Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ ní Ohun Tó Tọ́ Nípa Ìbálòpọ̀

Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ ní Ohun Tó Tọ́ Nípa Ìbálòpọ̀

Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀

Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ ní Ohun Tó Tọ́ Nípa Ìbálòpọ̀

Ìyá kan lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò tó ń jẹ́ Loida * sọ pé: “Wọ́n ń pín kọ́ńdọ̀mù fún àwọn ọmọ nílé ẹ̀kọ́, èyí sì mú káwọn ọmọ tí kò tíì pé ogún ọdún rò pé kò burú láti ní ìbálòpọ̀, tí kò bá ti fa àrùn tàbí kó di oyún.”

Ìyá kan nílẹ̀ Japan tó ń jẹ́ Nobuko sọ pé: “Mo béèrè lọ́wọ́ ọmọkùnrin mi pé kí ló máa ṣe tí òun àti ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ bá dá wà. Ó dáhùn pé, ‘Mi ò mọ̀.’”

NÍGBÀ tí ọmọ rẹ bẹ̀rẹ̀ sí í rìn, ǹjẹ́ o kò palẹ̀ gbogbo nǹkan tó lè ṣèpalára fún un mọ́ kúrò nínú ilé? Bóyá ńṣe lo dí gbogbo ibi tó ti lè kọwọ́ bọ iná mànàmáná, tó o kó gbogbo nǹkan ẹlẹ́nu ṣóṣóró kúrò nílẹ̀, tó o sì gbé nǹkan dí ọ̀nà àtẹ̀gùn, kí ọmọ rẹ má bàa fara pa.

Ní báyìí, o ò rí i pé iṣẹ́ kékeré kọ́ lo máa ṣe kí ọmọ náà tó pé ogún ọdún! Ó dájú pé, àwọn ìbéèrè tó ń dáni láàmú yìí á máa wá sí ẹ lọ́kàn, irú bíi, ‘Ǹjẹ́ ọmọkùnrin mi kò ti máa wo àwòrán oníhòòhò báyìí?’ ‘Ṣé ọmọbìnrin mi kò ti máa fi àwòrán ìhòòhò ara rẹ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù báyìí?’ Ìbéèrè tó wá pabanbarì níbẹ̀ ni pé, ‘Ṣé ọmọ mi tí kò tíì pé ogún ọdún kò ti máa ní ìbálòpọ̀ báyìí?’

Ṣíṣọ́ wọn lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ kò wúlò

Àwọn òbí kan máa ń gbìyànjú láti máa ṣọ́ àwọn ọmọ wọn tí kò tíì pé ogún ọdún lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀. Nígbà tó yá, ọ̀pọ̀ wọn wá rí i pé, ńṣe ni ṣíṣọ́ àwọn ọmọ yìí túbọ̀ ń mú kí wọ́n máa fi ohun tí wọ́n ń ṣe pa mọ́. Àwọn ọmọ wọn wá ti gbọ́n féfé nínú fífi ìwà wọn pa mọ́ fún àwọn òbí wọn.

Ó dájú pé, ṣíṣọ́ wọn lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ kọ́ ló máa yanjú ìṣòro náà. Jèhófà Ọlọ́run pàápàá kì í ṣọ́ àwọn èèyàn lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ kí wọ́n bàa lè ṣègbọràn sí òun, àwọn òbí náà kò sì gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. (Diutarónómì 30:19) Nítorí náà, kí lo ṣe táwọn ọmọ rẹ tí kò tíì pé ogún ọdún á fi ṣe ìpinnu ọlọ́gbọ́n tó bá di ọ̀ràn ìbálòpọ̀?—Òwe 27:11.

Ọ̀nà pàtàkì tó o lè gbà ṣe é ni pé kó o máa bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, kó o sì bẹ̀rẹ̀ nígbà tó ṣì wà ní kékeré. * (Òwe 22:6) Lẹ́yìn náà, nígbà tí ọmọ náà bá ti wọ ìgbà ìbàlágà, máa bá a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ìwọ òbí lo gbọ́dọ̀ máa fún àwọn ọmọ rẹ tí kò tíì pé ogún ọdún ní ìsọfúnni tó yẹ nípa ìbálòpọ̀. Ọmọbìnrin kan láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó ń jẹ́ Alicia sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló rò pé àwọn ọ̀rẹ́ wa la máa ń fẹ́ láti bá sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀, àmọ́ ìyẹn kì í ṣòótọ́. A máa mọyì rẹ̀ gan-an tó bá jẹ́ pé àwọn òbí wa ni wọ́n bá wa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. A mọ̀ pé òótọ́ ni ohun tí wọ́n bá sọ fún wa.”

Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kọ́ Wọn ní Ohun Tó Tọ́ Nípa Ìbálòpọ̀

Ó yẹ kí àwọn ọmọ mọ ohun tó pọ̀ nípa ìbálòpọ̀ ju pé ó kàn jẹ́ ọ̀nà kan láti bímọ. Ó yẹ kí wọ́n tún “kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:14) Ní kúkúrú, wọ́n ní láti ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nípa irú ìbálòpọ̀ tí ó tọ́, kí wọ́n sì máa gbé ìgbé ayé wọn lọ́nà tó bá ohun tí wọ́n gbà gbọ́ mu. Báwo lo ṣe máa kọ́ ọmọ rẹ tí kò tíì pé ogún ọdún nípa irú ìbálòpọ̀ tí ó tọ́?

Ohun tó o máa fi bẹ̀rẹ̀ ni pé, kó o ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí iwọ fúnra rẹ gbà pé ó tọ́ nípa ìbálòpọ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè gbà pé, àgbèrè, ìyẹn ìbálópọ̀ láàárín ọkùnrin àti obìnrin tí wọn kò tíì ṣègbéyàwó burú. (1 Tẹsalóníkà 4:3) Àwọn ọmọ rẹ lè mọ èrò rẹ nípa ọ̀ràn yìí. Wọ́n tiẹ̀ lè sọ ibi tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa ohun tó o gbà gbọ́ yìí. Nígbà tí wọ́n bá bi wọ́n ní ìbéèrè lórí ọ̀ràn náà, wọ́n lè dáhùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó burú.

Àmọ́, kò tán síbẹ̀ o. Ìwé kan tó sọ nípa ìbálòpọ̀, ìyẹn ìwé Sex Smart ṣàkíyèsí pé, kò dé ọkàn àwọn ọ̀dọ́ kan nígbà tí wọ́n bá sọ pé àwọn fara mọ́ ohun táwọn òbí wọn gbà pé ó tọ́ nípa ìbálòpọ̀. Ìwé yìí sọ pé: “Àwọn ọmọ fúnra wọn kò tíì ṣe ìpinnu nípa ohun tó tọ́ nípa ìbálòpọ̀, nítorí pé ọ̀ràn náà kò dá wọn lójú. Tí wọ́n bá bọ́ sínú ipò kan tí wọn kò retí, tó sì yẹ kí wọ́n ṣe ìpinnu tó tọ́, wọn kì í mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, wọ́n á sì kó sínú ìjàngbọ̀n.” Ìdí nìyí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn mọ ohun tó tọ́ nípa ìbálòpọ̀. Báwo lo ṣe lè ran ọmọ rẹ tí kò tíì pé ogún ọdún lọ́wọ́ láti mọ ohun tó tọ́ nípa ìbálòpọ̀?

Jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó o gbà gbọ́ nípa ìbálòpọ̀. Ṣé o gbà gbọ́ pé àwọn tó ti ṣègbéyàwó nìkan ló lè ní ìbálòpọ̀? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, sọ ọ́ lásọtúnsọ fún ọmọ rẹ, kí ó sì jẹ́ kó mọ̀ èyí dájú. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tó sọ nípa ìbálòpọ̀, ìyẹn ìwé Beyond the Big Talk, ṣe wí, ìwádìí fi hàn pé “nínú ìdílé táwọn òbí bá ti jẹ́ kó yé àwọn ọmọ wọn pé, kò yẹ kí àwọn ọmọ tí kò tíì pé ogún ọdún ní ìbálòpọ̀, ó ṣeé ṣe káwọn ọmọ náà pẹ́ kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìbálòpọ̀.”

Àmọ́ ṣá o, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ níṣàájú, sísọ ohun tó o gbà gbọ́ nípa ìbálòpọ̀ fún ọmọ rẹ kò fi dandan sọ pé ọmọ náà á tẹ̀ lé ìlànà tó o yàn. Síbẹ̀, ohun tí ìdílé kan gbà gbọ́ nípa ìbálòpọ̀ lè mú kí àwọn ọmọ ṣe ìpinnu tó tọ́ nípa ìbálòpọ̀. Ìwádìí ti fi hàn pé ọ̀pọ̀ ọmọ níkẹyìn máa ń tẹ̀ lé ìlànà táwọn òbí wọn fi lélẹ̀ lórí ọ̀ràn ìbálòpọ̀, bó tiẹ̀ jọ pé wọn kò tẹ̀ lé e nígbà tí wọ́n kò tíì pé ogún ọdún.

GBÌYÁNJÚ ÈYÍ WÒ: Lo ohun tó o gbọ́ nínú ìròyìn láti fi bá àwọn ọmọ rẹ sọ̀rọ̀, kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó o gbà gbọ́ nípa ìbálòpọ̀. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá gbọ́ ìròyìn ìwà ọ̀daràn kan tó jẹ mọ́ ìbálòpọ̀, ó lè sọ pé: “Mo kórìíra bí àwọn ọkùnrin kan ṣe máa ń kó àwọn obìnrin nífà. Ibo lo rò pé wọ́n ti kọ́ irú ìwà burúkú yẹn ná?”

Kọ́ wọn ní gbogbo ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa ìbálòpọ̀. Ó yẹ kó o kìlọ̀ fún wọn. (1 Kọ́ríńtì 6:18; Jákọ́bù 1:14, 15) Àmọ́, Bíbélì fi hàn pé ìbálòpọ̀ jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kì í ṣe páńpẹ́ Sátánì. (Òwe 5:18, 19; Orin Sólómọ́nì 1:2) Tó bá jẹ́ pé ewu tó wà nínú ìbálòpọ̀ nìkan lò ń sọ fún àwọn ọmọ rẹ tí kò tíì pé ogún ọdún, èyí lè mú kí wọ́n ní èrò tí kò tọ́ nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀ràn náà. Ọ̀dọ́bìnrin kan láti ilẹ̀ Faransé tó ń jẹ́ Corrina sọ pé: “Ọ̀rọ̀ pé ìbálòpọ̀ kò dáa làwọn òbí mi máa ń ránnu mọ́ ṣáá, èyí sì mú kí n máa fojú burúkú wo ìbálòpọ̀.”

Rí i dájú pé àwọn ọmọ rẹ mọ gbogbo òtítọ́ nípa ìbálòpọ̀. Ìyá kan nílẹ̀ Mẹ́síkò tó ń jẹ́ Nadia sọ pé: “Ohun tí mo máa ń fi yé àwọn ọmọ mi ni pé ìbálòpọ̀ dára, kò sì lòdì sí ìwà ẹ̀dá àti pé Jèhófà Ọlọ́run fi fún àwọn èèyàn láti gbádùn rẹ̀ ni. Àmọ́, àwọn tó ti ṣègbéyàwó ló wà fún. Ìbálòpọ̀ lè mú ká láyọ̀ tàbí kí ó kó ìpọ́njú bá wa, ìyẹn sì wà lọ́wọ́ bí a bá ṣe lò ó.”

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Nígbà tó o bá tún bá ọmọ rẹ tí kò tíì pé ogún ọdún sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀, tó o bá fẹ́ parí ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ kó mọ̀ pé ohun tó dára ni. Má ṣe bẹ̀rù láti sọ fún un pé ẹ̀bùn àgbàyanu ni ìbálòpọ̀ jẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, pé òun náà á gbádùn rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú tó bá ti ṣègbéyàwó. Jẹ́ kí ọkàn ọmọ rẹ tí kò tíì pé ogún ọdún bálẹ̀ pé títí di àkókò yẹn ó lè tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run lórí ọ̀ràn yìí.

Ran ọmọ rẹ tí kò tíì pé ogún lọ́wọ́ láti ro ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀. Kí àwọn ọmọ tí kò tíì pé ogún bàa lè ṣe ìpinnu tó dára ní ìgbésí ayé wọn, wọ́n ní láti gbé àwọn ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe yẹ̀ wò, kí wọ́n sì mọ ohun tó máa jẹ́ àǹfààní àti ewu tó wà nídìí ìpinnu tí wọ́n bá ṣe. Má ṣe rò pé ó ti parí nìyẹn tí wọ́n bá ti mọ ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́. Kristẹni obìnrin kan nílẹ̀ Ọsirélíà tó ń jẹ́ Emma sọ pé: “Nígbà tí mo ronú lórí àṣìṣe tí mo ṣe nígbà ọ̀dọ́ mi, mo lè sọ pé wíwulẹ̀ mọ àwọn ìlànà Ọlọrun kò túmọ̀ sí pé ẹni náà á fara mọ́ wọn. Ó ṣe pàtàkì pé kó o mọ àwọn àǹfààní tó wà nínú àwọn ìlànà yẹn àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tí o kò bá tẹ̀ lé wọn.”

Bíbélì lè ranni lọ́wọ́ nípa èyí, nítorí ọ̀pọ̀ ìgbà ló sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ téèyàn kò bá tẹ̀ lé àṣẹ tó wà nínú rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ Òwe 5:8, 9 rọ àwọn ọ̀dọ́kùnrin pé kí wọ́n má ṣe ṣàgbèrè ‘kí wọ́n má bàa fi iyì wọn fún àwọn ẹlòmíràn.’ Àwọn ẹsẹ yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé, dé ìwọ̀n àyè kan, àwọn tí wọ́n ń ní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó máa ń pàdánù ìwà rere wọn, ìṣòtítọ́ wọn àti iyì ara ẹni wọn. Ìyẹn kò sì ní jẹ́ kí wọ́n gbayì lójú ẹni tó bá fẹ́ fẹ́ wọn, bí ẹni tó fẹ́ fẹ́ wọn bá ní àwọn ìwà rere yẹn. Táwọn ọmọ rẹ bá ń ronú pé, rírú òfin Ọlọ́run lè mú káwọn kó àrùn, pé ó lè jẹ́ káwọn ní ẹ̀dùn ọkàn, tó sì lè ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́, èyí lè mú kí wọ́n pinnu láti máa pa òfin Ọlọ́run mọ́. *

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Lo àpèjúwe láti fi ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó lè rí ọgbọ́n tó wà nínú títẹ̀lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ pé: “Iná tá a fi ń se oúnjẹ dára, àmọ́ iná tó ń jó igbó ńlá kò dára. Kí ni ìyàtọ̀ tó wà nínú méjèèjì, ìjọra wo ló wà nínú ohun tó o sọ yìí àtàwọn òfin Ọlọ́run lórí ìbálòpọ̀?” Lo ohun tó wà ní Òwe 5:3-14 láti mú kí ọmọ rẹ tí kò tíì pé ogún ọdún lóye àbájáde eléwu tó wà nínú ṣíṣe àgbèrè.

Ọmọ ọdún méjìdínlógún kan nílẹ̀ Japan tó ń jẹ́ Takao sọ pé: “Mo mọ̀ pé ó yẹ kí n ṣe ohun tó tọ́, àmọ́ mò ń bá èrò kan tí kò tọ́ jìjàkadì nínú mi.” Àwọn ọ̀dọ́ tí irú èyí ń ṣẹlẹ̀ sí lè rí ìtùnú gbà ní ti pé àwọn nìkan kọ́ ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí. Ó ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pàápàá, ẹni tó jẹ́ Kristẹni tó dáńgájíá, ó ní: “Nígbà tí mo bá fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tí ó burú a máa wà pẹ̀lú mi.”—Róòmù 7:21.

Ó yẹ kí àwọn ọmọ tí kò tíì pé ogún ọdún mọ̀ pé kò burú tí wọ́n bá ń bá èrò tí kò tọ́ jìjàkadì nínú wọn. Ó lè mú kí wọ́n máa ronú nípa irú èèyàn tí wọ́n fẹ́ jẹ́. Ó lè mú kí wọ́n ronú jinlẹ̀ lórí ìbéèrè yìí pé, ‘Ǹjẹ́ mò ń lo ìgbésí ayé mi lọ́nà tó dára tí àwọn èèyàn sì mọ̀ mí sí ẹni tó níwà rere tó sì jẹ́ olóòótọ́ àbí mò ń fẹ́ kí wọ́n mọ̀ mí sí ẹni tó máa ńṣe ohun tí kò dára tí ara rẹ̀ bá ṣáà ti fẹ́?’ Tí ọmọ rẹ tí kò tíì pé ogún ọdún bá mọ ohun tó tọ́, ìyẹn á ràn án lọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè yẹn lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

^ Fún àbá lórí bó o ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọmọ rẹ nípa ìbálòpọ̀ àti bó o ṣe lè sọ ọ̀rọ̀ tí kò ju ọjọ́ orí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, ka Ilé Ìṣọ́, November 1, 2010, ojú ìwé 12 sí 14.

^ Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ṣé Ìbálòpọ̀ Máa Jẹ́ Ká Túbọ̀ Fẹ́ràn Ara Wa?” èyí tó wà nínú ìtẹ̀jáde Jí! July–September 2010 ojú ìwé 12 sí 14. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

BI ARA RẸ PÉ . . .

▪ Kí ló fi hàn pé ohun tí ọmọ mi tí kò tíì pé ogún ọdún mọ̀ nípa ìbálòpọ̀ tó tọ́ dá a lójú?

▪ Nígbà tí mo bá ń bá ọmọ mi tí kò tíì pé ogún ọdún sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀, ṣé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni mo máa ń sọ pé ìbálòpọ̀ jẹ́ ni àbí páńpẹ́ Sátánì?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]

Ìmọ̀ràn Bíbélì Wúlò Ní Gbogbo Ìgbà

“Ìtọ́ni tí Bíbélì fúnni nípa ìbálòpọ̀ wúlò ní gbogbo ìgbà. Lóde òní tí ọ̀pọ̀ ọmọ tí kò tíì pé ogún ọdún ń kórè ohun búburú tó ń wá látinú ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó, látinú gbígba oyún, kíkó àrùn éèdì àtàwọn àrùn ìbálòpọ̀ míì, èyí fi hàn pé, ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tó sọ pé, ìbálòpọ̀ wà fún kìkì àwọn tó ti ṣègbéyàwó . . . ló bọ́gbọ́n mu jù lọ, títẹ̀lé ìmọ̀ràn yìí nìkan ní kò ní jẹ́ kéèyàn kó àrùn ìbálòpọ̀, ìmọ̀ràn yìí nìkan ló sì gbéṣẹ́.”—Ìwé Parenting Teens With Love and Logic.