Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwà rere dà bí ẹ̀rọ atọ́nisọ́nà tí wọ́n ń pè ní kọ́ńpáàsì, ó máa ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti mọ ọ̀nà tó yẹ kó gbà

ÒBÍ

7: Ìwà Rere

7: Ìwà Rere

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ

Ìwà rere ni àwọn ìlànà dáadáa tẹ́nì kan yàn láti máa fi darí ìgbésí ayé rẹ̀, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń sọ pé ‘ìwà rere ni ẹ̀ṣọ́ èèyàn.’ Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ń sapá láti jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo tó ò ń ṣe, ó dájú pé wàá fẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ máa ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.

O tún máa fẹ́ kọ́ wọn láti jẹ́ ẹni tó ń ṣiṣẹ́ kára, tó ń ṣe dáadáa sáwọn èèyàn, tó sì ń gba tàwọn míì rò. Ìgbà tí àwọn ọmọ ṣì kéré ni wọ́n lè kọ́ irú àwọn ìwà yẹn.

LÀNÀ BÍBÉLÌ: “Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀; nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ.”​—Òwe 22:6.

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ

Ó ṣe pàtàkì kéèyàn níwà rere, pàápàá láyé ọ̀làjú yìí. Ìyá kan tó ń jẹ́ Karyn sọ pé: “Ní báyìí, fóònù ti mú kó rọrùn gan-an láti kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́. Níbi tó burú dé, ọmọ lè wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ òbí rẹ̀ kó sì máa wo ìwòkuwò lórí fóònù, tí òbí ò sì ní mọ̀!”

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: ‘Àwọn tí ó dàgbà dénú ti kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.’​—Hébérù 5:14.

Ìwà ọmọlúwàbí ṣe pàtàkì. Ó dáa kéèyàn máa lo àwọn gbólóhùn bí “ẹ jọ̀wọ́” àti “ẹ ṣeun,” ó tún yẹ kéèyàn máa pọ́n àwọn èèyàn lé. Irú àwọn ìwà báyìí ṣọ̀wọ́n lóde òní torí pé fóònù àtàwọn nǹkan míì làwọn kan kà sí pàtàkì, wọn ò sì rí tàwọn míì rò.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn.”Lúùkù 6:31.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Kọ́ ọ níwà rere. Ìwádìí fi hàn pé tí wọ́n bá ti jẹ́ kó ṣe kedere sí ọ̀dọ́ kan pé kì í ṣe ohun tó dáa kéèyàn ní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó, irú ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ kò ní fẹ́ lọ́wọ́ nínú ìbálòpọ̀.

ÀBÁ: Fi àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé kọ́ ọmọ rẹ ní ìdí tó fi yẹ kó máa hùwà rere. Bí àpẹẹrẹ, tẹ́ ẹ bá gbọ́ nínú ìròyìn pé ẹnì kan pa èèyàn, o lè sọ fún ọmọ rẹ pé: “Bí àwọn èèyàn ṣe ń hùwà ìkà sáwọn ẹlòmíì bani nínú jẹ́ gan-an ni. Kí lo rò pé ó fà á táwọn èèyàn fi ń hùwà ọ̀daràn?”

“Ó ṣòro fáwọn ọmọdé láti mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ tí wọn ò bá kọ́ wọn.”​—Brandon.

Kọ́ ọ níwà ọmọlúwàbí. Àwọn ọmọdé náà lè kọ́ láti máa sọ pé “ẹ jọ̀wọ́” àti “ẹ ṣeun,” wọ́n sì lè mọ béèyàn ṣe ń bọ̀wọ̀ fáwọn ẹlòmíì. Ìwé kan tó ń jẹ́ Parenting Without Borders sọ pé: “Táwọn ọmọ bá mọ̀ pé ohun tí àwọn bá ṣe máa nípa lórí ìdílé wọn, ilé ìwé wọn àtàwọn aládùúgbò wọn, wọn ò ní máa ro tara wọn nìkan, wọ́n á sì máa ṣe ohun tó máa ṣe àwọn míì láǹfààní.

ÀBÁ: Yan iṣẹ́ ilé fún àwọn ọmọ rẹ láti ṣe, ìyẹn máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó yẹ kí àwọ́n máa ran àwọn míì lọ́wọ́.

“Tá a bá ń kọ́ àwọn ọmọ wa láti máa ṣe iṣẹ́ ilé, ó máa mọ́ wọn lára. Tí wọ́n bá sì ti ń dá gbé, wọn ò ní máa retí pé kí ẹnì kan máa bá wọn ṣiṣẹ́, wọn ò sì ní ya ọ̀lẹ.”​—Tara.