o lè fọkàn balẹ̀ sọ̀rọ̀ nígbà tó o bá ń ṣe é lọ́wọ́.

5 MÁA SÙN DÁADÁA

IYE àkókò tá a nílò láti fi sùn yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ ìkókó sábà máa ń fi nǹkan bíi wákàtí mẹ́rìndínlógún [16] sí méjìdínlógún [18] sùn lóòjọ́. Àwọn ọmọ ọdún kan sí ọdún mẹ́ta máa ń fi nǹkan bíi wákàtí mẹ́rìnlá [14] sùn lóòjọ́. Àwọn ọmọ ọdún mẹ́ta sí mẹ́rin sì máa ń fi nǹkan bí wákàtí mọ́kànlá [11] sí méjìlá [12] sùn lóòjọ́. Àwọn ọmọ tó ti bẹ̀rẹ̀ iléèwé nílò wákátì mẹ́wàá láti fi sùn, àwọn tó ti bàlágà nílò oorun wákàtí mẹ́sàn-án sí mẹ́wàá, àwọn tó ti dàgbà sì nílò oorun wákàtí méje sí mẹ́jọ lójúmọ́.

Àwọn onímọ̀ sọ pé ó dáa ká máa sùn fún iye wákàtí tó yẹ lójúmọ́. Torí pé:

 • Ó máa ń jẹ́ kí àwọn ọmọdé àtàwọn ọ̀dọ́ dàgbà.

 • Ó máa ń jẹ́ kí ẹ̀kọ́ wọni lórí, kí èèyàn sì rántí ohun tó kọ́.

 • Ó máa ń jẹ́ kí àwọn èròjà inú ara ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ.

 • Ó máa ń jẹ́ kí ọkàn ṣiṣẹ́ dáadáa.

 • Ó máa ń dènà àìsàn.

Tí èèyàn kì í bá sùn tó bó ṣe yẹ, ó lè fa sísanra jọ̀kọ̀tọ̀, ìsoríkọ́, àrùn ọkàn, ìtọ̀ ṣúgà, ó sì lè fa ìjàǹbá. Fún ìdí yìí, ó yẹ ká rí i pé à ń sun oorun tó pọ̀ tọ́.

Tó bá ṣòro fún ẹ láti máa rí oorun sùn bó ṣe yẹ, kí lo lè ṣe?

 • Gbìyànjú láti ní àkókò kan pàtó tó o máa sùn àti àkókò tó o máa jí lójoojúmọ́.

 • Jẹ́ kí ibi tó o fẹ́ sùn pa rọ́rọ́, má sì ṣe tan iná sílẹ̀, jẹ́ kí ibẹ̀ tù ẹ́ lára, kó má ṣe gbóná jù kó má sì tutù jù.

 • Má ṣe wo tẹlifíṣọ̀n tàbí lo àwọn nǹkan míì bíi fóònù nígbà tó o bá fẹ́ sùn.

 • Tẹ́ bẹ́ẹ̀dì rẹ dáadáa.

 • Kó o tó lọ sùn, má ṣe jẹ oúnjẹ líle tàbí mú ọtí, má sì ṣe jẹ ohunkóhun tó bá ní èròjà kaféènì nínú irú bíi kọfí, obì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

 • Tó bá ṣì ṣòro fún ẹ láti rí oorun sùn, bóyá o máa ń tòògbé lọ́sàn-án tàbí o máa ń mí gúlegúle nígbà tí o bá ń sùn, ó máa dáa kó o lọ rí dókítà tó mọṣẹ́ dunjú.