Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tó o bá ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ bá ẹnì kejì rẹ sọ̀rọ̀, ìgbéyàwó yín á dúró digbí bí sìmẹ́ǹtì ṣe ń mú ilé dúró

TỌKỌTAYA

3: Ọ̀wọ̀

3: Ọ̀wọ̀

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ

Àwọn tọkọtaya tó bá bọ̀wọ̀ fún ara wọn máa ń gba ti ara wọn rò kódà nígbà tí èrò wọn kò bá ṣọ̀kan. Ìwé Ten Lessons to Transform Your Marriage sọ pé: “Irú àwọn tọkọtaya bẹ́ẹ̀ kì í bá ara wọn jiyàn, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n á fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá ara wọn sọ̀rọ̀ kí wọ́n lè yanjú ááwọ̀. Wọ́n tún máa ń fetí sílẹ̀ sí ara wọn tí wọ́n bá ń sọ èrò wọn, wọ́n á sì ṣe ìpinnu tó máa mú ara tu àwọn méjéèjì.”

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ìfẹ́. . . kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.”​—1 Kọ́ríńtì 13:​4, 5.

“Tí mo bá mọyì àwọn ìwà rere tí ìyàwó mi ń hù, tí mi ò sì ṣe ohun tó lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá a tàbí da ìgbéyàwó wa rú, ńṣe ni mò ń fi hàn pé mo bọ̀wọ̀ fún un.”​—Micah.

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ

Táwọn tọkọtaya ò bá bọ̀wọ̀ fún ara wọn, wọ́n á máa dọ́gbọ́n bú ara wọn, wọ́n tiẹ̀ lè máa sọ̀rọ̀ burúkú sí ara wọn, wọ́n á sì máa kan ara wọn lábùkù. Àwọn olùṣèwádìí sì sọ pé irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ló máa ń fa ìkọ̀sílẹ̀.

“Tí ọkọ bá ń bú ìyàwó rẹ̀ tàbí tó ń fi ṣe yẹ̀yẹ́, ńṣe ni ìyàwó á máa wo ara rẹ̀ bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan, kò ní fọkàn tán irú ọkọ bẹ́ẹ̀, ìyẹn sì lè da ìgbéyàwó náà rú.”​—Brian.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

DÁN ARA RẸ WÒ

Fún ọ̀sẹ̀ kan, kíyè sí bó o ṣe ń hùwà sí ẹnì kejì rẹ àti bó o ṣe ń bá a sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn náà, bi ara rẹ pé:

  • ‘Ṣé mo máa ń ṣàríwísí ẹnì kejì mi, báwo ni mo ṣe máa ń gbóríyìn fún un tó?’

  • ‘Àwọn nǹkan wo ni mò ń ṣe tó fi hàn pé mò ń bọ̀wọ̀ fún ẹnì kejì mi?’

Ẹ BÁ ARA YÍN SỌ̀RỌ̀

  • Báwo la ṣe lè máa bá ara wa sọ̀rọ̀ tàbí hùwà sí ara wa tó máa fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún ara wa?

  • Kí ni ẹnì kejì mi máa ń ṣe sí mi tó fi hàn pé kò bọ̀wọ̀ fún mi?

ÀBÁ

  • Kọ nǹkan mẹ́ta tó o fẹ́ kí ẹnì kejì rẹ máa ṣe láti fi hàn pé òun bọ̀wọ̀ fún ẹ. Ní kí ẹnì kejì rẹ náà kọ tiẹ̀. Lẹ́yìn náà, kí ẹnì kìíní fún ẹnì kejì ní ohun tó kọ sílẹ̀, kẹ́ ẹ sì ṣiṣẹ́ lórí àwọn ohun tẹ́ ẹ kọ.

  • Kọ àwọn ìwà tó o fẹ́ràn lára ẹnì kejì rẹ. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kí ẹnì kejì rẹ mọ bó o ṣe mọyì àwọn ìwà yẹn tó.

“Tí mo bá ń ṣe ohun tó máa jẹ́ kí ọkọ mi mọ̀ pé mo mọyì òun, tí mo sì ń mú inú rẹ̀ dùn, ìyẹn fi hàn pé mo bọ̀wọ̀ fún un. Kò dìgbà tí mo bá ṣe nǹkan ńlá, àwọn nǹkan kéékèèké tí mò ń ṣe ló máa fi hàn pé mò bọ̀wọ̀ fún un lóòótọ́.”​—Megan.

Pàtàkì ibẹ̀ ni pé kì í ṣe ìwọ lo máa sọ pé ò ń bọ̀wọ̀ fún ẹnì kejì rẹ, àmọ́ ẹnì kejì rẹ ló máa sọ bóyá ò ń bọ̀wọ̀ fún òun.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.”​—Kólósè 3:12.