Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Àlá Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run

Àlá Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run

Ǹjẹ́ Ọlọ́run ti fi àlá bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ rí?

Dáníẹ́lì [Wòlíì Ọlọ́run] fúnra rẹ̀ lá àlá . . . lórí ibùsùn rẹ̀. Ní àkókò yẹn, ó kọ àlá náà sílẹ̀. Ó sì sọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn nípa ọ̀ràn náà.”Dáníẹ́lì 7:1.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Onírúurú ọ̀nà ni Ọlọ́run ti lò láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Ó máa ń lo àlá láwọn àsìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Àmọ́ àwọn àlá yìí yàtọ̀ sáwọn tí kò nítumọ̀ téèyàn máa ń lá tó bá sùn. Àwọn àlá tí Ọlọ́run bá fi han àwọn èèyàn máa ń ṣe kedere, ó sì máa ń nítumọ̀. Bí àpẹẹrẹ, wòlíì Dáníẹ́lì lá àlá kan, nínú àlá náà ó rí oríṣiríṣi ẹranko abàmì tó ń ṣàpẹẹrẹ àwọn ìjọba ayé látorí ìjọba Bábílónì títí dórí àwọn ìjọba tá a ní lónìí. (Dáníẹ́lì 7:1-3, 17) Ọlọ́run tún tipasẹ̀ àlá sọ fún Jósẹ́fù ará Násárétì tó jẹ́ alágbàtọ́ Jésù, pé kó sá lọ sí Íjíbítì pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ àti Jésù ọmọ wọn. Bí Jésù ṣe bọ́ lọ́wọ́ Hẹ́rọ́dù Ọba burúkú tó fẹ́ pa á nìyẹn. Ọlọ́run tún wá tipasẹ̀ àlá míì sọ fún Jósẹ́fù pé Ọba burúkú yẹn ti kú àti pé kí ó mú ìdílé rẹ̀ pa dà sí ìlú rẹ̀.—Mátíù 2:13-15, 19-23.

Ǹjẹ́ Ọlọ́run ṣì máa ń fi àlá bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lónìí?

“Má ṣe ré kọjá àwọn ohun tí a ti kọ̀wé rẹ̀.”1 Kọ́ríńtì 4:6.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Àwọn àlá tó wà nínú Bíbélì wà lára àwọn àkọsílẹ̀ tí Ọlọ́run ṣí payá fún wa. Ìwé 2 Tímótì 3:16, 17 wá sọ nípa àwọn àkọsílẹ̀ náà, ó ní: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”

Bíbélì “mú wa gbára dì pátápátá” ní ti pé ó ti jẹ́ ká mọ gbogbo ohun tá a nílò. Ó ṣàlàyé irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, àwọn nǹkan tó nífẹ̀ẹ́ sí àti ohun tó fẹ́ fún wa. Nítorí náà, Ọlọ́run kì í lo àlá mọ́ láti sọ ohun tó fẹ́ ṣe fáwa èèyàn. Tá a bá fẹ́ mọ ohun tí Ọlọ́run sọ nípa ọjọ́ iwájú àti ohun tó fẹ́ ká ṣe, kò yẹ ká “ré kọjá àwọn ohun tí a ti kọ̀wé rẹ̀,” sínú Bíbélì. Ó ṣe tán, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló ní Bíbélì lọ́wọ́, torí náà wọ́n lè ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣí payá títí kan àwọn àlá tó wà nínú rẹ̀.

Kí nìdí tá a fi lè gbára lé àwọn àlá àti ìran tó wà nínú Bíbélì?

“Àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.”2 Pétérù 1:21.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Àsọtẹ́lẹ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn àlá àti ìran tó wà nínú Bíbélì. Bí wọ́n ṣe ṣàkọsílẹ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí sínú Bíbélì máa jẹ́ kí àwọn tó ń kà á rí i pé òótọ́ ni ohun tó wà nínú rẹ̀ àti pé Ọlọ́run ló darí àwọn tó kọ ọ́. Ǹjẹ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ìran kan tí Dáníẹ́lì rí kí wọ́n tó ṣẹ́gun Ilẹ̀ Ọba Bábílónì, èyí tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì 8:1-7.

Nínú ìran náà, Dáníẹ́lì rí àgbò kan àti akọ ewúrẹ́ kan. Akọ ewúrẹ́ náà ṣẹ́gun àgbò yẹn, ó là á mọ́lẹ̀, ó sì tún tẹ àgbò náà mọ́lẹ̀. Dáníẹ́lì ò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wá ìtumọ̀ ìran náà nítorí pé áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún un, ó ní: ‘Àgbò oníwo méjì náà dúró fún àwọn ọba Mídíà àti Páṣíà. Akọ ewúrẹ́ onírun náà sì dúró fún ọba ilẹ̀ Gíríìsì’. (Dáníẹ́lì 8:20, 21) Ìtàn fi hàn pé ilẹ̀ Mídíà òun Páṣíà ló ṣẹ́gun Bábílónì tó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí agbára ayé. Ní nǹkan bí igba [200] ọdún lẹ́yìn náà, ọba Alẹkisáńdà Ńlá ti ilẹ̀ Gíríìsì ṣẹ́gun ilẹ̀ Mídíà òun Páṣíà. Irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó péye báyìí àti àwọn àlá alásọtẹ́lẹ̀ ló wà nínú Bíbélì. Èyí mú kí Bíbélì yàtọ̀ sí àwọn ìwé ìsìn mìíràn, ó sì yẹ ká gbára lé e.